Ibrahim Alagunmu, Ilọrin
Ọjọ Ẹti, Furaide, opin ọsẹ to lọ yii, ni Arakunrin kan, Ọlayinka Ṣẹgun Owolabi, fẹẹ ṣeku pa ara rẹ nitori pe jijẹ ati mimu rẹ nira, ile aye su u, lo ba lọọ pokunso ni Budu Nuhu, lagbegbe papakọ ofurufu ilu Ilọrin, nipinlẹ Kwara. Ọpẹlọpẹ ero to n kọja lọ, to ri i, to doola ẹmi ẹ lọwọ iku ojiji.
Ninu atẹjade kan ti Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Kwara, Ọgbẹni Ọkasanmi Ajayi, fi sita to tẹ ALAROYE lọwọ lo ti ṣalaye pe ọkunrin kan ti orukọ rẹ n jẹ Ọlayinka Sẹgun Owolabi lo fẹẹ gbẹmi ara rẹ, to si lọọ pokunso latari pe o jẹ ọmọ orukan, ati pe gbogbo nnkan dojuru fun un. Ọpẹlọpẹ ẹlẹyinju aanu kan to n kọja lọ to rin sasiko iṣẹlẹ naa to doola ẹmi rẹ, ti wọn si sare gbe e lọ si ileewosan aladaani kan ti wọn n pe ni Tobi, lagbegbe Taiwo, niluu Ilọrin, nibi to ti n gba itọju lọwọ bayii.
Nigba ti wọn n fọrọ wa Owolabi lẹnu wo, o ni oun jẹ ọmọ agboole Alagbẹdẹ Abutu Ọyan, nijọba ibilẹ Odo-Ọtin, nipinlẹ Ọsun, ṣugbọn aye ti su oun pẹlu bi oun ṣe padanu iṣẹ ati awọn obi mejeeji, ti ko si si oluranlọwọ Kankan, bẹẹ ni ko si ireti nibi kan, eyi loun ṣe pinnu lati pa ara oun.
Kọmiṣanna ọlọpaa nipinlẹ Kwara, Tuesday Assayomo, ti waa rọ awọn obi ati alagbatọ lati maa ṣe ojuṣe wọn lori awọn ọmọ wọn lasiko to tọ, to yẹ, nigbakuugba lati dena irufẹ iṣẹlẹ bayii.