Kayọde sa lẹwọn Ibara, lo ba tun lọọ ji mọto n’Ijeun-tuntun

Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta

Kayọde Adeyẹmi lorukọ ẹ, iyẹn ọmọkunrin ẹni ọdun mẹtalelogun kan to sa kuro lọgba ẹwọn Ibara, l’Abẹokuta, ninu oṣu karun-un, ọdun yii, ṣugbọn tọwọ ti ba a pada bayii nitori mọto onimọto to tun lọọ ji n’Ijeun-tuntun.

Nigba  ti wọn gbe Kayọde wa si kootu Majisreeti Iṣabọ  l’Ọjọbọ to kọja pe o ji mọto, niṣe lo purọ orukọ to n jẹ. Ọmọkunrin naa sọ fun kootu pe Lekan Ogunmuyiwa lorukọ oun. Ṣugbọn nitori ki i ṣe ajoji fun kootu atawọn ọlọpaa, titi kan ọgba ẹwọn to ti sa kuro, irọ orukọ to pa naa ko jẹ wọn rara.

Agbẹnusọ  ijọba lori ẹjọ naa, Inspẹkitọ Lawrence Olu-Balogun, ti Inspẹkitọ Ọlaide Rawlings ṣoju fun, ṣalaye pe ọjọ kẹrinlelogun, oṣu keje, ọdun yii, ni Kayọde ji mọto ayọkẹlẹ naa.

O ni taksi ni ẹni to ni mọto naa fi n ṣe, iwaju ita rẹ lo si paaki ẹ si lagbegbe Ijeun-tuntun ti Kayọde ti ji i gbe. O tẹsiwaju pe Oluṣẹgun Ọladele lo ni mọto naa.

Inspẹkitọ Rawlings sọ fun kootu pe owo ọkọ to ji naa to ẹgbẹrun lọna ẹgbẹrin naira (800,000).

Oju ọna marosẹ Ṣagamu si Abẹokuta lọwọ ti ba Kayọde pẹlu mọto naa laipẹ yii, to fi di pe o foju bale-ẹjọ bayii.

Nigba to n dahun ibeere kootu pe ṣe o jẹbi ẹsun ole jija, Kayọde loun ko jẹbi.

Adajọ Dẹhinde Dipeolu ko faaye beeli silẹ fun olujẹjọ yii rara, o ni ki wọn da a pada sọgba ẹwọn to ti sa kuro ni.

Igbẹjọ tun di ọjọ kẹrindinlọgbọn, oṣu yii.

Leave a Reply