Ki laa ti waa ṣeyi si, awọn Fulani tun pa agbẹ mẹta sinu oko l’Ọwọ

Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ

Lẹyin bii ọjọ mẹrin pere ti wọn pa awọn meji sinu igbo ọba l’Ọwọ, awọn agbẹ mẹta mi-in lawọn Fulani darandaran tun yinbọn pa labule kan ti wọn n pe ni Ijugbere, nijọba ibilẹ Ọwọ, yii kan naa lọjọ Abamẹta, Satide, ọsẹ to kọja.

Oludamọran agba fun gomina lori eto ọgbin, Akin Olotu, lo fidi iṣẹlẹ yii mulẹ fawọn oniroyin kan lọjọ Aiku, Sannde, ọsẹ ta a wa yii.

O ni ipaniyan atawọn iwa ọdaran mi-in to n waye lemọ lemọ ninu igbo ọba to jẹ tipinlẹ Ondo lati ọwọ awọn Fulani ti fidi ohun to ṣokunfa bi Gomina Rotimi Akeredolu ṣe fofin de wọn ninu igbo ọba mulẹ.

O ni ṣe lo yẹ kí gbogbo awọn to n sọrọ ta ko igbesẹ naa dọwọ boju pẹlu atilẹyin ti wọn n ṣe fawọn onisẹẹbi ọhun.

Gomina Akeredolu la gbọ pe o ti fi ofin to rọ mọ kiko ẹran jẹ oko oloko sọwọ sile-igbimọ aṣofin ipinlẹ Ondo lọsẹ to kọja.

Arakunrin ni ijọba oun ti ṣetan lati kọ awọn ibudo igbalode tawọn Fulani yoo ti maa kẹran jẹ oko wọn ní gbogbo ìjọba ibilẹ mejidinlogun to wa nipinlẹ Ondo.

Bakan naa ni gomina ọhun tun fọwọ si rira ogun ọkọ fun awọn ẹsọ Amọtẹkun ki iṣẹ aabo ti wọn n ṣe ba a le rọrun si i.

 

Leave a Reply