Kekere lohun to ṣẹlẹ yii lẹgbẹẹ eyi to n bọ- Tunde Bakare

Faith Adebọla, Eko

Oludasilẹ ati adari ijọ Latter Rain Assembly tẹlẹ, to ti porukọ da si Citadel Church bayii, Pasitọ Tunde Bakare, ti sọ pe bii ọmọde meji n ṣere ni iwọde tawọn ọdọ ṣe ta ko awọn ọlọpaa SARS laipẹ yii, aifararọ ati biba dukia jẹ to ṣẹlẹ lẹyin iwọde naa maa jẹ lẹgbẹẹ rogbodiyan to n rọ dẹdẹ lori orilẹ-ede yii, afi ti ijọba atawọn oloṣelu ba jawọ ninu aapọn ti ko yọ bayii, ti wọn tete da omi ila ka’na lai fakoko ṣofo mọ.

Ọsan ọjọ Aiku, Sannde, ọsẹ yii ni ojiṣẹ Ọlọrun yii sọrọ naa ninu ikede pataki kan to ṣe lẹyin isin ọjọ isinmi rẹ. Bakare ni o ti gbọdọ han gbangba si awọn alagbara orilẹ-ede yii pe ko si iye ihalẹ, ifiyajẹni, idunkooko mọ ni ati ikoni-ni-papa-mọra to le bomi pana ẹhonu ati ikanra to wa lọkan awọn ọmọ Naijiria lasiko yii, o ni ara ti kan araalu de gongo gidi ni.

‘‘Ibọn yin le le wọn kuro ni titi, ṣugbọn ibọn yin ko le le ibinu ati ẹhonu to wa lookan aya wọn kuro. Ipenija ta a ni latari bi wọn ṣe n ṣejọba raurau lorileede yii lo fa a tara awọn eeyan fi gbẹkan, ti wọn ko si bikita lati ja funra wọn mọ.’’

O ṣalaye pe ijọba ti pẹ ju, aṣeju ati aṣetẹ ti wọ ọ, lẹnu bi wọn ko ṣe pese awọn nnkan koṣeemani bii ina ẹlẹntiriiki, omi, oju ọna to ja geere, ile ati ọrọ aje to dara fawọn araalu. Iru ifarada tawọn eeyan ni latọjọ yii wa ti sọnu bayii, ko sẹni tọrọ ilu yii tẹ lọrun mọ, tori iya ki i ṣe omi ọbẹ.

O ni orileede tawọn baba nla wa ja fun kọ niyi, ki i ṣe ipo ti wọn reti pe ki Naijiria wa lo wa yii, ko si sigba ti nnkan ko ni i burẹkẹ si i bo ba n lọ bo ṣe n lọ yii.

Ni ipari ọrọ rẹ, Bakare, to ti figba kan du ipo igbakeji aarẹ orileede yii pẹlu Aarẹ Buhari ri sọ pe imọran oun si ijọba apapọ ni pe ki wọn ma ṣe duro lori awọn ibeere marun-un tawọn ọdọ ti taari siwaju wọn nikan, ṣugbọn ki wọn tete gbe igbesẹ lati ṣatunto eto bi awọn awọn ọlọpaa ilẹ wa ṣe n ṣiṣẹ latoke delẹ.

O tun ni kijọba wadii awọn to wa lẹyin bi awọn ṣọja ṣe yinbọn lu awọn to ṣewọde ni Lẹkki lọjọ Iṣẹgun to kọja yii, ki wọn si fiya to tọ jẹ wọn labẹ ofin, tori igbesẹ buruku tawọn ṣọja naa gbe lo tanna ran gbogbo ifẹhonu han ati biba dukia jẹ to kọ ti ko dawọ duro yii.

O kilọ pe ni bayii, bi ayipada rere ko ba bẹrẹ si i waye latọdọ awọn onṣejọba wa lati Abuja, titi de awọn ipinlẹ, o da oun loju pe ohun to ṣi wa lẹyin ọfa maa ju oje lọ, afaimọ ni ki rukerudo to lagbara ko ni i ṣẹlẹ.

One thought on “Kekere lohun to ṣẹlẹ yii lẹgbẹẹ eyi to n bọ- Tunde Bakare

Leave a Reply