Kingsley dero ẹwọn, egboogi oloro lo fẹẹ gbe lọ siluu oyinbo ti wọn fi mu un

 Adewale Adeoye

Nitori pe o tete jẹwọ pe loootọ loun jẹbi ẹsun iwa ọdaran ti wọn fi kan an, ati pe eyi jẹ igba akọkọ rẹ to maa gbe egboogi oloro kokeeni nilẹ wa. Adajọ agba kan nile-ẹjo giga niluu Eko ti sọ pe ki ọkunrin oniṣowo kan to gbe egboogi oloro, Ọgbẹni Celestino Kingsley, ẹni tawọn eeyan mọ si Okafor Kingsley Ikenna, lọọ sẹwon ọdun mẹfa gbako pẹlu iṣẹ aṣekara lọgba ẹwọn l’Ekoo.

Adajọ Daniel Osiagor, lo ṣedajọ ọhun l’Ọjọruu., Wẹsidee, ọjọ karun-un, oṣu yii, nigba ti wọn gbe Ọgbẹni Celestino Kingsley wa siwaju rẹ fun idajọ to peye lori ẹsun ti wọn fi kan an.

Ọgbẹni Celestino Kingsley ti i ṣe ẹni ọdun mọkandinlaaadọta (49Yrs) ni ọlọpaa olupẹjọ to n ṣoju ajọ NDLEA, Agustine Nwagu ni ọwọ awọn oṣiṣẹ  ajọ NDLEA tẹ ninu ọkọ baalu ‘Qatar Airways’ to n lọ silẹ India, ṣugbọn to maa kọkọ deluu Doha, lọjọ kẹrin, oṣu Kẹta, ọdun yii. O ni ẹṣẹ ti Ọgbẹni Celestino Kingsley ṣẹ yii ta ko ofin ilẹ wa.

ALAROYE gbọ pe diẹ lo ku ki afurasi ọdaran yii gbe oogun naa kọja mọ awọn agbofinro lara, ṣugbọn ọwọ NDLEA pada tẹ ẹ nigba ti wọn n yẹ ẹru awọn to fẹẹ gbera nilẹ yii lọọ soke okun wo.

Ọlọpaa to n ṣoju ajọ NDLEA, Agustine Nwagu, sọ pe ṣe ni Kingsley lẹdi apo pọ pẹlu ọkunrin kan, Chibuzor Okoye, ti awọn ọlọpaa n wa bayii, lati gbe egboogi oloro ọhun lọ soke okun ko too di pe ọwọ tẹ ẹ.

Nibi ti ọlọpaa olupẹjọ sọrọ de ree ti Kingsley fi n rawọn ẹbẹ si adajọ pe ki wọn ṣiju aanu wo oun, o ni  igba akọkọ ree toun maa huwa naa.

Ṣugbọn bo ṣe n rawọ ẹbẹ naa ni agbefọba yii n ran adajọ leti pe ko ranti ohun ti ofin sọ, ati pe ijiya to tọ ni ki adajọ fi jẹ ọkunrin yii, bo tilẹ jẹ pe igba akọkọ rẹ ree ti yoo gbe egboogi oloro.

Nigba to n gbe ipinnu rẹ kalẹ, Daniel Osiagor,Sibẹ ni ki Celestino Kingsley lọọ ṣẹwọn ọdun mẹfa pẹlu iṣẹ aṣekara lọgba ẹwọn.

Ṣugbọn agbẹjọro ọkunrin naa rọ adajọ lati ṣiju aanu wo onibaara oun, o ni ko jẹ ko sanwo itanran dipo ko lọọ ṣẹwọn pẹlu bi ẹri ṣe fidi ẹ mulẹ pe igba akọkọ niyi ti yoo hu iru iwa bẹẹ.

Ipẹ ti lọọya Kingsley ṣe lo mu ki adajọ ni ki olupẹjọ san milọọnu meji aabọ Naira (N2.5M).

 

Leave a Reply