Monisọla Saka
Asiko yii ki i ṣe eyi to daa rara fun arẹwa obinrin to tun jẹ Olori laafin Ọọni Ileefẹ, Ọba Adeyẹye Ogunwusi tẹlẹ, ati oludari ileeṣẹ redio Agidigbo, Alaaji Oriyọmi Hamzat, pẹlu bi Onidaajọ Ọlabisi Ogunkanmi, ti ile-ẹjọ Majisireeti kan to wa n’Iyaganku, niluu Ibadan, nipinlẹ Ọyọ, ṣe paṣẹ pe ki wọn lọọ fi awọn mejeeji pẹlu ọga agba ileewe Islamic High School, Baṣọrun, si ọgba ẹwọn Agodi.
Lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọjọ kẹrinlelogun, oṣu Kejila, ọdun yii, ni adajọ paṣẹ naa. Eyi waye nitori iṣẹlẹ ijamba to ṣẹlẹ niluu Ibadan, nibi ti ọmọ bii marundinlogoji ti padanu ẹmi wọn, tawọn mẹfa mi-in si n gba itọju lọwọ nileewosan lasiko ti awọn eeyan n jijagudu lati gba iwe ti wọn yoo fi gba ẹbun atawọn nnkan mi-in ti Olori Naomi Ogunwusi fẹẹ pin fun awọn ọmọde nibi eto kan to fẹẹ ṣe fun wọn niluu Ibadan, eyi ti obinrin naa gbe kalẹ pẹlu ifọwọsowọpọ ileeṣẹ redio Oriyọmi Hamzat, iyẹn Agidigbo, lọjọ kejidinlogun, oṣu Kejila yii.
Ẹsun mẹrin ni wọn fi kan awọn olujẹjọ mẹrẹẹrin ọhun. Ohun naa si ni pe ilẹdi apo pọ, iṣekupani latari pe wọn ko ka nnkan si, iwa aibikita to ṣokunfa ipalara ati nitori bi wọn ṣe kọ lati pese eto aabo ati eto ilera to peye sibi ti wọn ti fẹẹ ṣe eto naa.
Awọn ẹsun yii ni wọn lo ta ko ẹsun iwa ọdaran ipinlẹ Ọyọ, ti ọdun 2000, ti ijiya nla si wa fun un.
Ile-ẹjọ ni awọn mẹtẹẹta yii ni wọn lọwọ si eto to sọ ayẹyẹ ọdun Keresi ọdun yii di ibanujẹ fun awọn mọlẹbi kan pẹlu bi wọn ṣe padanu awọn eeyan wọn.
Nigba to n gbe idajọ rẹ kalẹ, Onidaajọ Ogunkanmi paṣẹ pe ki wọn lọọ fi wọn pamọ si ọgba ẹwọn to wa ni Agodi, titi ti ile-ẹjọ yoo fi gba imọran lati ileeṣẹ to gba ni nimọran lori awọn ẹjọ to ba ri bayii, iyẹn Director of Public Prosecution (DPP).
Lọjọ Aje, Mọnnde, ọjọ kẹtalelogun, oṣu Kejila, ọdun yii, ni igbẹjọ kan ti kọkọ waye, nibi ti wọn ti gbọ ẹjọ awọn afurasi marun-un kan ti wọn tun mu lasiko iṣẹlẹ naa. Ṣugbọn ile-ẹjọ pada da wọn silẹ pẹlu bi wọn ṣe ni awọn marun-un ọhun ko mọ nipa ohun ti wọn mu wọn fun, ki wọn too waa gbe awọn mẹtẹẹta yii lọ siwaju adajọ.
Awọn marun-un ti adajọ da silẹ ọhun ni: Genesis Christopher, ẹni ọdun mẹrinlelogun (24), Tanimọwo Moruf, ẹni ọdun mejilelaaadọta (52), Anisolaja Ọlabọde, ẹni ọdun mejilelogoji (42), Idowu Ibrahim, ẹni ọdun marundinlogoji (35), ati Abiọla Oluwatimilẹyin, toun jẹ ẹni ọdun mẹẹẹdọgbọn (25).
Bẹ o ba gbagbe, eto pataki kan ni Olori Naomi gbe lọ si ilu Ibadan lati ṣẹ ajọyọ pẹlu awọn ọmọde to ku diẹ kaato fun lawujọ. Awọn ọmọ bii ẹgbẹrun ni obinrin naa kede pe oun ni eto yii fun, nibi ti wọn yoo ti jẹun, ti wọn yoo ṣere, ti yoo si fun wọn ni ẹbun ọdun.
Aago mẹwaa aarọ ni wọn fi eto naa si, ṣugbọn ohun ti wọn ko ro ba eyi ti wọn n ro jẹ pẹlu bi awọn to fẹẹ tete debẹ lati gba iwe ti wọn kọ nọmba si ti wọn yoo fi fun wọn lẹbun ṣe ti n de si ileewe Islamic High School, to wa ni Baṣọrun, nibi ti eto ọhun yoo ti waye lati aago marun-un idaji.
Niṣe ni awọn eeyan naa n ti ara wọn, ti wọn si n ṣe waduwadu, asiko naa ni wọn tẹ awọn kan pa. Ki oloju si too ṣẹ ẹ, awọn bii marundinlogoji lo ti jade laye, ti wọn si gbe awọn mi-in digbadigba lọ si ileewosan ti wọn ti n gba itọju di ba a ṣe n sọ yii.
Oore ni Olori Naomi to ni oun fẹran awọn ọmọde, o si maa n wu oun lati wa layiika wọn fẹ ṣe pẹlu ẹgbẹ alaanu rẹ to pe ni WINGS FOUNDATION, ki gbogbo nnkan too yiwọ bayii.
A gbọ pe eyi kọ ni igba akọkọ ti yoo ṣe iru eto bẹẹ, ti ko si si wahala kankan ni gbogbo ibi to ti ṣe e.
Adura lawọn eeyan n gba fun Olori Naomi ati Alaaji Oriyọmi pe ki Ọlọrun ko wọn yọ ninu wahala naa.