Ki aṣoju tijọba Ogun ran lọ si Yewa too pada dele, Fulani ti tun paayan mẹfa l’Agbọn Ojodu ati Asá

Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta

 

A o ti i ko Ifa nilẹ, Ifa ti n ṣẹ, lafiwe ohun to ṣẹlẹ lọjọ Aiku, Sannde, ọsẹ yii, ni awọn ilu meji ti wọn n pe ni Agbọn Ojodu ati Asà, nijọba ibilẹ Ariwa Yewa, nipinlẹ Ogun, nibi to jẹ bawọn aṣoju ijọba ṣe n kuro nibẹ bayii lawọn Fulani tun de, ti wọn si paayan mẹfa lẹyẹ-o-ṣọka.

Ijọba Gomina Dapọ Abiọdun lo ran Kọmiṣana fun eto oye jijẹ ati ijọba ibilẹ, Ọgbẹni Afọlabi Afuapẹ, ati Kọmiṣanna feto iroyin, Alaaji Waheed Oduṣilẹ, pẹlu Kọmiṣanna ọlọpaa, Edward Ajogun, atawọn mi-in lọ sawọn agbegbe ti Fulani ti n pa wọn yii, wọn de Ọja-Ọdan, Igua atawọn ilu mi-in, wọn si sọ fawọn eeyan naa pe awọn waa fi wọn lọkan balẹ pe kinni kan ko ni i ṣe wọn mọ ni.

Ọjọ Sannde naa ni wọn sọ fawọn eeyan pe laarin ọjọ mẹta pere, wọn yoo ri ikọ alaabo ti yoo waa jokoo ti wọn, ti wọn yoo maa ṣọ wọn tọsan-toru, ti aburu kan ko si ni i ṣẹlẹ si wọn mọ.

Ṣugbọn ikọ ijọba yii ko ti i de Abẹokuta ti wọn ti wa pada ti awọn kan ti wọn ni Fulani ni wọn tun fi de. Ni nnkan bii aago mẹjọ alẹ ni wọn de gẹgẹ bi Ọnarebu Haruna Egungbohun to n ṣoju Yewa keji nile-igbimọ aṣofin Ogun, to si gba ikọ ijọba to wa lalejo naa ṣe wi.

O ni ibọn AK47 lawọn Fulani naa gbe wa, bii ọgan ni wọn ti mu eeyan mẹrin balẹ ni Agbọn Ojodu, lọna Igua si Ọja Ọdan ( Ilu naa ko jinna si Iselu)

Ni ti Asa, wọn sun eeyan meji mọle ni gẹgẹ bi Egungbohun ṣe wi, bẹẹ ni wọn dana sun mọto wọn. Njẹ bawo lagbegbe yii ṣe ri bayii, Ọnarebu sọ pe awọn obinrin ti n sa kuro niluu, awọn ọkunrin diẹdiẹ lo ṣẹku nibẹ.

‘‘Mo sọ fun wọn pe oju wa n ri nnkan nibi ( iyẹn awọn aṣoju ijọba to wa), wọn ni to ba maa fi to ọjọ mẹta, wọn maa ko ikọ alaabo wa, mo si sọ fun wọn pe ko too digba naa, ti wọn ba ti pa wa tan nkọ.

‘‘ Wọn o ti i de Abẹokuta ti wọn ti wa pada tawọn Fulani yẹn tun fi de, ti wọn paayan mẹrin ni Agbọn Ojodu, ti wọn tun sun eeyan meji mọle ni Asá, wọn tun dana sun mọto ati ile wọn. Agbẹ ni gbogbo awọn ti wọn dana sun yii, wọn o niṣẹ meji ju iṣẹ agbẹ lọ’’

 

Bẹẹ ni Egungohun ṣalaye f’ALAROYE.

Bakan naa ni Baalẹ Agbọn Ojodu, Oloye Festus Oguntọṣin, sọ pe ọmọ ilu Agbọn Ojodu mẹta, ọmọ Igua kan, ni wọn da lọna, ti wọn pa wọn pẹlu ada, wọn si yinbọn fawọn mi-in.

‘‘Bi mo ṣe n ba yin sọrọ yii, awọn eeyan ti sa kuro niluu yii tan, nitori wọn tun ni awọn maa waa kogun ja wa loru oni naa ( Ọjọ Aje si ọjọ Iṣẹgun) Ẹ o le ri eeyan pupọ mọ lọdọ wa bayii, awọn ọkunrin kọọkan to laya lo ṣi duro, a o si ju bii mẹwaa lọ.

‘‘Wọn tun lọ si Asa, iyẹn ko ju maili kan si ọdọ wa lọ, mo gbọ pe wọn paayan mẹta nibẹ, wọn dana sunle, wọn ati mọto pẹlu maṣinni, ẹ gba wa o, kijọba gba wa o’’

ALAROYE gbiyanju lati ba Baalẹ Asa naa sọrọ, ṣugbọn ko bọ si i.

Bẹ o ba gbagbe, ikọlu iru eyi waye lawọn ilu bii Owode-Ketu ati Orile-Igboro, ni Yewa kan naa, lọsẹ to kọja yii kan naa si ni. Awọn Fulani ni wọn ni wọn wọle tọ awọn eeyan lọsan-an ati lọwọ oru, ti wọn yinbọn pa awọn mi-in, ti wọn si tun ṣa awọn kan pa. Koda, awọn ọmọde paapaa ko bọ lọwọ wọn, wọn ṣa wọn ladaa lori, bẹẹ ni wọn pa awọn obi wọn nibi ti wọn ti n sun lọwọ.

Ọjọ Ẹti to kọja yii nikọlu Orile Igboro waye, nigba ti eyi to ṣẹlẹ l’Owode-Ketu, nibi ti wọn ti ju oku awọn mi-in sodo waye l’Ọjọbọ, ọjọ kọkanla, oṣu keji, ọdun 2021.

Ipaniyan latọwọ awọn Fulani yii ti n waye ni Yewa lemọlemọ lati bii ọsẹ mẹta sẹyin, latigba naa ni wọn ko ti le sun asundọkan mọ, to jẹ kijokijo ni wọn n sa kiri.

Ijọba ipinlẹ Ogun ko yee fi wọn lọkan balẹ ṣa, wọn ni kawọn eeyan ma ṣofin lọwọ ara wọn nipa dida wahala silẹ, niṣe ni ki wọn fi ija naa fun ijọba ja, ko ni i pẹ tawọn ẹṣọ alaabo yoo fi yi wọn ka lati gbeja wọn.

Leave a Reply