Ko mọgbọn dani ki epo bẹntiroolu dinwo ni Naijiria – Buhari

Aarẹ Muhammadu Buhari ti sọ pe ki i ṣe ohun to mu ọgbọn dani pe ki epo bẹntiroolu dinwo ni Naijiria ju ti awọn orileede yooku ti wọn n pese epo bii Ghana, Chad ati Niger lọ. Buhari sọrọ yii ninu ọrọ apilekọ rẹ fun ọdun ominira to waye ni Eagles Square, niluu Abuja, l’Ọjọbọ, Tọsidee, ọsẹ yii.

O ni orileede Ghana ti awọn naa n pese epo bentiroolu, okoolelọọọdunrun ati mẹfa ni wọn n ta lita epo kan (326). Bakan naa ni Niger, ojilelọọọdunrun ati mẹfa (346) ni wọn n ta jala bẹntiroolu kan, nigba ti orileede Chad n ta tiẹ ni ọtalelọọọdunrun o le meji naira (362).

Buhari fi kun un pe oun gbiyanju ju gbogbo awọn aarẹ to ti ṣejọba lọ pẹlu pe iwọnba owo ti ko to nnkan lo n wọle lasiko ijọba oun yii. Bẹẹ lo sọko ọrọ lu awọn aarẹ to ti ṣejọba kọja lasiko ijọba tiwa-n-tiwa yii pe wọn wa ninu awọn to ko ba ọrọ aje Naijiria.  Ẹ gbọ ṣe ootọ ni ọrọ ti Aarẹ Buhari sọ?

One thought on “Ko mọgbọn dani ki epo bẹntiroolu dinwo ni Naijiria – Buhari

Leave a Reply