Kayeefi gbaa ni iku ọmọdebinrin kan ti wọn pe orukọ ẹ ni Precious Iwezoa ṣi n jẹ fawọn eeyan, pẹlu bi ọmọ naa ṣe ki ọrun bọ okun nile iyaaya rẹ to n gbe, iyẹn l’Ojule kẹfa, Opopona Osagie, Lucky way, ipinlẹ Edo.
Ọjọ Satide to kọja yii niṣẹlẹ yii waye gẹgẹ bi ẹka iroyin Channels to gbe e jade ṣe ṣalaye. Wọn ni Precious ko dagbere ibi kankan fun iya rẹ agba to fi lọọ ki ọrun bọ okun. Iya paapaa ko mọ pe ọmọ naa ti dan mẹwaa wo, nitori ko pẹ to ba a gbe ounjẹ kana lo jade sita, ti iya rẹ agba si wa ninu ile. Afi bo ṣe di pe awọn araale ri i to n fi dirodiro nibi to pokunso si.
Iya to bi Precious ti ku latigba tọmọ yii ti wa lọmọ ọdun meji pere, nigba to di ọdun 2017 ni wọn lo bẹrẹ si i gbe lọdọ iyaaya rẹ ti wọn pe orukọ tiẹ ni Janet Ohioma, iyẹn ọdun kerin sẹyin.
Nigba ti iya agba naa n fi omije ṣalaye ohun to ṣẹlẹ fawọn ọlọpaa, o loun ko ro ohun to ṣẹlẹ yii pe iru ẹ le ṣẹlẹ sọmọ oun laye. Iya sọ pe bi Precious ṣe gbe ounjẹ foun tan lo lọọ jokoo si palọ, to n wo tẹlifiṣan, ibẹ loun si ro pe o wa, afi bi wọn ṣe waa pe oun pe koun waa wo o, o loun tiẹ ro pe o sa lọ bo ṣe ṣe nigba kan ni, ti wọn waa ba oun ri i, afi boun ṣe debẹ toun ri i pe o ti pokunso ni.
Ko si idi kan pato ti ọmọ kekere bii eyi yoo ṣe pokunso, gẹgẹ bi Alukoro ọlọpaa ipinlẹ Edo, Bello Kontongs, ṣe sọ. O ni o jẹ ohun to baayan lọkan jẹ lati fidi iṣẹlẹ aburu bayii mulẹ nipa ọmọdebinrin ti ọjọ ori ẹ ko ju mẹtala lọ yii.
O ni boun ṣe wo ọmọ yii nibi to so si, ki i ṣe pe wọn ki ọrun rẹ bọ okun, ṣugbọn iwadii to jinlẹ ni yoo fidi ohun to ṣẹlẹ gan-an han, awọn si ti bẹrẹ rẹ ni pẹrẹwu.