Kiko ẹgbẹ afẹmiṣofo jọ, fifẹ lati doju ijọba de ati pipa araalu lawọn ẹsun tuntun ti wọn ka si Kanu lẹsẹ

Faith Adebọla

Ọjọ kọkandinlogun ati ogunjọ, oṣu ki-in-ni, ọdun 2022, ni igbẹjọ yoo maa tẹsiwaju lori ẹsun ti wọn fi kan ajijangbara ọmọ ilẹ Ibo nni, Nnamdi Kanu, latari bi igbẹjọ to yẹ ko waye l’Ọjọruu, Wẹsidee yii, ṣe fori ṣanpọn, ti awọn lọọya mọkandinlogun to n ṣoju fun Kanu si fibinu jade ni kootu giga naa.

Nnkan bii aago mẹwaa ku iṣẹju mẹwaa ni wọn mu afurasi ọdaran naa de ile-ẹjọ giga naa foju bale-ẹjọ ilu Abuja, aago mẹwaa l’adajọ jokoo, ti igbẹjọ si bẹrẹ, ṣugbọn Nnamdi Kanu fẹjọ sun Adajọ Binta Nyako pe awọn ẹṣọ ileeṣẹ ọtẹlẹmuyẹ (DSS) o jẹ kawọn lọọya kan foju kan oun, paapaa Amofin Bruce Fein to wa lati orileede Amẹrika nitori ẹjọ yii, o ni wọn o jẹ kawọn lọọya naa wọle si yara igbẹjọ gan-an.

Kanu ni, “Mo ni ẹjọ kan ti mo n jẹ lọwọ lorileede Amẹrika, wọn o jẹ ki n ri lọọya mi to wa lọhun-un, o si fẹẹ wo bi igbẹjọ oni ṣe maa lọ si. O ti lọ sọdọ awọn DSS pe oun fẹẹ ri mi, ṣugbọn wọn o gba.”

Ki Kanu too sọrọ yii lawọn agbẹjọro rẹ mọkandinlogun ti binu jade ni yara igbẹjọ naa, wọn ni bawọn ẹṣọ ọtẹlẹmuyẹ ko ṣe jẹ ki Bruce Fein atawọn to ku wọle, awọn o ni i kopa ninu igbẹjọ to fẹẹ waye naa, ni kaluku ba ko iwe rẹ ti wọn si bọ wiigi ori wọn, wọn jade.

Adajọ beere lọwọ Kanu boya o fẹẹ kigbẹẹjọ tẹsiwaju lẹyin awọn lọọya rẹ, ọkunrin naa si loun o gba. Ṣugbọn Agbẹjọro fun ijọba, Amofin agba Mohammed Abubakar, rọ adajọ pe ki igbẹjọ tẹsiwaju jare, tori olori awọn lọọya olujẹjọ, Amofin agba Ifeanyi Ejiofor, ti kọkọ wọle si kootu naa, awọn si ni wọn mọ ohun to ṣe wọn ti wọn n binu jade, ẹbi wọn ni, o ni jijade wọn tumọ si pe ẹbẹ ti wọn n bẹ ile-ẹjọ pe ki wọn da awọn ẹsun tuntun ti wọn fi kan onibaara wọn nu ko ṣiṣẹ mọ niyẹn, ki igbẹjọ maa lọ ni pẹrẹu lori awọn ẹsun ọlọkan-o-jọkan ọhun ni.

Adajọ Nyako ni bo tilẹ jẹ pe oun o nifẹẹ si iwa tawọn lọọya Kanu hu bi wọn ṣe rọ jade ni kootu, sibẹ, oun o gba ẹbẹ olupẹjọ wọle pe kile-ẹjọ da ẹbẹ olujẹjọ nu, o ni igbẹjọ ṣi maa tẹsiwaju, ṣugbọn o di ọjọ mi-in ọjọ ire, lo ba sun igbẹjọ to kan si oṣu kin-in-ni, ọdun to n bọ.

Lara awọn ẹsun tuntun marun-un ti wọn fi kan Olori ẹgbẹ to n ja fun Orilede Biafra ni pe o n ko  ẹgbẹ afẹmiṣofo jọ, o fẹẹ doju ijọba de, o si tun ṣeku pa awọn araalu kan.

Leave a Reply