Ki iku Timothy ma baa ba orukọ otẹẹli jẹ ni Roheem fi sọ pe ka bura pe ẹnikẹni ko gbọdọ gmọ- Magdalene

Florence Babaṣọla, Oṣogbo
Akọwe ileetura (Receptionist) Hilton, Ileefẹ, nibi ti akẹkọọ Fasiti Ifẹ, Timothy Adegoke, ku si loṣu Kọkanla, ọdun to kọja, Magdalene Cheifuna, ti sọ fun kootu pe Raheem Adedoyin to jẹ oludari ileetura naa lo sọ pe ki awọn bura lọjọ naa lati daabo bo orukọ otẹẹli naa.

Raheem ni ọmọ Dokita Rahmon Adedoyin to ni ileetura naa ni baba rẹ si fi ṣe alakooso ibẹ.

Nigba ti wọn pe olujẹjọ naa, Magdalene ṣalaye pe akẹkọọ ẹka Philosophy loun ni Fasiti Ifẹ, lati ọdun 2020 loun si ti n ṣe akọwe ni otẹẹli naa, oun ko si gbọ pe ẹnikẹni ku sibẹ ri.
O ni oun gba iṣẹ lọwọ Adeṣọla Adedeji ni ọjọ kẹfa, oṣu Kọkanla, ọdun 2021, iyẹn si sọ foun pe awọn alejo wa ninu yara meji to jẹ pe wọn ko ti i ṣetan lati kuro nibẹ.
O ni gbogbo igba lawọn n lọ wo ẹni to wa ni yaara 305, ṣugbọn ti awọn ko gburoo rẹ, nigba to di ọjọ keje, oṣu Kọkanla, ni oun gba kọkọrọ ti wọn maa n fi pamọ sọdọ oluṣọ ile, housekeeper, ti oun si ṣilẹkun yara naa.

Magdalene fi kun ọrọ rẹ pe bi oun ṣe ṣilẹkun, oun gbọ oorun buburu kan, oun si ro pe boya nnkan kan lo ti n bajẹ ninu firiiji yara naa tori awọn ko ri ibẹ tunṣe. O ni oun ri oogun (drug) kan lori tabili ti oun ko mọ orukọ rẹ, oun si tun ri oogun paracetamol.
O ni oun wọnu yara, oun si ba ẹnikan to sun sori bẹẹdi, o dasọ bora, ṣugbọn ko da aṣo bo oju, bẹẹ ni ika-ẹsẹ rẹ yọ jade, bẹẹ ni foonu rẹ n dun lẹgbẹẹ rẹ, ṣugbọn ko gbe e, nigba ti oun si mi ẹsẹ rẹ ti ko mira ni ẹru ba oun, ti oun si sa jade lẹyin ti oun ti ilẹkun yẹn pada pẹlu kọkọrọ ti oun ba lẹnu ilẹkun latinu.
O fi kun ọrọ rẹ pe oun lọọ pe manija lori foonu lati sọ nnkan to ṣẹlẹ, ti iyẹn si pada wa si otẹẹli kiakia. Nigba to de, awọn jọ pada si yara naa, oun duro sẹyin, nigba ti manija naa si yẹ ọkunrin naa wo, o ri i pe o ti ku.
Lẹyin naa ni manija ke si Dokita Rahmon Adedoyin, lẹyin naa ni Raheem Adedoyin de, ti oun ati manija si gun oke, lẹyin naa ni manija mu oun lọ si ọfiisi Raheem, nibi ti wọn ti sọ fun oun pe awọn yoo bura lati pa aṣiri naa mọ ki orukọ ileetura naa ma baa bajẹ, oun si fi bibeli bura.
O ni Raheem fun oun ni lẹta lati pada si ileewe lọjọ kọkanla, oṣu Kọkanla, lẹyin to sọ pe ki oun pa akọsilẹ ileetura naa rẹ lori foonu oun. O ni oun ko mọ nnkan kan mọ titi di ọjọ kejila, oṣu Kọkanla, ti awọn ọlọpaa waa gbe oun ni ile Adedoyin.

Ṣaaju ni akọṣẹmọṣẹ nipa ayẹwo oku kan to n ṣiṣẹ ni Ọbafẹmi Awolọwọ University Teaching Hospital, Ile-Ifẹ, Ọjọgbọn Oluṣẹgun Sylvester Ojo, ti sọ fun kootu pe ayẹwo ti awọn ṣe ko le sọ ni pato ohun to ṣokunfa iku Timothy.
O ni oun wa lara awọn dokita mẹjọ ti wọn ṣayẹwo oku Timothy ni UNIOSUNTHC, Oṣogbo, nigba ti ọkan lara awọn dokita naa, W. A. Oluogun, gbe abajade ayẹwo naa jade, kia loun sọ gbangba nipa awọn abala ti oun ko fara mọ nibẹ, idi niyẹn ti oun si fi kọ abajade ayẹwo ti oun, ti oun si lọọ fun kọmiṣanna ọlọpaa l’Ọṣun.

About Alaroye

Journalist, Press man and News Researcher of the federal Republic of Nigeria

Check Also

Adajọ agba ilẹ wa, Tanko Muhammad ti kọwe fipo silẹ

Adewumi Adegoke Adajọ agba ile-ẹjọ to ga ju lọ nilẹ wa, Onidaajọ Ibrahim Tanko Muhammad, …

Leave a Reply

//thaudray.com/4/4998019
%d bloggers like this: