Kazeem ti dero ile-ẹjọ o, ọrẹ rẹ lo pa to fẹẹ fi ṣoogun owo ni Kwara

 

Musa Ibrahim, Alagunmu

Ile-ẹjọ Magistreeti kan niluu Ilọrin, ti fi igbẹjọ Kazeem ati awọn mẹta miiran ti wọn jọ gbimọ-pọ pa ọrẹ rẹ, Bukọla Ojo, ni ilu Patigi, nijọba ibilẹ Patigi, nipinlẹ Kwara, si ọjọ kẹjọ, oṣu keje, ọdun yii, to si ni ki wọn wa ni ahamọ titi di ọjọ igbẹjọ.

Iroyin to tẹ ALAROYE lọwọ ni pe, Kazeem to jẹ ọrẹ timọtimọ si Bukọla Ojo, lo pinnu lati fi ọrẹ rẹ ṣe oogun owo, to si gbimọ-pọ pẹlu awọn mẹta miiran ki iṣẹ naa le rọrun fun un lati ṣe. Igbeyawo Ojo ti n sun ile diẹdiẹ, eyi lo mu ki wọn tan an lọ sinu igbo pe ko waa wo maaluu ti awọn ba ra fun ayẹyẹ igbeyawo rẹ to n bọ lọna, ti wọn si ṣeku pa a. Ọkan ninu awọn ọrẹ yii, Madu Jeremiah, lo ṣeto bi wọn ṣe ri ibọn ti wọn fi pa ọkunrin ọhun.

Lẹyin ti wọn pa a tan ni wọn ge ori rẹ, ati apa mejeeji, ti Kazeem si ko o lọ sọdọ Muhammad Chatta ti yoo ba a fi ṣe oogun owo. Mohammed tun gbe foonu oloogbe fun Jimoh Abdullateef, wọn fi pe mọlẹbi rẹ, wọn si n beere fun milionu mejila owo itusilẹ ẹni ti wọn ti seku pa, ki ọwọ palaba wọn too ṣegi.

Agbefọba, Moshood Adebayọ, waa rọ Magistreeti Adeniyi lati fi awọn afurasi naa si ahamọ titi di ọjọ igbẹjọ. Adeniyi ti ni ki awọn mẹrẹẹrin maa lọọ gbatẹgun lọgba ẹwọn titi di ọjọ igbẹjọ mi-in.

Leave a Reply