K’Igboho ma baa yipada di ologbo lawọn ọlọpaa Bẹnnẹ ṣe de e mọlẹ-Falọla

Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta

Lasiko ti wọn ṣẹṣẹ mu Oloye Sunday Adeyẹmọ (Igboho Ooṣa) ni Bẹnnẹ, iroyin gbode pe awọn ọlọpaa ilẹ Olominira naa de e mọlẹ, awọn kan sọ pe wọn so o ni ṣẹkẹṣẹkẹ lọwọ bii ọbọ ni.

Aṣiwaju ninu awọn lọọya to n ṣoju ọkunrin naa ni Bẹnnẹ, Amofin Malik Oluṣẹgun Falọla, ti fidi eyi mulẹ. O ni awọn ọlọpaa Bẹnnẹ de Igboho mọlẹ loootọ, ṣugbọn ko ma baa di ologbo mọ wọn lọwọ ni wọn ṣe ṣe bẹẹ.

Amofin Falọla sọ pe awọn ọlọpaa gbe igbesẹ naa nitori wọn mọ pe alagbara ni Igboho, to ba yipada di ologbo, yoo pada poora mọ wọn loju ni.

Lọọya yii ṣalaye pe awọn ọlọpaa naa ko deede ṣe bẹẹ fun Sunday, o ni ohun ti wọn gbọ ni pe Igboho le di oloogbo ko si ṣe bẹẹ lọ mọ wọn lọwọ. Ko si ma di pe yoo lọ loootọ, ti ẹjọ naa ko ni i ṣe e ro lọdọ ijọba, tabi ti yoo di ọran si wọn lọrun lo jẹ ki wọn de e lai le da nnkan kan ṣe nigba naa.

‘Nigba ti mo de lati Paris, ti mo si lọọ wo Igboho ni ahamọ ti wọn fi i si, wọn de e ni ṣẹkẹṣẹkẹ nigba naa ni loootọ. Ẹru n ba wọn pe o le poora ninu afẹfẹ, ko lo afẹẹri, nitori agbara oogun to ni lọwọ.

“Ọlọpaa to n sọ ọ sọ pe boun ba tu ṣẹkẹṣẹkẹ naa kuro, Igboho le poora tabi ko di ologbo, to ba si ṣẹlẹ bẹẹ, iṣẹ yoo bọ lọwọ ọlọpaa naa ni’ Bẹẹ ni Amofin Falọla wi.

O ni ṣugbọn oun jẹ ki wọn mọ pe Igboho ko ni i di ologbo, ko si ni i sa lọ bi wọn ba tu u, nitori oun ti ba a sọrọ pe ko ma ṣe bẹẹ, ẹjọ to n jẹ yii yoo pari lọjọ kan, ko si kuku jẹbi ijọba Naijiria, ẹtọ awọn ẹya rẹ lo n ja fun, nitori naa, ko farapamọ si ahamọ nibẹ fungba diẹ, gbogborẹ yoo yanju lọjọ kan.

Lasiko to ba Alaroye sọrọ ni Bẹnnẹ, Falọla sọ pe awọn ọlọpaa naa ko kọkọ fẹẹ gba, ṣugbọn nigba toun rin in bo ṣe tọ, wọn tu ṣẹkẹṣẹkẹ lọwọ ajafẹtọọ ọmọniyan yii, latigba naa ni ko si ti si ṣẹkẹṣẹkẹ lọrọ rẹ mọ.

 

Leave a Reply