Kẹkẹ Maruwa ko sẹnu tirela n’Ipẹru, eeyan marun-un lo dagbere faye

Adefunkẹ Adebiyi,Abẹokuta

Eeyan marun-un ti gbogbo wọn jẹ ọkunrin, ni wọn ku iku ojiji laaarọ ọjọ Iṣẹgun, ọjọ kẹtadinlọgbọn, oṣu kẹrin yii, nigba ti tirela meji, kẹkẹ Maruwa meji, fori sọ ara wọn lagbegbe Ipẹru, nipinlẹ Ogun.

Awọn to wa ninu kẹkẹ Maruwa mejeeji naa lo ku, gẹgẹ bi Kọmandanti Ahmed Umar, ọga FRSC nipinlẹ Ogun, ṣe ṣalaye.

O sọ pe ni nnkan bii aago mẹsan-an aarọ ku iṣẹju mẹẹẹdogun niṣẹlẹ yii waye, nigba ti tirela ti nọmba ẹ jẹ UWN 279 YT, ati ikeji ti nọmba ẹ jẹ AAB 973 ZY, pẹlu kẹkẹ Maruwa to ni nọmba PKA 438 UN ati ikeji ẹ to jẹ LSD 566QF, n sare loju popo yii. Ere naa lo pọ ju, ti wọn kọ lu ara wọn ti ijamba fi waye.

Yatọ sawọn ọkunrin marun-un to ku lẹsẹkẹsẹ ninu awọn kẹkẹ Maruwa mejeeji, obinrin ati ọkunrin kan naa tun fara pa.

Wọn gbe mẹrin ninu awọn to doloogbe naa lọ si mọṣuari Fakọya, ni Ṣagamu,ẹbi ẹnikarun-un ni awọn yoo lọọ sin in lẹsẹkẹsẹ, ki wọn ma gbe e lọ si mọṣuari kankan, wọn si gbe e lọ.

Awọn ẹbi lo gbe awọn meji to fara pa naa lọ fun itọju gẹgẹ bi ọga FRSC naa ṣe sọ.

Umar sọ pe ijamba yii ṣee dena, to ba jẹ pe awọn to kọ lu ara wọn naa farabalẹ ni. O rọ awọn ọlọkọ, onimaruwa, ọlọkada lati maa ṣe suuru loju ọna, nitori ohun to n ṣọṣẹ ko to nnkan.

 

Leave a Reply