Ki Buhari kuro nipo lai fakoko ṣofo, o to gẹẹ-Abubakar Gumi

Faith Adebọla

Ilu-mọ-ọn-ka aṣaaju ẹsin Musulumi lapa Oke-Ọya nni, Sheikh Abubakar Gumi, ti takoto ọrọ ṣọwọ si olori orileede wa, Muhammadu Buhari, pe ko sohun to pọn ọn le lasiko yii ju ko kọwe fipo silẹ, ko si kuro lori aleefa Aarẹ Naijiria, latari bi ifẹmiṣofo ati itajẹsilẹ ṣe n peleke si i lorileede yii.

Gumi ni o ti han gbangba pe apa Aarẹ Buhari ko ka a lati daabo bo awọn ọmọ Naijiria, pẹlu bawọn janduku agbebọn ṣe n da ẹmi awọn eeyan legbodo lojoojumọ.

Olukọ ẹsin Islam naa ṣọrọ yii nigba to n ba awujọ awọn ẹlẹsin Musulumi kan sọrọ lọjọ Iṣẹgun, Tusidee yii.

O loun ko ṣẹṣẹ maa gba awọn olori lamọran nipa ohun to yẹ ki wọn ṣe, o loun fun aarẹ tẹlẹ ri, Goodluck Jonathan, lamọran pe ko kọwe fipo silẹ nigba ti apa rẹ ko ka ifẹmiṣofo to waye lasiko iṣejọba rẹ, ṣugbọn akiyesi oun ni pe ijọba Buhari yii ko tiẹ tẹle ilana ijọba awa-ara-wa to ti Jonathan, bo tilẹ jẹ pe ‘Bọọda oun’ lo wa nipo, gẹgẹ bo ṣe sọ.

“Lasiko iṣẹjọba Jonathan, ti ẹjẹ bẹrẹ si i ṣan bii omi, mo ta ko o tori ko gbe igbesẹ to yẹ. Idi ti mo fi da Jonathan lẹbi ni pe awọn Boko Haram kan n ju bọmbu kaakiri ni, ijọba rẹ ko si sapa to lati dẹkun ẹ.
Bakan naa lọrọ ri lasiko yii, itajẹsilẹ ati ifẹmiṣofo ti asiko yii tiẹ tun legba kan si ti asiko ijọba Jonathan, iwọ naa ro o wo. Ẹsin wa, ẹsin ododo ni, a gbọdọ sododo fun ara wa. Lasiko Jonathan, ẹjẹ n ṣan ni ṣọọṣi, ni mọṣalaaṣi, loju popo, mo si sọ fun un pe ko kọwe fipo silẹ tori agbara ẹ ko gbe e lati dẹkun ẹ. Mo ni ko yaa kọwe fipo silẹ lo tọ.

Nigba tawọn eeyan ba n ku kaakiri, ti Aarẹ atawọn gomina wa si n lọ si pati igbeyawo atawọn ibi ayẹyẹ, iwa aibikita ati idagunla gbaa niyẹn. Bi mo ṣe le sọ fun Jonathan pe ko maa lọ, mo gbọdọ le sọ bakan naa fun Aarẹ Buhari. Mo fẹ kẹyin oniroyin gbe e, ẹ jẹ ki Buhari kuro nipo lai fakoko ṣofo, o to gẹẹ.

Koda bi a ṣe sọ pe ijọba Jonathan o daa to, o si ṣe nnkan lọna to ba dẹmokiresi mu ju eyi lọ.”

Gumi ni o yẹ koun tọrọ aforiji lọwọ Goodluck Jonathan. O loun ko ri idi kan lati fara mọ ijọba to wa lode yii, ki Buhari tete maa lọ lo yẹ.

Leave a Reply