Ketu lọwọ ti tẹ awọn ọmọkunrin yii, adigunjale ni wọn

Faith Adebọla, Eko

Ọsan oni, ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ni Kọmiṣanna ọlọpaa ipinlẹ Eko, Ọgbẹni Hakeem Odumosu, ṣafihan awọn gende marun-un kan lọfiisi rẹ n’Ikẹja, o ni gbewiri ni wọn, agbegbe ibudokọ Ketu, nijọba ibilẹ Koṣọfẹ, lọwọ ti ba wọn, lẹyin ti wọn ja awọn ọkunrin meji kan lole nibẹ.

Orukọ awọn maraarun ni: Ọlasunkanmi Oyewọle, Quadri Lawal, Abraham Ọlatẹju, Tunde Bello ati Ọlagoke Adewọle. Ọjọ ori awọn maraarun ko ju ọdun mẹẹẹdogun si mẹẹẹdọgbọn lọ.

Odumosu ni ọjọ Ẹti, Furaidee, ọjọ kẹsan-an, oṣu yii, lọwọ kọkọ ba meji ninu wọn, lẹyin ti wọn ṣẹṣẹ ja ọkunrin kan ti wọn ko fẹẹ darukọ ẹ lole, wọn gba foonu atawọn dukia ẹ.

Ọjọ Aje, Mọnde yii, lọwọ awọn ọlọpaa ba awọn mẹta to ku ti wọn jọ n ṣiṣẹ buruku naa.

Odumosi ni iwadii ti bẹrẹ lori wọn, oun yoo si ri i pe awọn wọn wọn de kootu laipẹ.

O tun fi kun un pe oun ti ṣagbekalẹ ikọ ọlọpaa akanṣe kan ti yoo maa lọ kaakiri awọn ọna Eko lati gbogun ti awọn kọlọransi ẹda ti wọn ba fẹẹ maa huwa ọdaran lawọn oṣu baa-baa-baa ta a wa yii.

Leave a Reply