Jide Alabi
Wahala buruku lo n ṣẹlẹ laarin awọn ọba alaye meji yii, Ọọni Ile Ifẹ, Ọba Adeyẹye Ogunwusi, ati Eselu ti ilu Iselu, Ọba Akintunde Akinyẹmi, lori ipade ti Arole Oodua lọọ ba Aarẹ Muhammadu Buhari ṣe niluu Abuja laipẹ yii.
Ifọrọwerọ kan ni wọn sọ pe Ọba Iselu ṣe pẹlu ileeṣe iroyin kan, nibi to ti ṣeleri atilẹyin ẹ fun Oloye Sunday Igboho, ṣugbọn lara ohun ti Kabiesi Iselu sọ bọ si apo ibinu Arole Oodua, Ọba Adeyẹye Ogunwusi, eyi to fa bi wọn ṣe n ta ohun sira wọn bayii.
Ohun ti wọn lo kọkọ da wahala ọhun silẹ ni bi awọn eeyan Yewa, nipinlẹ Ogun ṣe kọkọ le awọn Fulani darandaran kuro lagbegbe wọn, ṣugbọn ti awọn ṣọja ti wọn wa ni adugbo kan to n jẹ Alamala, lẹgbẹẹ Abẹokuta, tun sin wọn pada si agbegbe ọhun pelu ibọn lọwọ, ti awọn eeyan naa ko si ri ohun kan bayii ṣe, bi awọn maaluu ṣe n jẹ’ko, ti wọn si tun duro ti wọn nibẹ.
Bi iroyin iṣẹlẹ naa ṣe gba ode kan ni Kabiesi Ọba Iselu ti ba ileeṣẹ iroyin kan sọrọ, to si ṣeleri atilẹyin fun Sunday Igboho lori ipa ẹ lati gba iran Yoruba silẹ lọwọ jọgọdi awọn Fulani.
Ko pẹ to ṣe bẹẹ naa ni Oloye Sunday Adeyẹmọ, ẹni tawọn eeyan tun mọ si Igboho Ooṣa paapaa yọju si Kabiesi yii, to si rọ ọba naa atawọn yooku ti wọn wa ni ipinlẹ Ogun ati ilẹ Yoruba lapapọ lati ma ṣe faaye gba awọn to le maa ko idaamu ba awọn eeyan ti wọn n ṣelu le lori lagbegbe wọn.
Bi iroyin ti kabiesi ṣe yii ṣe gba igboro kan, ni Ọba Ẹnitan Ogunwusi, Ọọni Ile-Ifẹ, ti fi atẹjiṣẹ ranṣẹ si i, nibi to ti sọ pe oun gan-an ni Ọba Iselu pede abuku si ninu ifọrọwerọ to ṣe pẹlu ileeṣẹ iroyin naa.
Ọọni sọ pe ede abuku ti Eselu pe si oun ko ju ibi to ti mẹnuba ọrọ ọba alaye to ṣẹṣẹ lọọ ri Aarẹ Buhari lọ. Bẹẹ ni Arole Oodua ki Ọba Iselu nilọ ko ṣora ẹ gidigidi ti ko ba fẹẹ ri wahala oun.
Arole Oodua ninu atẹjiṣẹ ẹ sọ pe, “Ọba wo lo ṣẹṣẹ ti ilu Abuja de nilẹ Yoruba. O ṣe pataki ki a maa mọ hulẹhulẹ ọrọ ki a too ṣọ ohun ti oju wa ko to, paapaa awọn ọrọ ti ko ba ṣoju wa.
“Ẹledaa awọn irunmọlẹ ni yoo da a fun mi to ba jẹ pe ohun ti mo lọọ ṣe ni Abuja yatọ si ̀ọrọ ilẹ Yoruba, bakan naa ni mo tọrọ ki Ọlọrun dajọ awọn to n sọ ohun ti oju wọn ko to nipa mi.”
Ṣa o, bi Ọọni Adeyẹye ti sọrọ yii tan naa ni Ọba Akinyẹmi naa ti fesi pada, to si sọ pe iwa ti Ọọni hu ku diẹ kaato lori bo ṣe kọ lu oun lori ọrọ naa. O ni ohun to dun oun ninu ọrọ yii ko ju bi Ọọni ṣe kuna lati duro sipo nla ti oun to o si gẹgẹ bii aṣaaju awọn ọba alaye nilẹ Yoruba.
Ọba Akinyẹmi ninu atẹjiṣẹ ẹ sọ pe: “Ẹ kaaarọ, Kabiyesi, Alayeluwa. Kabiyesi, ipo nla ni mo to yin si, Ọlọrun to ṣẹda wa paapaa mọ bi mo ṣe ka yin kun to. Mi o lero pe ẹ le gbe iru ọrọ yii ko mi loju, ohun ti emi n reti latọdọ yin ni ọrọ ibanikẹdun si ọkan ninu awọn ọba yin nilẹ Yoruba, ti awọn Fulani darandaran pa awọn eeyan ẹ ni ipakupa. Kabiesi, ti ẹ ba gbọ ifọrọwerọ mi daadaa, ko si ibi kan bayii ti mo ti sọ pe ẹ ti gbowo l’Abuja. Ọrọ itaniji ni mo sọ ranṣẹ si gbogbo kabiesi ilẹ Yoruba lori bi nnkan ṣe n lọ, ẹyin naa si wa ninu awọn ti mo n sọ pẹlu.
“Kabiyesi, ipo ọla ti ẹ wa yẹn, gbogbo iran Yoruba pata lẹ n sọju fun, ohun ti mo si n fẹ latọdọ yin ni bi ẹ oo ṣe nawọ irẹpọ si gbogbo awa ọba alaye ilẹ Yoruba. Ohun ti a n fẹ latọdọ yin ni bi ẹ oo ṣe ran awọn eeyan wa si ilu Iselu lati jabọ fun yin bi wọn ṣe sọ awọn ọmọ Iselu di ẹru nilẹ baba wọn.”
Bẹẹ ni Ọọni naa tun da kabiesi yii lohun, to si kilọ fun un ko ma darapọ mọ awọn ti wọn n gbe iroyin ẹlẹjẹ kiri nipa ohun ti oun lọọ ṣẹ niluu Abuja pẹlu Aarẹ.
Ninu atẹjiṣẹ ọhun naa lo ti sọ pe ohun ti awọn jọ sọ ni bi wọn yoo ṣe pana wahala nla ti wọn fẹẹ da si Sunday Igboho lọrun lori bo ṣe le awọn Fulani darandaran kuro ni Igangan, lagbegbe Ibarapa, nipinlẹ Ọyọ.
Ọọni tun fi kun un pe, ko dara ki awọn eeyan maa foju buruku wo gbogbo ọba alaye tabi ki wọn maa sọ pe gbogbo igba ti Ọba alaye ba ti lọọ ri Aarẹ niru ọba bẹẹ lo n tọrọ ibi iwapo.
Arole Oodua fi kun un pe, “Emi nikan ni ọba alaye to lọọ ri Aarẹ, ohun to si fa a ko ju bi Aarẹ ṣe n fẹ ka tẹle ofin to le dina itankalẹ arun Koronafaiọọsi. Ibeere ti mo ni fun ọba yii ni pe, njẹ o wa nibẹ nigba ti mo n ba Buhari, sọrọ. Ti ọrọ ba ri bayii, ọgbọn inu leeyan maa n lo dipo ariwo ogun ati ọtẹ. Ohun ti mo mọ ni pe ọrọ alaafia ni mo lọọ ba Aarẹ sọ.”
Ọba Akinyẹmi, naa ti fesi o, ohun to si sọ ni pe Ọọni Ile-Ifẹ ti dakẹ ju lori wahala ti awọn Fulani n ko ba awọn ọmọ Yoruba. O ni, “Alayeluwa, ko ni i wu mi ki n tapa si imọran ti olori awa ọba ni agbegbe mi, Olu ti ilu Ilaro, gba mi pe ki n ma ṣe ba yin ṣe gbọmi-si-i-omi-ko-to-o lori ọrọ to wa nilẹ yii, imọran yẹn gan-an ni mo maa tẹle.
“Ṣugbọn ẹ jẹ ki n sọ kinni kan fun yin, wahala to wa nilẹ Yoruba loni-in, nibi ti ẹ ti n ṣe olori awọn ọba, nnkan ti daru patapata labẹ akoso yin. Ohun ti awọn eeyan n la kọja ti kuro ninu ohun ti eeyan le fọwọ kekere mu, wahala ẹlẹyamẹya, ijọba aninilara atawọn apaṣẹ-waa ti gbode kan bayii, bẹẹ ni nnkan ko rọgbọ.
“Boya lẹ mọ pe ki i ṣe ẹyin nikan ni ọba alaye ilẹ Yoruba to maa n lọ si Abuja, bẹẹ lo ṣee ṣe ki n ma mọ gbogbo awọn ọba to n waa ri Aarẹ Buhari nitori emi kọ ni olori oṣiṣẹ Aarẹ. Ọrọ nipa iwe aṣẹ epo wiwa ti ẹ sọ pe mo fi kan yin, ki i ṣe ẹyin nikan ni ọrọ yii ba wi, gbogbo awa ọba alaye ti a wa nilẹ Yoruba ni ọrọ ọhun kan gbọngbọn. Kabiesi, ẹ ti dakẹ ju lori bi nnkan ṣe n ri nilẹ Yoruba bayii. Ohun ti mo si mọ ni pe boya iroyin telifiṣan CNN nikan lẹ maa n wo.”
Ọba Iselu fi kun un pe inu oun yoo dun ti Ọọni Ile-Ifẹ ba le ran awọn eeyan wa si agbegbe oun lati waa wo bi ohun gbogbo ṣe ri nibẹ. Bakan naa ni Ọba yii sọ pe oun yoo fi awọn fọto kan ranṣẹ si Ọọni ko le mọ iru ara ti wọn n fi awọn eeyan oun da lagbegbe naa, paapaa lori bi wọn ṣe n du wọn bii ẹran, ti wọn n ṣe oko wọn lofo, ti awọn Fulani darandaran n jaye fa-mi-lete-n-tutọ
Ọrọ ti Ọba Iselu tun sọ yii ni wọn lo mu Ọọni fun un lesi pe bi ọba alaye naa ba lero pe oun ti dakẹ ju lori ọrọ Yoruba, oun dupẹ to sọ ọ, ṣugbọn kinni kan loun fẹẹ fi ye e pe kaluku lo ni bo ti ṣe maa n ṣe ti ọrọ ba delẹ.
Ọba Ogunwusi sọ pe, “Nile-Ifẹ, awa paapaa ti ri wahala awọn Fulani darandaran ri lọdun 2017, gbogbo ohun to ṣẹlẹ nigba yẹn pata la ni aworan ẹ nipamọ. Ohun ti ko ye mi to ni wahala ti o sọ pe o o ba ba mi fa ka ni Olu Ilaro ko da ẹ lẹkun ni, bẹẹ ni mo tun fẹẹ bi ẹ, aridaju to o ni pe mi o ki n wo ju iroyin CNN lọ. Ti o ba si sọ pe mi o ni itara si ohun to n ṣẹlẹ nilẹ Yoruba, mo dupẹ lori akiyesi rẹ, ṣugbọn kaluku lo ni bo ti ṣe maa n yanju ọrọ, ariwo kọ, bẹẹ aṣeyọri igbẹyin ọrọ lo ṣe pataki ninu ohun gbogbo.”
Tẹ o ba gbagbe, Sunday Igboho, gan-an lo kọkọ kọ lu Ọọni Ile-Ifẹ, Aṣiwaju Bọla Tinubu atawọn oloṣelu nla kan nilẹ Yoruba, nibi to ti pe wọn ni ẹru Fulani nitori iha ti wọn kọ si bi awọn Fulani darandaran ṣe n ko wahala ba awọn Yoruba nilẹ wọn, niluu wọn ati lori ilẹ wọn kaakiri ilẹ Yoruba, ti awọn to jẹ aṣiwaju yii ko ri ohun kankan ṣe si i.
Ọrọ ti Sunday Igboho sọ si Ọọni yii da họwuhọwu silẹ, ṣugbọn lẹyin ti awọn kan da si i, ni Sunday Igboho bẹ Ọba Adeyẹye Ogunwusi pe ko ma binu, inu lo ṣi oun bi, nitori iya buruku ti awọn Fulani fi n jẹ iran Yoruba ti pọ ju, bẹẹ oun lero pe niṣe lo yẹ ki awọn aṣaaju Yoruba dide gbe awọn eeyan wọn nija.