Ki ẹni to ba fẹẹ ṣofofo awọn ọdaran to ji ẹru lasiko iwọde SARS pe nọmba yii…

Florence Babaṣọla, Oṣogbo

Lẹyin ti anfaani wakati mejilelaaadọrin ti Gomina Gboyega Oyetọla kede gẹgẹ bii asiko oore-ọfẹ fun awọn to ji ẹru ijọba pe loru Ọjọruu, Wẹsidee, ọsẹ yii, awọn agbofinro yoo bẹrẹ si i lọ lati ile de ile, lati ṣawari awọn ẹru naa lati Ọjọbọ, Tọsidee, ọsẹ yii.

Ninu atẹjade kan ti akọwe ijọba ipinlẹ Ọṣun, Ọmọọba Wọle Oyebamiji, fi sita lori atunṣe to de ba asiko konilegbele lo ti ni ijọba dupẹ lọwọ awọn ti wọn lo anfaani asiko oore-ọfẹ ọhun lati da ẹru ti wọn ji pada.

Oyebamiji ṣalaye pe bo tilẹ jẹ pe awọn kan ti da awọn ẹru naa pada, sibẹ, ẹru ijọba ati tawọn aladaani to ku nita ṣi pọ, idi niyẹn tijọba yoo fi gbe igbesẹ to nipọn lori awọn kọlọransi ẹda naa.

O ni lati owurọ Ọjọbọ lọ, ole ni wọn yoo pe ẹnikẹni ti wọn ba ba ẹru ofin nile rẹ, wọn yoo mu un, yoo si foju bale-ẹjọ gẹgẹ bii ọdaran.

Ijọba waa rọ ẹnikẹni to ba fẹẹ ṣofofo awọn ọdaran naa ti wọn wa lagbegbe wọn lati pe sori nọmba yii: 08187187678.

Tẹ o ba gbagbe, lopin ọsẹ to kọja lawọn kan n lọ sile awọn oloṣelu ati ileeṣẹ ijọba, ti wọn si n ko gbogbo nnkan ti wọn ba nibẹ latari bi awọn kan ṣe ri ounjẹ korona tijọba ipinlẹ Ọṣun ko siluu Ẹdẹ.

Ọpọlọpọ ọkada, mansinni iranṣọ, ẹrọ ilọta, jẹnẹretọ, aga, oogun-oyinbo, ẹrọ amomitutu ati bẹẹ bẹẹ lọ ni wọn ji gbe nibẹ.

Leave a Reply