Kazeem ti dero ẹwọn o, odidi oṣu marun-un lo fi ba ọmọ bibi inu rẹ sun n’Ido-Ọṣun

Florence Babạsọla, Oṣogbo

Ọgbẹni Kazeem Ọlapade ladajọ ile-ẹjọ Majisreeti kan niluu Oṣogbo ju sẹwọn lọjọ Ẹti, Furaidee, ọse yii lori ẹsun pe o n ba ọmọ bibi inu rẹ sun.

Laaarin oṣu kẹjọ, ọdun to kọja, si oṣu kin-in-ni, ọdun yii, la gbọ pe baba naa fi ba ọmọ rẹ ti wọn pe ni Mariam lajọṣepọ, ko too di pe ọwọ awọn ọlọpaa tẹ ẹ.

Inu ile wọn to wa ni Ido-Ọṣun la gbọ pe olujẹjọ ti n huwa ti ko bojumu naa fun ọmọ rẹ.

Agbefọba, Inspẹkitọ Jacob Akintunde, fi ẹsun mẹta kan olujẹjọ, o si ṣalaye pe gbogbo awọn ẹsun naa ni wọn nijiya labẹ ipin kin-in-ni ati ikeji, abala kọkanlelọgbọn ofin to n daabo bo ẹtọ awọn ọmọde tipinlẹ Ọṣun gbe kalẹ lọdun 2007.

Bakan naa lo ni o nijiya labẹ ipin okoolelugba o din mẹfa (214) ati ọtalelọọọdunrun-un (360) abala kẹrinlelọgbọn ofin iwa ọdaran ti ọdun 2002 nipinlẹ Ọṣun.

Nigba ti wọn ka ẹsun mẹtẹẹta si olujẹjọ leti, o ni oun ko jẹbi, agbẹjọro rẹ naa, K. C. Abioye, bẹbẹ pe ki kootu faaye beeli silẹ fun un lọna irọrun.

Onidaajọ Oluṣẹgun Ayilara sọ pe oun ko le fun un ni beeli, o ni kawọn ọlọpaa taari rẹ si ọgba ẹwọn ilu Ileṣa.

Lẹyin naa lo sun idajọ lori gbigba beeli rẹ si ọjọ karun-un, oṣu keji, ọdun yii.

Leave a Reply