Kayeefi ree o! Dẹrẹba bọọsi BRT ji ero inu ọkọ rẹ gbe sa lọ l’Ekoo

Jọkẹ Amọri

Titi di ba a ṣe n sọ yii ni wọn ṣi n wa dẹrẹba BRT kan to gbe ọdọmọdebinrin ti ko ju ẹni ọdun mejilelogun lọ, Oluwabamiṣe Ayanwọla to wọ bọọsi rẹ lọ lọjọ Abamẹta, Satide, ọjọ kẹrindinlọgbọn, oṣu Keji, ọdun yii.

Gẹgẹ bi iweeroyin Punch ṣe gbe e jade, ilu Ajah ni ọmọbirin ti wọn lo n ṣiṣẹ awọn to n ranṣọ yii n gbe ni Chevron Estate. Ṣugbọn lọjọ kẹrindinlọgbọn, oṣu Keji, ọdun yii, o kuro nile to n gbe l’Ajah, o loun fẹẹ lọọ lo opin ọsẹ lọdọ ẹgbọn oun to n gbe niluu Ọta, nipinlẹ Ogun.

Nigba naa lo wọ bọọsi BRT kan ti nọmba rẹ jẹ 240257.

Nigba ti wọn n lọ ti dẹrẹba naa ko gbe ero mi-in ni gbogbo awọn ibudokọ ti wọn kan loju ọna lara bẹrẹ si i fu ọmọbinrin yii. Eyi lo mu ki ọmọbinrin yii bẹrẹ si i ba ọrẹ rẹ kan sọrọ lori foonu rẹ. O sọ fun ọrẹ rẹ yii pe ko jọwọ, ko maa gbadura foun o, pe oun fura si dẹrẹba mọto ti oun wọ yii.

Wọn ni ọrẹ rẹ yii sọ fun un pe ko bọ silẹ to ba ti de ibudokọ Oworonṣhoki ko too de ibudokọ Oshodi.

Bakan naa ni wọn ni ọmọbinrin ti wọn n wa yii fi fidio bi inu mọto naa ṣe dudu to han ọrẹ rẹ yii.

Eeyan mẹrin ni wọn lo wa ninu bọọsi BRT ọhun. Ọkunrin mẹta ati obinrin kan, ti obinrin naa si jokoo sẹyin ninu ọkọ ọhun gẹgẹ bi Oluwabamiṣe ṣe sọ fun ọrẹ rẹ, to si fi nọmba bọọsi ọhun ranṣẹ si i pẹlu pe aibaa mọ o. To si tun tẹnu mọ ọn fun ọrẹ rẹ yii pe ko maa gbadura foun.

Ohun ti wọn gbọ mọ nipa ọmọbinrin naa niyi titi di ba a ti n sọ yii gẹgẹ bi iya rẹ ṣe sọ.

Ọkan ninu awọn mọlẹbi ọmọbinrin naa ni awọn lọ sọdọ ọga agba awọn onimọto BRT, awọn si ba ọga yii atawọn mẹta mi-in ti wọn sọ fawọn pe bi awọn ṣe gbe ọrọ naa lọ sori ẹrọ ayelujara le ṣe akoba fun iwadii awọn ọlọpaa lori rẹ.

Bakan naa ni wọn sọ pe awọn gan-an kọ ni awọn n gba oṣiṣẹ, ati pe awọn ti fi to ẹni to n ba wọn gba oṣiṣẹ leti. Bẹẹ ni wọn sọ pe ẹni to ṣe oniduuro fun dẹrẹba naa ti sa lọ. Wọn ko ti i ri.

Alukoro ileesẹ ọlọpaa nipinlẹ Eko, Adekunle Ajiṣebutu, fi idi iṣẹlẹ naa mulẹ, bẹẹ lo ni iwadii ti n lọ lori rẹ.

Bakan naa ni ọga ọlọpaa Eko, Abiọdun Alabi, ni gbogbo ohun to ba gba lawọn yoo fun un lati ri i pe ọmọ naa di riri.

Leave a Reply