Kayeefi nla leleyii o! Ọlọpaa wa ninu awọn to fipa  ba akẹkọọ Fasiti Ilọrin lo pọ, ti wọn tun pa a

Ibrahim Alagunmu, Ilọrin

Kayeefi nla ati iyalẹnu lọrọ naa jẹ nile-ẹjọ, nigba ti ọlọpaa to wa lẹnu iṣẹ, Sajẹnti Adewale Adeshọla, jẹwọ pe oun jẹ ọkan lara awọn to fipa ba ọmọ akẹkọọ Fasiti Ilọrin, Ọlajide Blessing Omowumi lo pọ, tawọn tun sẹku pa a, lagbegbe Tankẹ, niluu Ilọrin, ipinlẹ Kwara.

Ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọṣẹ yii, ni Adeshọla fara han nile-ẹjọ gẹgẹ bii ẹlẹrii, ṣugbọn ti ọrọ tun gba ọna miiran yọ, nigba ti wọn ni oun naa wa lara awọn afurasi mẹjọ ti wọn n jẹjọ lọwọ niwaju Onidaajọ Ibrahim Yusuf, lori ẹsun pe wọn fi pa ba Blessing lo pọ wọn tun sẹku pa a.

Adeshọla sọ pe ọkan lara awọn afurasi, Abdulateef Abdulrahman, ti awọn jọ n gbe lati bii ọdun mẹẹẹdogun sẹyin, lo fun oun ni ẹrọ ibanisọrọ to jẹ ti oloogbe (Blessing) pe ki oun ba a fi pamọ, laarin ọjọ kẹwaa, oṣu kẹfa, ọdun yii, ṣugbọn oun o ti i ṣe iwadii lori ẹrọ ibanisọrọ naa ti ajọ ẹṣọ alaabo DSS fi ranṣẹ pe oun.

Ajọ DSS, ẹka ti ipinlẹ Kwara, ti waa ko awọn ẹri ti kodin ni ogoji siwaju adajọ, to fi mọ ayederu ibọn onigi ti awọn afurasi:Abdulazeez Ismail, Ajala Moses Oluwatimilẹyin (aka Jacklord); Oyeyẹmi Timilẹyin, Ọmọgbolahan; Abdulkarim Shuaib (aka Easy); Kareem Oshioyẹmi Rasheed (Rashworld); Abdullateef Abdulrahman, Daud Bashir Adebayọ (aka Bashman) ati Taye Ọladọja Akande, lo lati fi siṣẹ aburu wọn, ti ajọ naa si wọ wọn lọ si kootu fun ẹsun ifipabanilopọ, ipaniyan ati idigunjale.

Ajọ DSS tun ko awọn ẹlẹrii mẹta wa sile-ẹjọ, to fi mọ ọrẹbinrin ọkan lara awọn afurasi, Zainab Ọlaiya to sọ fun ile-ẹjọ pe Akande Taiye fi ẹrọ ibanisọrọ Blessing pe oun, eyi lo jẹ ki ajọ DSS mu  Taye.

Adajọ ti sun igbẹjọ si Ọjọruu, Wẹsidee, ọṣẹ yii.

 

Leave a Reply

//byambipoman.com/4/4998019
%d bloggers like this: