Ki alara ṣọra o, awọn ọmọ Hausa n ba Yoruba ja ni Fagba, Eko

Iroyin to n jade bayii ko daa rara, afi ki alara ṣọra ẹ gidi o. Ohun ti Alaroye gbọ ni pe awọn ọmọ Hausa ni agbegbe Fagba, ni Iju Ageege, lEkoo, ti n ba awọn Yoruba adugbo naa ja o, ija naa si ti fẹẹ maa le ju ohun ti apa ka lọ, nitori iṣoro ni lati jade lagbegbe naa bayii, kaluku tilẹkun mọri ni.

Lati ijẹrin ni ija ti bẹre ni adugbo naa, lasiko ti wọn ni awọn mọla gbe mọto kan to ko ẹran wọle latilẹ Hausa. Maaluu lo kun inu mọto naa, ṣugbọn wọn ko ribi kọja nitori ti wọn ti gbegi dana, ti awọn ọdọ to n ṣewọde ko si jẹ ki ẹnikẹni lọ, ṣugbọn lẹyin ti awọn Hausa naa lọ si odo-ẹran (abatọ), ti wọn lọọ ko ogunlọgọ awọn mọla ẹgbẹ wọn wa, ti ọrọ naa si fẹẹ dija nla, awọn ọdọ jẹ ki mọto yii lọ.

Ṣugbọn awọn mọla yii pada wa lanaa lasiko isede, wọn si bẹrẹ si i fọ ṣọọbu, wọn n jale gidi ni, awọn obinrin ati ara agbegbe naa si bẹrẹ si i gbe ohun o n ṣẹlẹ naa sori fidio, ti wọn pariwo pe ki awọn agbofinro waa gba oun. Niṣe lawọn eeyan naa si ro pe awọn mọla yii ti lọ, afi bi wọn ti ṣe tun de si adugbo naa loni-in pẹlu oriṣiriṣi ohun ija, ija naa si n lọ nigba ti wọn fi iroyin yii to wa leti.

 

One thought on “Ki alara ṣọra o, awọn ọmọ Hausa n ba Yoruba ja ni Fagba, Eko

  1. Emi gege bi enikan ohun tonsele yi kodun man mi rara koda opamilekun gidi gidi awa nan lamanbu awan olowo wa wipe wan o da ile ise sile si ilu abini bi wan ewawo biwanse ba dukia asiwaju je omo Yoruba eje karonhun nibo lanlo,

Leave a Reply