Ki lo de tawọn eeyan yii n sọ ominira di inira fun wa

A fẹran lati maa fi ara wa ṣe yẹyẹ ju. Mo wa ọrẹ mi kan lọ sile nijẹta n ko ri i, nitori alagbara ninu ijọba yii ni. Mo pe e pe nibo lo wa, o ni awọn n ṣe wahala ọdun ominira ọgọta ọdun lọwọ. Nigba ti mo pada ri i, to si sọ iye ti awọn fẹẹ na, ẹnu ya mi. Ṣugbọn mo kuku mọ pe wọn o le na owo to to bẹẹ, wọn maa ko o jẹ ni. Ṣugbọn mo beere lọwọ ẹ pe ṣe ninu ominira la wa ni tabi ninu inira. Mo ni owo ti wọn n na danu yii, bi wọn ba ni laakaye ati inu ti wọn n ro ni, iṣọkan Naijiria lo yẹ ki wọn fi wa, nitori emi ri i pe Naijiria yii o ni i pẹe fọ, ti yoo si pin yẹlẹyẹlẹ.

Ko si ki Naijiria yii ma pin si wẹwẹ. Mo woye titi, n ko ri ọna ti a oo gbe e gba. N ko ri i bi wọn ti fẹẹ ṣe e ki Yoruba ma ṣe tirẹ lọtọ laarin awọn eeyan ti a ko tira yii, ti a jọ n pe ara wa ni Naijiria yii, nitori awọn eeyan naa ko fẹ wa fun daadaa rara. Yatọ si pe wọn o fẹ wa fun rere, gbogbo ọna pata ni wọn n gba lati sọ wa di ẹru. Gbogbo ọna pata ni wọn n gba lati mu ki awa ẹya to ku ka maa ṣiṣẹ fun Fulani jẹ. Bi a ba pa owo ni ilẹ Yoruba, wọn aa wa gbogbo ọna lati ko o lọ silẹ Hausa, wọn aa si bẹreẹ si i pin in laarin ara wọn. Ohun to maa waa tete mu ki orilẹ-ede yii fọ ni iru ijọba ti Buhari n ṣe yii, ijọba ti ko sẹni to ri iru ẹ ri ni Naijiria yii ni. Afi bii ẹni pe aditi lọkunrin yii, tabi bii ẹni to ti ku sara ti ko mọ ohun to n lọ ni ayika ẹ ati laarin orilẹ-ede to ti n ṣe olori wọn.

Lojoojumọ la n pariwo: awọn ẹgbọn ti wọn ju iru awa yii lọ, awọn ti ko to wa, awọn ti wọn ti ṣejọba ri, awọn ti wọn ti ṣe ṣọja ri, awọn ọmọwe to ti ni iriri iwe ati ti ọjọ ori, lojoojumọ la n pariwo pe bi ọkunrin yii ti n ṣejọba ko dara. Ṣugbọn bi wọn ba ti bu u nidiii eyi to n ṣe yii, ko ni i ṣiwọ nibẹ naa o, eyi to si tun maa ṣe ni iwa ibajẹ mi-in to maa buru ju ti tẹlẹ lọ. N o mọ ohun ti awọn ti wọn n gbeja Buhari yii fẹẹ sọ, n o mọ ohun ti wọn fẹẹ wi si iru ohun tọkunrin naa tun ṣe yii. Boya ẹyin naa o si ti i gbọ. Lọsẹ to kọja yii, ijọba Buhari fọwọ si i pe ki awọn ṣe ọna reluwee to maa gbera lati Kano, ti yoo gba Daura, niluu Buhari funra ẹ kọja, ti yoo si yọ si orilẹ-ede Nijee (Niger Republic). Orilẹ-ede Nijee yii ni ilu ti Naijiria ba paala, nibi ti awọn Fulani pọ si, agbegbe tawọn Boko Haram ati Fulani onijaadi n ba wọ ilẹ wa.

Ọrọ naa ki i ṣe ọrọ ti ẹnikẹni gbọdọ rẹrin-in si, ọrọ ti ẹni to ba ni omi loju le tori ẹ sunkun ni, nitori ijọba Buhari yii fẹẹ fi ogun ja wa, ohun ti wọn si n ṣe ye wọn daadaa. Ohun ti wọn n ṣe ni lati ṣi ọna fun awọn Fulani wọnyi, ko ma si si ohun ti yoo da wọn duro lati wọ Naijiria wa, ati lati ri i pe ko sohun to da awọn Fulani ọdọ tiwa bii awọn Buhari yii naa duro lati lọọ ba awọn eeyan wọn to wa ni orilẹ-ede mi-in. Ta ni yoo da awọn Fulani wọnyi duro lati ma wa si Naijiria lati Nijee, boya wọn ko maaluu wa, boya wọn kan n bọ waa ṣiṣẹ, koda ko jẹ iṣẹ aburu ni wọn fẹẹ waa ṣe. Ta ni yoo da wọn duro. Bi ibo ba de ti wọn ba fẹ ki awọn eeyan yii waa dibo, wọn maa ya wọ Naijiria bii eṣu ni, ko si sẹni to le da wọn duro, nitori awa ti a wa ni isalẹ nibi ko ni i ri wọn, a ko tilẹ ni i mọ igba ti wọn de tabi ti wọn wọle.

Ọna meji to buru ni nnkan yii ko fi dara. Ọna akọkọ ni ti eto ọrọ aje to mu lọwọ, ifowoṣofo lasan ati fifi owo ti Naijiria ran wọn lọwọ lorilẹ-ede awọn Fulani, ti wọn yoo si maa purọ fun wa pe awọn eeyan naa lo n ran wa lọwọ. Ọna keji ni nidii eto aabo, bi ogun ba ṣẹlẹ ni Naijiria yii, reluwee lawọn Fulani yii aa fi maa wọle, ti wọn aa maa jade. Pẹlu iwa ifẹmiṣọfo to kari aye bayii, ki i ṣe asiko ti Naijiria yẹ ko kọ reluwee lati maa ko ero wa lati Nijee si Naijiria niyi! Nitori kin ni? Anfaani wo lo wa nibẹ fun wa! Ko si aanfaani nibẹ afi ofo nikan! Wọn fẹẹ ko wa lẹru, wọn ko si fi bo fun wa pe awọn fẹẹ ṣe bẹẹ, nitori bi ko ṣe bẹẹ ni, eyi ti wọn ṣe yii, bii baba onile to fi ọwọ ara rẹ ṣilẹkun fun awọn ole ki wọn wọle ni. Ohun meji lo si le fa eleyii, bi baba onile funra ẹ ko ba jẹ ole, aa jẹ agbẹyinbẹbọjẹ to fẹẹ ṣe awọn ara adugbo rẹ to ku leṣe.

Nigba ti tawọn eeyan yii kọkọ bẹrẹ, mo pariwo ọrọ naa sita o. Koda, mo sọ fun gbogbo Yoruba to ba leti. Ṣugbọn awọn kan ki mi mọlẹ, wọn bu mi titi, ẹni kan si sọ fun mi pe lori ọrọ ti mo kọ nigba naa yii, niṣe lo yẹ ki awọn DSS waa gbe mi, nitori iwa to le da ilu ru ni mo n hu, ohun to le fọ Naijiria si wẹwẹ ni mo ṣe. Lọdun to kọja lọhun-un ni, nigba ti awọn ti wọn n ba wọn wa epo kede pe awọn n lọo kọ ileeṣe ifọpo kan si itosi orilẹ-de Nijee yii. Wọn ni awọn fẹẹ maa ra epo lati orilẹ-ede Nijee wa si Naijiria, awọn aa si maa fọ epo naa nibẹ ki awọn too pin in si aarin awọn eeyan Naijiria. Mo sọ fun yin nigba naa pe irọ ni wọn n pa, ọtọ lohun ti wọn fẹe ṣe. Ohu ti mo ṣe sọ bẹẹ ni pe arun oju ni, ohun ti ko mọgbọn dani ni ijọba Buhari kede nigba naa, bi ko ba si jẹ wọn ko lọgbọn, a jẹ etekete ni wọn fẹẹ ṣe.

Orilẹ-ede Nijee ti wọn ni awọn ti fẹẹ maa ra epo bẹntiroolu yii, epo ti awọn yẹn n ṣe ni gbogbo ọdun kan ko to eyi ti Naijiria yoo fi oṣu kan pere ṣe, mo si sọ bẹẹ nigba naa fawọn eeyan. Bawo ni ibi ti wọn ti n ṣe epo ti ko to ẹyọ kan ninu ọgọrun-un, eyi ti Naijiria n ṣe ṣe waa di ibi ti Naijiria yoo ti maa lọọ ra epo wa. Ẹni to ba ti gbọ eyi aa ti mọ pe jibiti ni, ijọba Buhari fẹẹ lu wa ni jibiti fawọn Fulani ni. Ohun ti wọn fẹẹ ṣe ni lati maa fi ọgbọn gbe epo ti wọn ba ṣe lọdọ wa yii naa lọ sibẹ ni, wọn aa si maa fi ọgbọn ko owo Naijiria jade si Nijee, wọn aa ni awọn ni wọn n ta epo bẹntiroolu fun wa. Loootọ ni ko dun mọ awọn eeyan yii ninu pe ilu Eko, nilẹ Yoruba, ni epo n ba wọ Naijiria, ati pe gbogbo ọna ni wọn fi n wa bi epo bẹntiroolu yii yoo ṣe lalẹ yọ lati apa ọdọ wọn. Ṣugbọn epo naa ko wa, wọn ko ri epo nibẹ, iyẹn lo fa ọgbon buruku ti wọn fẹe da yii.

Bo tilẹ jẹ pe ọpọ eeyan lo tun sọ iru ọrọ ti mo sọ yi nigba naa pe ohun tijọba lawọn fẹẹ ṣe yii ko daa, sibẹ, wọn o gbọ! Kinni naa ni wọn n ba lọ yii, oun ni wọn si ṣe ya biiliọnu meji owo dọla sọtọ, ti wọn ni awọn yoo fi kọ ọna reluwee. Ọtọ ni wọn ya owo sọtọ pe awọn fẹẹ fi kọ ileeṣẹ ifọpo yii o, bẹẹ ni ileeṣẹ ifọpo kan wa ni Kaduna ti wọn ko tun un ṣe, ọkan wa ni Pota ti ko ṣiṣẹ daadaa, wọn pa gbogbo eyi ti, wọn ni awọn fẹẹ kọ ile-ifọpo tuntun sitosi Nijee. Ẹ wọ iye owo ti wọn yoo na lati gbe epo de inu aṣalẹ buruku yii, epo ti wọn n ṣe ni Naija-Delta, ti wọn aa kọkọ ru u lọ si Nijee lati lọọ fọ, ti wọn yoo ṣẹṣẹ tun da a pada waa fun wa ni owo gọbọi pe ka ra a, ka si maa ta a fawọn eeyan wa. Ibeere to yẹ ki awọn ọmọ Naijiria beere lọwọ awọn Buhari yii ni pe ki lo de ti wọn ko tun ile-ifọpo to wa ni Kaduna ṣe, ki lo de ti awọn to ku ko ṣiṣẹ, ṣebi ti wọn ba tun awọn yii ṣe, ko ni i si wahala lati maa wa ileefọpo mi-in kiri.

Iranlọwọ wo ni ileeṣẹ ifọpo to ba wa nitosi Nijee fẹẹ ṣe fun wa? Ko si! Ohun ti wọn fẹe ṣe naa ni wọn n ṣe yii, lati fi owo Naijiria kọ ilu ati le ati ileeṣẹ fun Fulani nitosi Nijee, ki awọn si fi ọgbọn sọ awọn ọmọ orilẹ-ede naa di ọmọ Naijiria, ọna lati sọ ilẹ Naijiria di ti Fulani ni. Ṣugbọn eyi ko ni i ṣee se. Ko le ṣee ṣe rara. Naijiria yoo yaa pada fọ naa ni. Idi ni pe iran Yoruba ko ni i ṣe eru iran mi-in, ohun to ba gba ni gbogbo wa yoo jọ fun un. Tabi kin ni a ṣe fun wọn, kin ni idi ti awọn eeyan naa fi fẹe gba ilẹ wa ati ohun-ini wa fun iran tiwọn. Kin ni idi ti Buhari di fẹẹ ṣe eleyii fun Naijira! Awọn ti wọn ba sọ fun un pe eleyii yo ṣee ṣe n tan an ni o, nitori ohun ti ko ni i ṣee ṣe ni. Ija naa ni yoo gbẹyin, ogun ni yoo gbẹyin, bo ba ya, onikaluku yoo gba ile baba rẹ lọ. Inira yii ṣẹ n pọ ju, nitori eyi ti a wa ninu ẹ yii ki i ṣe ominira, ninu ide awọn Fulani la fẹẹ bọ si.

Leave a Reply