Ki laa ti waa ṣeyi si, awọn agbebọn tun ji ọọdunrun akẹkọọ-binrin gbe nileewe ijọba nipinlẹ Zamfara

Aroye wọn maa ri awọn ọmọleewe rẹpẹtẹ tawọn agbebọn ji gbe lọ nipinlẹ Niger lọsẹ to kọja yii, ti wọn ko i ti i tu wọn silẹ laraye ṣi n wi lọwọ, awọn agbebọn tun ti ji awọn bii ọọdunrun akẹkọọ to jẹ ọmọbinrin gbe loru mọju ọjọ Ẹti, Furaidee yii, nipinlẹ Zamfara, wọn ti ko wọn wọgbo lọ.

Ileewe girama tijọba, to jẹ kidaa awọn ọmọbinrin lo n lọ sibẹ (Government Girls’ Secondary School), niṣẹlẹ ọhun ti waye, lagbegbe Jangebe, nipinlẹ Zamfara.

Ọkan lara awọn tiṣa ileewe naa ti ko fẹ darukọ ara ẹ sọ pe nnkan bii aago kan oru ọjọ Ẹti lawọn agbebọn naa ya bo awọn akẹkọọ yii, ti wọn n sun lọwọ ninu awọn yara wọn, o ni mọto lawọn agbebọn naa gbe wa, pẹlu ọkada meloo kan.

Ko ṣeni to ti i le sọ pato iye ọmọ ti wọn gbe lọ, gẹgẹ bo ṣe wi, ṣugbọn nigba ti wọn ka iye awọn akẹkọọ to ṣẹku, ti wọn si yọ iye naa kuro ninu awọn akẹkọọ to yẹ ko wa ni hositẹẹli (hostel) wọn lasiko ọhun, ọọdunrun awọn ọmọ yii lo ti wa lakolo awọn janduku agbebọn yii.

Wọn lawọn agbofinro ti wa sileewe naa nigba tilẹ mọ, ṣugbọn wọn o ti i le sọrọ lori iṣẹlẹ naa di ba a ṣe n sọ yii.

Tẹ o ba gbagbe, iṣẹlẹ ijinigbe, yiya bo awọn akẹkọọ nileewe wọn ti di ohun to n ṣẹlẹ lemọlemọ lagbegbe Oke-Ọya bayii. Ninu oṣu kejila, ọdun to kọja, ni wọn ji awọn akẹkọọ-kunrin bii ọọdunrun gbe ni Kankara, nipinlẹ Katsina, ẹyin eyi ni wọn tun ji awọn bii mejilelogoji gbe nipinlẹ Niger lọsẹ to kọja.

Leave a Reply