Ki alara ṣọra: Ijọba ti bajẹ mọ Buhari atawọn ọmọ ẹ lọwọ o

*Ojoojumọ lawọn Boko Haram n paayan kiri

Ademola Adejare

Ninu ọfọ gidi ni olori orilẹ-ede yii, Aarẹ Muhammadu Buhari, wa; ibanujẹ gidi si ba a. Oun naa lo fẹnu ara rẹ sọ bẹẹ, o ni lati igba ti oun ti gbọ iku awọn mẹtalelogoji ti awọn Boko Haram pa lẹẹkan naa ni abule kan to n jẹ Kwashebe, ni ijọba ibilẹ Jere, ni ipinlẹ Borno, ni inu oun ko ti dun rara.  Bẹẹ ni ki i ṣe Buhari nikan ni inu rẹ bajẹ, ti gbogbo araalu ni, ibanujẹ naa si buru debii pe ọpọlọpọ eeyan lo n bu Buhari ati ijọba rẹ, ti wọn n sọ pe nnkan ti bajẹ patapata laye ijọba yii, eto aabo ti daru, ohun gbogbo si ti bajẹ mọ ijọba Buhari lọwọ. Ọrọ naa le debii pe awọn kan ti bẹrẹ ariwo pe ki Buhari fi ijọba silẹ, nitori o ti han gbangba pe apa rẹ ko ka awọn Boko Haram yii, ati pe bi oun naa ti n pariwo laye ijọba Goodluck Jonathan ree nigba ti awọn Boko Haram n yọ ijọba naa lẹnu. Loootọ si ni, gbangba ni Buhari bọ si nigba naa, to ni afi ki Jonathan gbejọba naa silẹ, ko tete maa lọ.

Oun nikan kọ lo tilẹ sọ ọrọ naa nigba naa, apapọ awọn ẹgbẹ APC gba ẹnu Alaaji Lai Muhammed sọrọ, wọn ni Jonathan ko kapa ijọba to n ṣe, ohun to si jẹ ki awọn ọta maa halẹ mọ ọn naa niyẹn. Bakan naa ni Aṣiwaju Bọla Ahmed sọ ọ, ti oun naa ni o ti to gẹẹ, Jonathan ko le ṣejọba yii, afi ko kọwe fi ipo rẹ silẹ kia. Ohun to waa jẹ ki awọn eeyan maa binu gan-an niyi, nitori gbogbo ohun to n ṣẹlẹ nigba naa, iyẹn laye ijọba Jonathan ti awọn oloṣelu yii n tori rẹ pariwo, ko to ida marun-un ohun to n ṣẹlẹ bayii rara. Ti aye Boko Haram yii le, awọn janduku ti gba gbogbo ilẹ Hausa gẹgẹ bi Sultan Sokoto ti sọ laipẹ yii, ohun ti wọn si n fojoojumọ ṣe nibẹ ko dara. Eyi ti wọn waa ṣe ni ọjọ Satide to kọja yii buru debii pe niṣe ni Gomina ipinlẹ naa paapaa, Babagana Zulum bu sigbe. Ọrọ naa buru.

Zulum ko le ṣe ko ma bu sigbe, nitori niṣe lo sọ fawọn eeyan pe afi ki oun fi oju ara oun ri oku awọn ti wọn pa yii. Nigba ti oun naa si ri i bi wọn ti tẹ oku awọn eeyan lọ bẹẹrẹ, to ri bi wọn ti ge wọn lori lọ salalu, to si ri awọn ti wọn rẹ bii ẹni rẹla, ati iroyin pe titi di asiko naa, awọn obinrin mẹjọ ni wọn ko ti i ri, awọn Boko Haram to waa pa wọn naa lo ko wọn lọ, niṣe lo n miri titi, ti ọrọ kan ko si le jade lẹnu rẹ, bo tilẹ jẹ pe o fẹẹ wi nnkan kan. Nigba ti yoo si jaja sọrọ, ohun ti oun tun wi tun ṣẹru ba awọn eeyan, nitori o ni iroyin ti oun n gbọ fi ye oun pe bii aadọrin (70) awọn eeyan lawọn ọmọ ogun afẹmiṣofo naa pa, ọna kan naa ti wọn si n gba pa wọn ni lati da wọn dubulẹ, ki wọn si du wọn bii ẹran, tabi ki wọn bẹ eyi to ba n ṣagidi lori feu lẹẹkan naa.

Lara ibanujẹ ibẹ si ni pe Musulumi lawọn ti wọn pa yii, bẹẹ bi wọn ti n dumbu wọn ni wọn n ṣe ‘Allau Akbar, ati Bisimilai’, ki wọn too fipa ran wọn sọrun. Gomina Zulum duro ti wọn fi kirun si gbogbo awọn oku naa lara, ti wọn si rọ wọn si koto lẹẹkan naa. ALAROYE gbọ ẹjọ kan pe awọn araadugbo naa mu Boko Haram kan to n yọ wọn lẹnu nibẹ ni, wọn si lu u bii ko ku, ohun to si bi awọn ẹlẹgbẹ wọn ati awọn ọga wọn ninu ree, ti wọn fi lọọ ka awọn eeyan naa mọ oko irẹsi, nibi ti wọn ti n ṣiṣẹ lọwọ, ti wọn si pa wọn nipakupa bẹẹ. Gomina Zulum pe awọn ṣọja ki wọn tun ara mu, diẹ lo si ku ki oun naa pa iru ariwo ti gbogbo araalu n pa pe ki ijọba Buhari le awọn olori ologun rẹ lọ, nitori ko jọ pe wọn ni iṣẹ kan ti wọn n ṣe bayii mọ, ọpọ wọn si ti di oloṣelu, wọn kan ko aṣọ ọga ologun sọrun lasan ni.

Iṣẹlẹ naa ko girigiri ba wọn nile ịjọba Abuja, nitori nibi ti ọrọ naa de duro bayii, ko jọ pe awọn naa mọ ohun ti wọn le ṣe si i mọ, ọrọ naa ti tobi ju wọn lọ. Ọjọ Abamẹta, Satide, ni wọn pa awọn eeyan rẹpẹtẹ loko irẹsi yii, ṣugbọn ni ọjọ Ẹti, ọjọ naa k’ọla, ni awọn ajinigbe da Arabinrin Ale, iyawo Olugbenga Ale, ti i ṣe olori oṣiṣẹ Gomina ipinlẹ Ondo, Rotimi Akeredolu lọna, ti wọn si ji i gbe lọ. Ki wọn too ri i gba lọwọ awọn Fulani ajinigbe naa, ikun imu ọtun bọ si tosi nibi ti wọn ti n ṣọna bi yoo ti jade ninu igbo ti wọn gbe e lọ. Eko lobinrin naa ti n bọ, Akurẹ lo si n lọ, oun ati awọn eeyan rẹ ti wọn jọ n ṣiṣẹ funjọba. Bi wọn ti de Owena lawọn janduku ajinigbe yii fo ja oju ọna, ki oloju si too ṣẹ ẹ, wọn ti gbe obinrin naa ati ọrẹ rẹ wọ inu igbo lọ. Awọn Amọtẹkun ni wọn bẹrẹ iṣẹ nla ko too di pe wọn ri obinrin naa mu jade.

Bẹẹ lọjọ ti iṣẹlẹ naa ku ọla, iyẹn ni Ọjọbọ, Alamisi, ọjọ kẹrindinlọgbọn, oṣu kẹwaa, to ṣẹṣẹ pari yii, awọn ajinigbe yii yinbọn pa ọkan pataki ninu awọn ọba ilẹ Yoruba, Olufọn ilu Ifọn, Ọba Israel Adewusi. Ipade lọbalọba ni kabiyesi naa lọ niluu Akurẹ, nigba to si n pada lọ siluu ẹ ni awọn ajinigbe naa mura lati da a lọna ni Ẹlẹgbẹka. Ṣugbọn dẹrẹba ọba naa ri wọn, kia lo si mura lati sa mọ wọn lọwọ. Nibi to ti n sa lọ yii ni inu ti bi awọn Fulani ajinigbe naa, ni wọn ba da ina ibọn bolẹ, wọn si yinbọn naa titi ti ọta fi ko si Ọba Adewusi lagbari. Wọn gbiyanju lati gbe ọba naa lọ si ọsibitu lẹyin iṣẹlẹ naa, ṣugbọn nigba ti wọn yoo fi de ọhun, ọba yii ti waja, ko si si aapọn kankan ti awọn ara ọṣibitu naa le ṣe si i. Bẹẹ ni ọkan ninu awọn aṣaaju ọba Yoruba ku sọwọ awọn Fulani ajinigbe.

Iyẹn ni wọn n sọ lọwọ nigba ti ariwo iku Ẹni-ọwọ Johnson Ọladimeji naa tun gbode. Lati Ekiti ni iroyin iku naa ti jade wa, o si ya gbogbo eeyan lẹnu pe kin ni ojiṣẹ Ọlọrun naa tun ṣe. Rẹfurẹẹni yii ni olori ijọ Solution Baptist, to wa ni Ikẹrẹ-Ekiti, iṣẹ iranṣẹ pataki kan lo si gbe e lọ si ipinlẹ Ọṣun, nibi to si ti n dari bọ ni awọn ajinigbe ti tun jade lati mu un ṣinkun, o si jọ pe nibi to ti n sa fun wọn ni wọn ti da ina ibọn bo oun naa, ti wọn si pa a ko to ribi sa lọ. Nigba ti awọn eeyan ko ri i, wọn wa a titi, ko too di pe wọn kan mọto rẹ ni ọna Igbara-Odo yii, nigba ti wọn si ri oun funra rẹ ninu mọto ọhun, o ti ku pata, bẹẹ ni ọta ibọn si kun ara rẹ kitikiti. Bẹẹ lo ṣe pe ati ọna Ondo o, ati ọna Ekiti, ati ọpọlọpọ ibi nilẹ Yoruba, ko si ibi ti awọn janduku ajinigbe yii ko ti gbilẹ si, ojumọ kan, wahala kan, si ni.

Ohun ti awọn eeyan n sọ kaakiri naa ni pe ijọba orilẹ-ede yii ni ko mojuto ọrọ naa bo ti yẹ, o si jọ pe awọn ni wọn n fọwọ pa awọn Fulani ati janduku yii lori, ti wọn fi n raaye ṣe ohun ti wọn ṣe. Ọpọ awọn Boko Haram ti ijọba ba ri mu, awọn ijọba yii naa lo maa n fi wọn silẹ, ohun ti wọn si n sọ ni pe wọn ti ronupiwada, wọn yoo waa tọju wọn lẹyin naa, wọn yoo fun wọn lowo to pọ, wọn yoo si to wọn si ipo eeyan pataki, awọn yii yoo si maa jaye ọba. Nidii eyi, awọn eeyan ti wọn n binu sọ pe ijọba Buhari funra rẹ lo n mu iṣẹ ifẹmiṣofo yi wu awọn ọdọ ilẹ Hausa i ṣe, pe wọn ti mọ pe lara iṣẹ ti awọn le ṣe ti awọn yoo fi di ọlọla tabi eeyan pataki lawujọ ni, nitori bi awọn ba ti paayan diẹ, awọn le pada waa sọ fun ijọba pe awọn ti ronu piwada, ki awọn si jẹ anfaani oriṣiiriṣii tijọba ti ko silẹ fawọn.

Ohun to fa a niyi to jẹ pe nilẹ Hausa, bo tilẹ jẹ ijọba ko yee royin iye ti awọn n na lori eto aabo, ati lati ba awọn Boko Haram jagun, kaka ki kinni naa dẹ, niṣe lo n le koko si i, o si ti han gbangba pe apa ijọba yii ko ka Boko Haram mọ, ohun to si le ṣẹlẹ nigbakigba ko ye ẹnikan. Idi ni pe rogbodiyan ti yoo ti ibi ipaniyan awọn Boko Haram yii wa yoo le pupọ, nitori awọn ti wọn n ṣiṣẹ agbẹ ni wọn pọ ju lapa agbegbe naa, nigba ti ọrọ si ti di ka maa lọọ ka awọn agbẹ mọ inu oko, ka si maa dumbu wọn yii, ọpọ awọn eeyan naa ni wọn lawọn ko le lọ si oko mọ. Nitori iru iṣẹlẹ yii ni ko ṣe sẹni to fẹẹ da lọ soko laduugbo naa rara, wọn maa n fẹẹ rin ni ọwọọwọ, bii ogoji, bii aadọta, ko ma di pe awọn afẹmiṣofo naa yoo kọ lu wọn ni. Ṣugbọn pẹlu ẹ naa, awọn apaayan naa lọọ ka wọn mọ oko, bi wọn si ti pọ to naa ni wọn fi pa wọn to.

Ko i pẹ rara ti gbogbo ilu tun dide biba, ti wọn n pariwo pe ki Buhari yọ awọn olori ologun wọnyi kuro lẹnu iṣẹ wọn, nitori wọn ko ni iwulo kan ti wọn n ṣe lori ọrọ awọn afẹmiṣofo yii mọ, o jọ pe kinni naa ti tobi ju wọn lọ.  Ko sẹni to tun le la ọrọ naa mọlẹ ju olori ile-igbimọ aṣoju-ṣofin, Fẹmi Gbajabiamila, lọ. Nigba tiroyin jade pe wọn tun pa ogoji eeyan ni Borno, ohun to sọ ni pe o yẹ wayi ki awọn ṣọja wa ṣe iṣẹ wọn bii iṣẹ, ki wọn jade, ka le mọ pe loootọ la ni awọn jagunjagun. Ọkunrin olori awọn aṣofin naa ni o buru pe ilu to lọba to ni ijoye, ti olori ilu si wa nibẹ, awọn kan yoo dide lojiji, wọn yoo si lọọ pa awọn ọmọ orilẹ-ede yii bẹẹ yẹn lai nidii, ti wọn yoo si ṣe kinni naa ti wọn yoo mu un jẹ. O ni ọrọ naa fidi ariwo ti wọn ti n pa lati ọjọ yii mulẹ, pe awọn ṣọja wa, awọn ologun ta a ni, gbọdọ dide ki wọn ṣe iṣẹ wọn bii iṣẹ.

Bi oun ti sọrọ yii, bẹẹ ni olori ile-igbimọ aṣofin agba, Ahmad Lawan naa wi, o ni ọrọ ipaayan yii ko daa rara, paapaa lasiko ti kaluku n wo iyan to n bọ lọọọkan nitori awọn ohun to n ṣẹlẹ kaakiri. O ni afi bi eeyan yoo ba tan ara ẹni jẹ, ko si ohun meji ti awọn ologun wa gbogbo yoo ṣe bayii ju ki wọn wa gbogbo ọna lati fi agbara kun agbara wọn, ki wọn si dide wuya lẹẹkan naa lati koju awọn Boko Haram yii, ki wọn le wọn jinna si Naijiria. Ohun ti Lawan naa n fọgbọn sọ ni pe awọn ṣọja ti a ni ko ṣe iṣẹ wọn bii iṣẹ. Ko si ohun meji ti i fa iru eleyii ninu iṣẹ ologun ju pe bi olori ba ti ṣe ri bẹẹ naa ni ero ẹyin yoo ri lọ. Bẹẹ akọkọ kọ niyi ti olori ile-igbimọ aṣofin agba yii yoo sọ bẹẹ, ọpọ igba ti awọn Boko Haram ba ti pa awọn eeyan ni ipakupa bayii naa ni yoo jade lati sọ pe awọn ologun wa ko ṣe daadaa to.

Bi iku ba n pa ojugba ẹni, owe ni iru iku bẹẹ n pa fun ni. O fẹrẹ jẹ ohun to ṣe awọn gomina gbogbo ni Naijiria ree, nitori awọn naa jade, wọn ni o ti debi ti elewe n ja a, ti oloogun si gbọdọ sa a bayii, ki ijọba apapọ mọ bi yoo ti ṣe ọrọ awọn afẹmiṣofo yii si, nitori ọwọ Buhari funra rẹ ni agbara wa lati yanju iṣoro ọhun. Bi wọn ko tilẹ fi gbogbo ẹnu sọrọ, awọn naa ni ohun to ṣẹlẹ ni Kwashebe, ipinlẹ Borno yii, tun jẹ keeyan ronu pe ṣe eto aabo ilẹ yii dara tabi ko dara, ṣe awọn agbofinro ati awọn ologun wa n ṣe iṣẹ wọn bii iṣẹ tabi wọn ko ṣe e. Olori ẹgbẹ awọn gomina yii funra rẹ, Ọmọwe Kayọde Fayẹmi, lo fọwọ si iwe yii lorukọ awọn gomina to ku, bo si tilẹ jẹ pe o fi han pe awọn gomina yii binu si iwa ika buruku bayii, ohun ti wọn n beere naa ni pe nijọ wo ni apa awọn ologun, tabi apa ijọba Buhari yoo ka awọn Boko Haram.

Bo ba ṣe pe Aarẹ Buhari gbọ ọrọ ti awọn eeyan ilu n sọ ni, yoo ti paarọ awọn olori ologun gbogbo to n ba a ṣiṣẹ yii, yoo si ti fi awọn ẹjẹ tuntun mi-in rọpo wọn. Awọn ti wọn mọ nipa eto aabo ilu ati orilẹ-ede ti n sọ ọ tipẹ pe nigba ti ogun kan ba wa, to n ja ilu tabi agbegbe kan fun bii ọdun meji mẹta, ogun naa ni ọwọ awọn araale ninu ni. Loootọ ijọba n sọ pe awọn n gbiyanju, ṣugbọn awọn paapaa ko le sọ pe awọn ko ri i pe iyanju awọn yii ko de ibi kankan. Gẹgẹ bi ẹgbẹ awọn gomina ti wi, bi gbogbo ilu kan ba n wo o pe ogun Boko Haram ti fẹẹ pari, nigba naa ni awọn eeyan naa yoo tun dide wuya, ti wọn yoo si ṣe ohun to buru ju eyi ti wọn ti n ṣe tẹlẹ lọ. Bẹẹ ni bi eeyan ba gbọ ọrọ to jade lati ẹnu Sultan, Ọba Sokoto, yoo mọ pe awọn eeyan yii ko fi kinni naa bo rara, bẹẹ ni wọn ko sa fun awọn agbofinro.

Sultan Sa’ad Abubakar sọ pe ni gbangba, laarin ọja, ati laarin ilu, lawọn Boko Haram yii ti n gbe ibọn rin lojumọmọ, ti wọn n raja ni tipatipa, nitori iye to ba wu wọn ni wọn yoo san fun ọlọja, tabi ki wọn tile mu ọja to wu wọn lai sanwo rara. Bi eleyii ba n ṣelẹ lojumọmọ bẹẹ, nibo ni awọn ṣọja ti ijọba ni awọn n nawo le lori wa? Ohun ti ọpọ awọn araalu n beere niyi. Nidii eyi ni wọn si ṣe n pariwo pe o ti yẹ ki Buhari, awọn olori ṣọja ati ọmọ ogun to ku lọ tipẹ, nitori ko si ọgbọn tuntun ninu wọn mọ, o jọ pe awọn Boko Haram yii ti mọ gbogbo ọgbọn to wa ninu wọn. Ṣugbọn Buhari ko le wọn, ko si sọ idi ti oun o fi le wọn. Bẹẹ ni ohun gbogbo n daru, bẹẹ ni ohun gbogbo n bajẹ mọ ijọba rẹ lọwọ, ko si si ohun ti araalu le ṣe mọ, afi ki alara ṣọra, ki ọlọmọ kilọ fọmọ ẹ, awọn Boko Haram gbajọba mọ Buhari lọwọ poo!

Leave a Reply