Ki lo n ṣẹlẹ: Ijọba Buhari fẹẹ gba Amọtẹkun lọwọ awọn Yoruba!

Ọpọ eeyan ni ko ka ọrọ naa si, ṣugbọn nigba ti wọn ranti pe ọrọ ti ọlọgbọn ba sọ, ẹnu aṣiwere leeyan ti n gbọ ọ, ni gbogbo won ṣe dide, ti wọn si ni ala ti ko ni i le ṣẹ ni o, ohun ti ko ṣee ṣe lọkunrin naa fẹnu ara rẹ sọ. Ọkunrin to maa n kede ọrọ gbogbo to ba ti ẹnu Aarẹ Muhamamdu Buhari jade ni, Garba Shehu lorukọ ẹ, oun naa lo si sọrọ kan to ko gbogbo aye lọkan soke gan-an. ALAROYE gbọ pe lati bii ọjọ mẹta kan ni inu awọn eeyan yii ko ti dun si ohun to ṣẹlẹ ni Ondo lọjọ kọkanla, oṣu kẹjọ, to kọja yii, lọjọ ti wọn fi ikọ Amọtẹkun lọlẹ nibẹ. Bi Gomina, Arakunrin Rotimi Akeredolu, ti mura lọjọ naa bii ọga ologun, ti wọn si da aṣọ ologun ara ọtọ fun awọn ọmọ Amọtẹkun, ti oun si mura bii ọga agba pata fun wọn ko dun mọ ọpọ awọn eeyan to n ba Buhari ṣiṣẹ, bẹẹ ni kinni naa ko si dun mọ awọn agba Fulani kan ninu rara.

Arakunrin Rotimi Akeredolu

Lati ọjọ yii ni wọn ti n sọrọ Amọtẹkun ni ileeṣẹ Aarẹ, ti wọn n sọ ọ ni ayika ibi ti awọn agba Hausa-Fulani wa, ohun ti wọn si n wi naa ni pe ijọba gbọdọ ri i pe Amọtẹkun yii ko ṣiṣẹ, tabi ki wọn gbe e si abẹ awọn ọlọpaa patapata. Ko si ẹni to mọ bi wọn yoo ti sọrọ yii jade, afi ni ọsẹ to kọja yii ti Garba Sheu lọ si ori eto tẹlifiṣan kan, to si sọ ọ ni gbangba nibẹ pe Amọtẹkun ti awọn gomina ilẹ Yoruba n pariwo wọnyi, ko si ibi ti wọn yoo ti ṣiṣẹ ju abẹ ọlọpaa ijọba apapọ lọ. Ọkunrin to n ba Aarẹ ṣiṣe yii ni ofin ti wa, ohun ti ofin si sọ ni pe iru ikọ awọn ẹṣọ bayii ko le da duro, wọn yoo wa labẹ ọlọpaa ni, ọlọpaa ni yoo si maa ṣeto gbogbo ti wọn ba fẹ fun wọn. Garba Shehu ni ọga ọlọpaa pata ni yoo maa dari eto gbogbo ati ilana gbogbo ti Amọtẹkun ba fẹẹ tọ, nitori oun nikan lo ni agbara lori eto aabo abẹle, nigba to jẹ iṣẹ ọlọpaa ni.

Ohun to fi han pe ọrọ naa ki i ṣe ọrọ Garba Shehu nikan ni pe ni bii ọjọ mẹrin si igba ti oun yoo sọrọ yii, iyẹn ni ọjọ kọkanlelogun, oṣu kẹjọ, to pari yii, Ọgagun Agba Muhammadu Buhari gbe owo nla kalẹ, biliọnu mẹtala, o ni ki wọn tete fi gbe eto olọpaa ibilẹ kalẹ, ki awọn ọlọpaa ibilẹ naa si bẹrẹ iṣẹ kiakia. Lati igba ti ijọba ti kede pe oun fẹẹ ṣeto ọlọpaa ibilẹ yii ni awọn eeyan ti binu, ti wọn n sọ pe ọtẹ lasan ni ijọba fẹẹ fi ọrọ awọn ọlọpaa naa ṣe. Idi ni pe fun ọpọlọpọ ọdun ti awọn janduku, awọn ajinigbe ati awọn ọdaran mi-in, paapaa awọn Fulani onimaaluu fi n yọ gbogbo agbegbe ilẹ Yoruba lẹnu, ijọba apapọ yi oju wọn si ẹgbẹ kan ni, wọn ko si ṣe bii ẹni to mọ ohun to n lọ rara. Awọn eeyan reti ki ijọba Buhari sọrọ, wọn ko sọrọ. Wọn dakẹ rọrọ bi awọn Fulani onimaaluu yii ti sọ ara wọn di nnkan mi-in laarin awọn ọmọ Yoruba pata.

Ṣugbọn ni gbara ti awọn gomina ilẹ Yoruba pade, ti wọn ni awọn ko le jẹ ki awọn Fulani onimaaluu ati awọn ọdaran tawọn ko mọ maa waa ṣe ijamba fawọn eeyan awọn, ti wọn ni awọn yoo da Amọtẹkun silẹ fun ẹṣọ ati aabo ilẹ Yoruba, kia ni ijọba apapọ naa jade pẹlu eto tuntun ti wọn pe ni ‘Ọlọpaa Ibilẹ’, bi eeyan ba si ti gbọ gbogbo ohun ti wọn ni awọn ọlọpaa ibilẹ yii yoo maa ṣe, ati bi wọn yoo ṣe maa gba awọn eeyan sinu rẹ, yoo ti mọ pe nitori Amọtẹkun ni wọn ṣe sare fẹẹ ko wọn jade, ko jọ pe ijọba ni eto naa lọkan tẹlẹ. Wọn ko ti i bẹrẹ eto naa paapaa ti wọn ti ni gbogbo awọn ẹgbẹ tabi ajọ to ba n ṣe iṣẹ ẹṣọ, iyẹn awọn ikọ bii ti Amọtẹkun yii, wọn yoo jọ maa ṣiṣẹ pọ pẹlu awọn ọlọpaa ibilẹ yii ni. Ọrọ yii kọ awọn eeyan lominu nigba naa, ohun ti wọn si fẹẹ mọ ni nnkan ti ijọba Buhari yii n fẹ gan-an.

Ojogbon Banji Akintoye

Nigba ti Amọtẹkun Ondo waa jade, ti wọn ri i pe kinni naa ti fẹsẹ mulẹ tootọ, wọn ko owo kalẹ ki eto yii bẹrẹ kia. Ohun to tun yaayan lẹnu ni pe pẹlu owo ti wọn ko kalẹ yii, niṣe ni Igbakeji Ọga aga ọlọpaa pata, Adelẹyẹ Oyebade, ni awọn gomina ipinlẹ gbogbo ni yoo maa sanwo oṣu ati owo iṣẹ ti awọn ọlọpaa ibilẹ naa ba n ṣe. O ni ojuṣe ti awọn ọlopaa fẹẹ ṣe fun awọn eeyan yii ni lati kọ wọn ni ẹkọ bii ṣọja, wọn yoo wa ni awọn ijọba ibilẹ ati agbegbe gbogbo lati maa ran awọn ọlọpaa lọwọ, nitori ofin ojuṣe ọlọpaa lawọn fi da wọn silẹ, bii wakati mẹrindinlogun naa ni wọn yoo maa fi ṣiṣẹ laarin ọsẹ kan, ijọba ipinlẹ ni yoo si maa sanwo to tọ si wọn. Tiwa ni lati kọ wọn lẹkọọ to yẹ. Awọn gomina mi-in binu si eyi, wọn ni ko sẹni to ran wọn niṣẹ, bi wọn ba mọ pe awọn ko le sanwọ oṣu, kin ni wọn n gba awọn eeyan siṣẹ fun.

Gbogbo bi ijọba apapọ ṣe n gba iwaju ti wọn n gbẹyin yii ti n mu ifura dani pupọ, paapaa nigba ti iru ikọ eleto aabo bayii wa ni awọn ilẹ Hausa lati ọdun yii wa, ti ko si sẹni to ṣi wọn lọwọ, ti ijọba paapaa ko si figba kan sọ pe ohun ti wọn n ṣe ko dara, tabi pe awọn yoo da ọlọpaa ibilẹ silẹ nitori tiwọn. Ṣugbọn lati igba ti ọrọ Amọtẹkun yii ti bẹrẹ ni kinni naa ko ti tẹ awọn ara Oke-Ọya lọrun rara, koda awọn Hausa naa ti da Amọtẹkun tiwọn silẹ nigba kan, ti wọn ni awọn fẹẹ fi han awọn Yoruba yii pe awọn naa le ṣe ohun ti wọn n ṣe. Awọn Fulani paapaa dide, wọn ni awọn yoo ni fijilante tawọn naa, ti awọn yoo si da wọn kaakiri ilẹ Yoruba ati ibi gbogbo ni Naijiria. Ohun to fa a ti ọpọ awọn eeyan ṣe lodi si i ree, nigba ti wọn ri i pe ohun to jọ pe ijọba Buhari yii fẹẹ ṣe ni lati gba Amọtẹkun kuro lọwọ awọn Yoruba, ti wọn yoo si fi ohun mi-in ti wọn mọ pe ko ni i ṣiṣẹ rọpọ fun wọn.

Eyi lo fa a to jẹ bi ọrọ naa ti jade lẹnu Garba Shehu pe abẹ ọga ọlọpaa ni wọn yoo ko Amotẹkun si, niṣe lawọn gomina ilẹ Yoruba yari rangbọndan. Akeredolu lo kọkọ sọrọ, o ni ki Buhari tabi ẹnikẹni ninu ijọba rẹ ma ṣe ro iru ero bẹẹ, nitori bi wọn ba ta a ni tẹtẹ, wọn ko le jẹ. Gomina naa ni ofin to da Amọtẹkun silẹ ki i ṣe ofin ijọba apapọ, ofin ijọba ilẹ Yoruba ni, nitori bẹẹ, ko si ohun ti Amọtẹkun yoo wa lọ sọdọ ijọba apapọ, ki kaluku maa fi tiẹ ṣe tiẹ ni. Nigba naa ni Gomina Ṣeyi Makinde paapaa kin ọrọ yii lẹyin, to gbe iwe jade kia pe ko sẹni ti yoo gba Amọtekun lọwọ Yoruba, nitori awọn gẹgẹ bii gomina ko di ẹnikẹni lọwọ pe ki wọn ma da ikọ alaabo to ba wu wọn silẹ lọdọ tiwọn. Bi oun ti sọrọ, bẹẹ naa ni Ẹgbẹ Afẹnifẹre wi, bẹẹ ni awọn agbaagba ilẹ Yoruba gbogbo si sọ. Wọn ni ko si ohun to jọ bẹẹ, ti Yoruba ni Amọtẹkun, ko ṣeni ti yoo gba a lọwọ awọn.

Ẹgbẹ apapọ ọmọ Yoruba ti wọn n pe ni ‘Yoruba World Congress’ lo la ọrọ naa mọlẹ pe ko si ohun to wa lọkan awọn Buhari ju ki wọn gba Amọtẹkun kuro lọwọ awọn gomina wọnyi lọ. Aarẹ ẹgbe yii, Ọjọgbọn Banji Akintoye, ni iwadii awọn ti fi han pe ko si ohun ti wọn fẹẹ ṣe ju lati gba Amọtẹkun, ki wọn waa fi nnkan mi-in rọpo, iyẹn naa ni wọn si n pe ni ọlọpaa Ibilẹ. Ọjogbọn yii ni ki i ṣe pe awọn ọlọpaa ibilẹ yii naa yoo pẹ titi, bi wọn ba ti ṣe e diẹ, ti wọn ti fi ba Amọtẹkun yii jẹ, wọn ko ni i ya si i mọ, wọn yoo si tun da Yoruba pada sibi to ti wa tẹlẹ, nibi ti eto aabo gbogbo agbegbe naa ko ti dara. Ohun ti awọn ọmọ Buhari ṣe n ṣe eleyii ko yeeyan, idi si niyi i tawọn agbaagba ilẹ Yoruba fi n beere pe ki lo de ti Buhari fẹẹ gba Amọtẹkun lọwọ awọn Yoruba o!

Leave a Reply