Ki ẹni to ba fẹẹ dupo oṣelu ninu ẹyin oṣiṣẹ mi kọwe fipo silẹ-Oyetọla

Florence Babaṣọla, Oṣogbo
Ni bayii ti idibo apapọ ọdun 2023 ti ku si dẹdẹ, gomina ipinlẹ Ọṣun, Adegboyega Oyetọla, ti kede fun gbogbo awọn to n ṣiṣẹ labẹ rẹ ti wọn nifẹẹ lati du ipo kan tabi omiiran lati lọọ kọwe fipo ti wọn n di mu lọwọlọwọ silẹ.
Ninu atẹjade kan ti Akọwe ijọba ipinlẹ Ọṣun, Ọmọọba Wọle Oyebamji, fi sita lo ti ni ki awọn eeyan naa gbe igbesẹ ọhun lai fi falẹ rara.
O ni eleyii jẹ abọ ipade awọn alaṣẹ ipinlẹ Ọṣun to waye lọjọ kẹtala, oṣu Kẹrin, ọdun 2022, ati alakalẹ abala ikẹrinlelọgọrin iwe ofin idibo orileede yii, ati nibaamu pẹlu deeti idibo ti ajọ INEC gbe jade.

O ni ki eyikeyii ninu wọn ma ṣe fi ọwọ yẹpẹrẹ mu aṣẹ naa.

Leave a Reply