Kíréètì ọti bíà meji pere ni mo ji gbe lagọọ ọlọpaa lasiko iwọde SARS- Hamsat

Ọlawale Ajao, Ibadan

Ọkan ninu awọn afurasi ọdaran tọwọ awọn agbofinro tẹ fun pe wọn dana sun agọ ọlọpaa ilu Isẹyin lẹyin ti wọn ti ji gbogbo ẹru to wa nibẹ ko, Taoreed Hamsat, ti sọ pe dukia awọn ọlọpaa ti oun ji gbe ninu teṣan wọn ko pọ rara, oun ko gbe ju kireeti ọti bia meji pere lọ.

Ọmọkunrin ẹni ọdun mẹrindinlọgbọn yii, ẹni tawọn ẹgbẹ ẹ tun mọ si Shorlex, jẹ ọkan ninu awọn mẹsan-an tọwọ awọn agbofinro tẹ lori agọ ọlọpaa Isẹyin ti wọn dana sun lẹyin ti wọn ti le awọn agbofinro ibẹ lugbo, ti wọn si ji gbogbo dukia to wa ninu teṣan naa ko.

Nigba ti ọga agba awọn ọlọpaa ipinlẹ Ọyọ, CP Joe Nwachukwu Enwonwu, n ṣafihan oun atawọn yooku ẹ fawọn oniroyin l’Ọjọruu, Wẹsidee, ọsẹ yii, Hamsat ṣalaye pe, “Mo dara pọ mọ awọn to n ṣe iwọde nipa ọrọ SARS. Nigba ta a de teṣan ọlọpaa (ni Isẹyin), mo ri i ti kaluku n ko nnkan to wu u ninu ẹru to wa nibẹ nitori ba a ṣe yọ lọọọkan lawọn ọlọpaa to wa ni teṣan ti sa lọ.

“Kireeti ọti bia meji pere lemi ri gbe ni temi. Ki i si i ṣe pe mo gbe e lọ sile naa, iwaju teṣan yẹn naa ni mo gbe e si ti kaluku si n mu eyi to maa mu.

“Nnkan kan ṣoṣo ti mo le sọ pe mo ri gbe dele nibẹ ko ju jẹnẹretọ kekere lọ. Lọjọ keji ni mo si ti gbe e lọ si mọṣalaaṣi nigba ti Kabiesi, Asẹyin tilu Isẹyin, Ọba Ganiyy Adekunle, paṣẹ pe gbogbo awa ta a ji nnkan ko ni teṣan, ka tete da a pada si mọṣalaaṣi tabi aafin awọn.

“Ki i ṣe pe mo deede gbe jẹnẹretọ gan-an, nigba ti mo ri i pe wọn fẹẹ dana sun un pọ mọ teṣan ni mo gbe e ko ma baa jona. Aago ara ogiri ko si lara ẹru ti mo gbe ni teṣan, iwaju mọṣalaṣi ni mo ti ri i.

Tẹ o ba gbagbe, ọlọpaa mẹfa lawọn oluwọde dana sun ninu ikọlu ọtọọtọ lọsẹ to kọja laisko ti wọn n pe fun ifopin si SARS, iyẹn, ẹka ileeṣẹ ọlọpaa ilẹ yii to n gbogun ti idigunjale ti wọn si sun agọ ọlọpaa nina.

CP Enwonwu fidi eyi mulẹ pe oun ko ti i le sọ iye ọlọpaa ti awọn oluwọde naa pa lasiko ifẹhonu han wọn, ṣugbọn ọlọpaa mẹfa lawọn ti i le fidi ẹ mulẹ pe o ba iṣẹlẹ ọhun rin.

O waa ṣeleri pe gbogbo awọn to lọwọ ninu ikọlu awọn agọ ọlọpaa kaakiri ipinlẹ Ọyọ, eyi to ṣokunfa iku ọpọlọpọ agbofinro lọwọ awọn yoo tẹ, ti awọn yoo si fi wọn jofin bo ṣe tọ ati bo ṣe yẹ.

 

Leave a Reply