Kẹhinde fipa ba abirun lo pọ l’Ọta, Musa naa tun fipa ba ọmọ ọdun mẹjọ lo pọ n’Ijẹbu-Ode

 Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta

Fun pe o fi tipatipa ba ọmọbinrin kan ti ara rẹ ko da pe lo pọ, Kẹhinde Oluwafẹmi ti foju ba kootu Majisreeti Ọta, nipinlẹ Ogun, lọsẹ to kọja yii, ṣugbọn o loun ko jẹbi.

Agbegbe Isalẹ Ilogbo, l’Ọta, ni Kẹhinde, ẹni ọdun marundinlogoji (35) n gbe, ibẹ naa lo ti fipa ba ọmọbinrin naa lo pọ ni nnkan bii aago mẹwaa aabọ alẹ ọjọ kejila, oṣu keji, ọdun yii.

Iwa yii ta ko ofin ipinlẹ Ogun ti wọn ṣe lọdun 2006, ijiya si wa fun un gẹgẹ bi Agbefọba, Inspẹkitọ E.O Adaraloye, ṣe ṣalaye fun kootu naa. Ṣugbọn nigba ti olujẹjọ n dahun ibeere ti wọn bi i pe ṣe o jẹbi tabi bẹẹ kọ, Kẹhinde loun ko jẹbi.

Esi rẹ yii lo jẹ ki Adajọ A. O Adeyẹmi faaye beeli silẹ fun un pẹlu ẹgbẹrun lọna aadọta Naira (50,000) ati oniduuro meji niye kan naa.

O paṣẹ pe awọn oniduuro naa gbọdọ maa gbe lagbegbe kootu, wọn si gbọdọ niṣẹ gidi lọwọ. Igbẹjọ tun di ọjọ kọkandinlogun, oṣu yii.

Bakan naa ni Musa Anifowoṣe, ẹni ọdun mọkanlelogun pere (21) ti di ero ẹwọn bayii, ohun to si fa a naa ni pe o fipa ba ọmọ ọdun mẹjọ laṣepọ n’Ijẹbu-Ode lọjọ kin-in-ni, oṣu karun-un, ọdun 2020 yii.

Kootu Majisireeti ni wọn ti ju u sẹwọn l’Ọjọruu, Wẹsidee,  to kọja yii, l’Abẹokuta. Adajọ I.O Abudu sọ pe gbogbo ẹri pata lo fidi ẹ mulẹ pe Musa to n gbe l’Ojule keji, Isalẹ Iyemule, n’Ijẹbu-Ode, fipa ba ọmọbinrin kekere naa sun ni nnkan bii aago mẹsan-an aarọ ọjọ yii, o si ṣe e ṣakaṣaka.

Ṣaaju ni Agbefọba, Inspẹkitọ Bukọla Abọlade, ti sọ fun kootu pe l’Ojule kẹfa, Opopona Agbaje, n’Ijẹbu-Ode, ni olujẹjọ ti huwa to lodi sofin ọhun, bẹẹ, iya ọmọ naa lo ran an niṣẹ ti Musa fi fọgbọn ẹtan mu un wọ ile akọku kan lẹgbẹẹ ibi ti wọn ti n ta ẹran ni Sabo, Ijẹbu-Ode, nibẹ lo si ti sọ ọmọ naa di obinrin pẹlu ibale rẹ to gba.

Iya ọmọ naa lo ri ẹjẹ lara rẹ nigba to de, nigba naa lọmọ si jẹwọ fun iya rẹ pe Musa ṣe nnkan pẹlu oun ninu ile akọku.

Lẹyin ti gbogbo ẹri si ti fi han pe olujẹjọ huwa naa, Adajọ Abudu ran an lẹwọn ọdun meji lọgba ẹwọn to wa l’Ọ̀bà, l’Abẹokuta. Ko faaye owo itanran silẹ, ẹwọn ọdun meji gbako lo ni ko maa lọ.

Leave a Reply