Ki Bisi mura si i, ki Bọla naa mura si i

ỌMỌỌDỌAGBA

Ohun to ṣẹlẹ lọsẹ to kọja yii ki i ṣe tuntun. Ohun ti mo sọ fun gbogbo awọn ti wọn n fi foonu daamu mi, ati awọn ti wọn n wa mi wa lati igba ti wọn ti gbọ ohun to ṣẹlẹ, ati bawọn oniweeroyin ti n gbe kinni ọhun jade. Ohun kan naa ti mo n sọ fun wọn niyẹn, iyẹn naa ni pe ki i ṣe tuntun. Ki i ṣe tuntun rara. Pe Bisi (Akande) kọwe, o fi bu gbogbo awọn aṣaaju ẹ nidii oṣelu, pe o kọwe, o fi tabuku wọn, tabi pe o kọwe, o fi n yin aṣaaju awọn Fulani to n ṣejọba lọwọ, bẹẹ lo fi n fọ ilẹ Yoruba si wẹwẹ, ohun to ṣẹlẹ naa ki i ṣe tuntun. Nigbakigba ti awọn Fulani ba ti wọ aarin wa, ti wọn ba ti ri awọn kan mu ninu wa, agaga nigba ti wọn ba ri i pe ẹ ti n ṣeto iṣọkan laarin ara yin, bi awọn ti wọn ba mu ṣe maa n huwa naa lẹ n ri yii: Ohun tawọn ara iṣaaju ṣe to fa Yoruba sẹyin titi di asiko yii ni Bisi ati Bọla n ṣe ti ẹ n ri yii. Ki i ṣe tuntun.

Awọn Fulani ti mu wọn, wọn ti ga wọn lọrun, wọn ti tan wọn, wọn ti purọ ohun ti ko ni i ṣẹlẹ fun wọn, iyẹn lẹ ṣe n gbọ gbogbo isọkusọ yii, ti ẹ n ri gbogbo palapala to n ṣẹlẹ laarin awọn Yoruba. Bisi wa laye lati bii ọdun marun-un nilẹ yii, ki i ṣe pe ọjọọbi kan pataki lo n ṣe tabi pe o n ṣe kinni kan to fi le da bii pe wọn fẹẹ fun un ni iyi tabi ẹyẹ, iwe lo ni oun kọ, bi iwe kikọ ṣe waa di ohun to la wahala bayii lọ ni ko ni i ye awọn ti ko ba mọ awọn araabi yii, ti wọn maa ro pe nnkan ti ko le kan ni. Amọ o le ju bẹẹ lọ, nitori ohun to n ṣẹlẹ yii ye iru awa. Nigba ti awọn Fulani yii ba fẹẹ mu wa, ẹni kan to lagbara ju ninu wa nidii oṣelu naa ni wọn maa kọkọ mu, tabi ki wọn mu ẹni to ba sun mọ ọn ju lọ, wọn aa bẹrẹ si i tan an, wọn aa maa kọrin, ‘a o merin jọba, ẹwẹkuẹwẹlẹ’ fun un. Ṣugbọn bi wọn ṣe ṣe erin ti wọn gbẹ koto jinjin ti wọn ti i si i, bẹẹ naa ni wọn maa ṣe fawọn naa. Ki i ṣe tuntun.

Nitori pe Bọla fẹẹ di aarẹ, ẹtan ti awọn Fulani gbe le e lọwọ ree o, Bisi si ni wọn fẹẹ fi ṣe Baba isalẹ ẹ, ko si le ṣe baba isalẹ ti ko ba ba awọn agbaagba to ku jẹ, ko purọ mọ wọn, ko si ta ko wọn, ohun to ṣe kọwe tuntun lasiko yii ree, lasiko ti ibo n kanlẹkun, ki gbogbo Yoruba le ro pe awọn ti ri awọn eeyan gidi kan. Ṣugbọn wọn ki i ṣe eeyan gidi! Ọlọrun n gbọ, wọn ki i ṣe eeyan gidi! Awọn mejeeji ti wọn wa nidii ọrọ yii, ati Bọla ni o, ati Bisi ni o, wọn ki i ṣeeyan gidi. Bi ẹ ba ranti daadaa, lasiko ti ibo n bọ lọdun 2015, gbogbo alaye yii ni mo ṣe fun yin, mo sọ fun yin bawọn mejeeji yii ṣe jẹ ẹlẹtan, ati amuni-lọwọ-fẹkun-pa-jẹ, ọpọlọpọ yin lẹ ni nitori pe mo koriira Buhari ni, n ko fẹran Bọla ni, mo lodi si Bisi ni mo ṣe n sọ gbogbo ohun ti mo n sọ. Awọn yii ni wọn wa sibi ti wọn gbe Buhari waa ba wa. O ku sọwọ yin bayii lati ronu ara yin wo, bo ba jẹ oore ni wọn ṣe wa ni tabi ibi.

Awọn ni wọn gbe Buhari wa, gbogbo bi Fulani si ti ṣe n paayan, ti wọn fẹẹ fi ipa gba gbogbo ilẹ wa, ti wọn n laalaṣi wa, ti wọn n pa awọn eeyan wa loko wọn, ti wọn si fi iṣẹ maaluu silẹ ti wọn ko ṣe mọ, to jẹ awọn eeyan wa lo ku ti wọn n ji gbe, Bisi wa nibẹ ko ku, Bọla wa nibẹ ko lọ sibi kan. Sugbọn wọn o le gbeja Yoruba, koda, wọn o le sọ pe awọn lawọn mu ọkunrin yii waa ba yin, ẹ ma binu, a o pada lọọ ba a sọrọ, wọn fi gbogbo iran Yoruba yii silẹ funya jẹ ni. Ti Bisi ba lanu, ati Bọla paapaa, tawọn mejeeji ba lanu pe awọn aṣaaju Afẹnifẹre gba owo kan tabi hu iwa kan ti ko dara, awọn ibeere kekere ni ki ẹ bi wọn, ti ẹ ba ti le ri ẹni dahun awọn ibeere naa, ki ẹyin fi itumọ tiyin kun un. Njẹ ẹ mọ pe ninu gbogbo iwe ti Bisi kọ yii, ko ṣalaye ohun kan ti oun ṣe ti ko dara, bẹẹ ni ko si ohun ti Bọla ṣe loju ẹ to ku diẹ kaato, ohun gbogbo ti Bọla ati oun Bisi ṣe lo dara ju lọ.

Ẹ beere lọwọ Bisi ti ẹ ba ri i, ẹ bi i pe nigba to fẹẹ du ipo gomina ni ọdun 1999, ile meloo lo ni, ati eelo lo wa lọwọ ẹ. Ọkunrin ti ẹ n wo yii ko nile ni Ila, ko si ni ni Eko, Ibadan to si n gbe naa ki i ṣe pe ile nla kan wa nibẹ to kọ sibẹ, o kan n tirogo kiri ni. Nnkan le fun un debii pe ko ni owo to fi le gba fọọmu, iyẹn owo ti awọn ti wọn fẹẹ ṣeto idibo ni ki wọn san. Owo fọọmu ẹ, Iyiọla Omiṣore lo san an, iyẹn aburo wa ọmọ Ileefẹ yẹn. Bi Bisi ba si ti gbagbe, ki n ran an leti. Moji (Akinfẹnwa) lo ṣeto naa, oun lo ni ki Iyi duro, ko jẹ kawọn lo owo ti oun fẹẹ fi gba fọọmu tẹlẹ, ki wọn lo owo fọọmu tiẹ fun Bisi. Ariwo ti Bisi n pa ni pe oun ti sọ tẹlẹ pe ko si owo lọwọ oun o, ko si sibi ti oun ti fẹẹ ri owo o, oun o lowo kankan lọwọ. Bisi ko mọ bawọn Moji ati Iyi atawọn mi-in ṣe ri owo ti wọn fi ṣe kampeeni fun un, nitori ko lowo lọwọ loootọ.

Ọrọ ohun le fun un debii pe ko si mọto to le maa lo lati fi ṣe kampeeni, bo tilẹ jẹ pe ẹgbẹ AD ti fa a kalẹ pe kawọn araalu dibo fun un. Iyi yii naa lo gbe mọto mẹta kalẹ, ninu ẹ ni wọn ti fun un ni ọkan ti yoo maa da gun, tabi to le lo nigba mi-in lati fi lọ sibi to ba fẹẹ lọ. Bi wọn ṣe ṣe titi to fi wọle niyi. Loni-in ti mo wa n sọrọ yii nkọ, ile ti Bisi kọ si ilu ẹ ni Ila, o loju olowo to n ṣiṣẹ loju mejeeji to le kọ ọ. Nibo ni ki tọhun ti ri iru owo bẹẹ: ile gbaramu gbaramu ti ọkunrin ti ko lowo lati gba fọọmu lati fi du ipo gomina naa kọ ni bii ọdun kejila sẹyin. Bisi ni ile nla ni Ogudu, l’Ekoo, o si ti tun ni ile mi-in ni Lẹkki, lasiko ti nnkan bẹrẹ si i ṣenuure. Awọn ile ti aye mọ niyi, awọn mi-in wa ti ko sẹni to mọ, nitori ile akọta ni wọn. Laarin iwọnba asiko kekere yii, nibo loun ti ri owo to fi ṣe gbogbo ohun to ṣe yii, tabi ileeṣẹ wo lo da silẹ ti ko ni tẹlẹ ko too di gomina, to waa jẹ lẹyin to ṣe gomina tan lo bẹrẹ si i kọle kiri.

Ki lohun to fa ija ajaku-akata ti Ọọni Okunade Ṣijuwade ba Bisi yii ja, to fi jẹ pe Bisi ko to ẹni ti i wọ aafin Ọọni titi ti ọba naa fi waja. Ki lo fa ija Ọọni ati ẹ, ko ṣalaye ẹ! Awọn ọrọ wa teeyan maa ṣi lawẹlawẹ lati fi oju awọn onibajẹ yii han, kawọn araalu too ṣi wọn mu lẹẹkan si i. Bo ba si jẹ ti Bọla funra ẹ ni, nigba to pada delẹ yii ni ọdun 1998, ile ẹyọ meji lo ni, oun funra rẹ lo si jẹwọ pe oun ti ta ọkan ninu ẹ lati ri owo idibo oun ko jọ. Lonii yii, ẹni to ba fẹẹ ka ile Bọla, oluwa rẹ yoo ṣe iṣẹ aṣeṣulẹ ni, owo ti pọ lọwọ ẹ debii pe mọto agboworin loun naa fi n gbe owo kiri. Iṣẹ wo ni Bọla ṣe. Gbogbo owo to n ko fawọn Fulani ti wọn n tan an yii, nibo lo ti ri owo naa! Ohun ti oun ko si mọ, ti Bisi naa ko lọgbọn ẹ lori, ni pe nigba ti ọrọ ba de oju ẹ fun un tan, awọn ti wọn maa gba a mu niyẹn.

Wọn n tan an bayii, oun naa n gba ẹtan, wọn gba a laaye ko maa nawo Eko lọ, oun naa si n na an lọ, asiko n bọ ti wọn maa beere awọn nnkan wọnyi lọwọ ẹ, ohun to si maa le e nidii ipo to n wa yii niyẹn. Sibẹ naa, ko si ohun to buru ninu keeyan mura lati de ipo kan, iwa ojale-onile-bo-tiẹ-lẹyin ni, ko dara. Kin ni Bisi n ba awọn eeyan jẹ nitori pe o fẹẹ ṣe atilẹyin fun Bọla si! Ki lo n sọsọkusọ si awọn aṣaaju to ku si nigba ti ọwọ oun naa ko mọ, to jẹ akisa ẹlẹgbin ni bo ṣe n rin kiri yẹn. Ọpẹoyinbo fi dundun ṣẹwa, ẹgun to wa lara ẹ ko wa le legbeje. Ida lo maa pe ara ẹ lẹru, to ba ya, awọn kan aa ni ọmọ Yoruba lo fẹẹ du ipo aarẹ, ki wọn gbaruku ti i, awọn yii ko ri i lasiko ti awọn adamọdi ọmọ Yoruba ti wọn n wa ipo lọwọ Fulani n ba iran tiwa jẹ yii o. Ki Bisi mura si i, ki Bọla naa si mura si i. Baluwẹ to ni oun maa di odo nla ni o, oju gbogbo wa lo maa ṣe.

Leave a Reply