Kẹhinde ati Emeka to n ta ayederu foonu n’Ikẹja ti ha!

Faith Adebọla, Eko

Ẹni ba ri Kẹhinde Ọlabọde, ẹni ọdun mẹrinlelọgbọn, ati Chukwuemeka Ogbona, ẹni ọdun marundinlaaadọta, nibi kanta ti wọn lawọn ti n tun foonu ṣe ni Computer Village, to wa n’Ikẹja, eeyan yoo kọkọ ro pe ‘ẹnjinnia’ ni wọn ni, ṣugbọn iṣẹ jibiti foonu lori ayelujara lawọn afurasi naa n ṣe.

Ẹnikan ti wọn ṣẹṣẹ ṣe gbaju-ẹ foonu I-Phone X ti owo rẹ to ẹgbẹrun lọna ọtalerugba naira (N260,000) lo ṣokunfa bọwọ ṣe tẹ wọn l’Ọjọruu, Tọsidee, to kọja yii.

Ninu alaye ti wọn lawọn afurasi naa fẹnu ara wọn ṣe lagọọ ọlọpaa, wọn lawọn kan n dibọn pe ẹnjinnia foonu lawọn ni, ayederu foonu lawọn maa n ta lori ikanni fẹni to ba ko sakolo awọn.

Wọn lori atẹ ayelujara ti wọn ti n ta ọja aloku tabi tokunbọ lawọn ti maa n lọọ polowo foonu olowo iyebiye ni pọntọ, kawọn eeyan le nifẹẹ lati ra a, awọn yoo si ṣeto bi wọn yoo ṣe pade ẹni to ba fẹẹ ra ọja ti wọn polowo ọhun, ibẹ ni wọn yoo ti lu ọnitọhun ni jibiti.

Kẹhinde ni ẹgbẹrun lọna marundinlaaadọjọ naira (N155,000) loun polowo foonu I-phone X yii sori ikanni naa, toun si gbe fọto foonu iru ẹ sibẹ loriṣiiriṣii, ni onibaara yii ba loun fẹẹ raa, awọn si jọ ṣadehun lati pade ni ṣọọbu kan ninu ọja Computer Village lọjọ naa.

Nigba ti onibaara naa de, awọn fi foonu I-phone X gidi han an, o yẹẹ wo, o si sanwo, ibi tawọn si ti n ba a tẹẹsi foonu naa lawọn ti dọgbọn paarọ ẹ si ayederu to jọra pẹlu eyi ti wọn ti fi han an tẹlẹ, ni wọn ba sa lọ. Ẹgbẹrun lọna ọgbọn naira pere ni wọn n ta eyi ti wọn fi paarọ fun un yẹn lori igba.

Ọkunrin to lugbadi jibiti wọn yii lo lọọ fẹjọ sun ni teṣan ọlọpaa to wa ninu ọja naa, wọn si pada ri awọn afurasi ọdaran naa mu nirọlẹ ọjọ naa.

Kẹhinde lawọn pọ tawọn jọ maa n lu jibiti naa, o loun ti kọkọ ṣeto awọn ti wọn maa fi ọrọ de onibaara naa mọlẹ, ti ko fi ni i fọkan si i tabi mọ igba toun ba fẹẹ paarọ foonu ojulowo si ayederu rara.  

Chukwuemeka ni tiẹ jẹwọ pe nigba mi-in, niṣe lawọn maa n fi ayederu owo naira paarọ ojulowo tawọn eeyan ba fi sanwo fawọn, iyẹn ti onitọhun ba loun ko fẹ ọja naa mọ, to si fẹẹ gba owo ẹ pada.

Wọn tun darukọ Ibrahim, wọn loun lọga awọn nidii jibiti lilu yii, ṣugbọn o ti sa lọ.

Ọrọ yii ti de ọdọ kọmiṣanna ọlọpaa ipinlẹ Eko, Kayọde Odumosu, o si ti paṣẹ ki wọn taari awọn mejeeji tọwọ ba naa si ẹka ileeṣẹ ọlọpaa to n bojuto iwa jibiti ati ole jija.

Leave a Reply