Ko ni i ṣẹku agbebọn kankan mọ, ma a ṣẹgun gbogbo wọn ki n too kuro nipo-Buhari

Faith Adebọla

 Olori orileede wa, Aarẹ Muhammadu Buhari ti ṣeleri pe oun maa ri i daju pe ko ṣeku agbebọn tabi afẹmiṣofo kan ni Naijiria koun too gbejọba silẹ lọdun 2023, o ni kawọn araalu lọọ fọkan balẹ, oun maa ṣegun ṣẹtẹ wọn patapata ni.

Nibi apejẹ kan ti ijọba ipinlẹ Kaduna ṣeto fun un laṣaalẹ ọjọ Abamẹta, Satide, ọjọ kejilelogun, oṣu yii, lati kadii abẹwo ọlọjọ mẹta to ṣe si ipinlẹ naa lo ti sọrọ yii.

O loun gboṣuba gidi fun ijọba ipinlẹ Kaduna, eyi ti Mallam Nasir El-Rufai jẹ gomina rẹ, lori isapa wọn lati pese aabo to peye fun ẹmi ati dukia, paapaa fun bi wọn ṣe ṣedasilẹ ẹka ileeṣẹ ọba kan lori ipese aabo abẹle fawọn eeyan ipinlẹ Kaduna.

Buhari ni “Mo fẹẹ fi da ẹyin eeyan ati ijọba ipinlẹ Kaduna loju pe ijọba apapọ n gbe gbogbo igbesẹ to yẹ lati rẹyin awọn agbebọn, awọn afẹmiṣofo to n daamu awọn araalu ati dukia wọn kaakiri orileede yii. A maa ri i daju pe ko ṣẹku agbebọn kankan mọ ki n too gbejọba silẹ lọdun 2023.

“Gomina yin ti beere pe ka tubọ ṣeranwọ si i pẹlu awọn ọmoogun ti yoo ro eto aabo lagbara, a si maa ṣe bẹẹ kiakia.

“Ko ya mi lẹnu pe Nasir El-Rufai ati awọn ẹmẹwa rẹ ti ṣaṣeyọri awọn ohun amayedẹrun ati iṣẹ akanṣe kaakiri awọn ẹkun idibo apapọ mẹtẹẹta to wa nipinlẹ yii, tori mo ti kọkọ waa ṣi ileeṣẹ ipese ounjẹ adiẹ nla ati ileeṣẹ ipese oromọdiẹ lọdun 2017, mo si tun waa ṣi abala keji ileeṣẹ ipese omi kale-kako to wa niluu Zaria, lọdun 2019, ni bayii, mo tun foju ara mi ri awọn iṣẹ akanṣe tijọba rẹ ṣe.”

CAPTION 

 

Leave a Reply