Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta
Akọsilẹ ijọba lori Abiọdun Ọshọba ati Mustapha Ṣakiru ni pe ẹlẹwọn ni wọn. Ọdun 2020 to kọja yii ni wọn ṣẹṣẹ fi wọn silẹ lọgba ẹwọn Igbeba, n’Ijẹbu-Ode. Afi bi wọn ṣe jade tan to tun jẹ ọkada ni wọn fibọn gba lọjọ kejilelogun, oṣu keji yii, ni Ṣagamu, nibi ti wọn ti n sa lọ lọwọ palaba wọn ti segi.
Ọlọkada kan torukọ ẹ n jẹ Aminu Iliyasu ni wọn ni ko gbe awọn lọ si otẹẹli kan ni Ṣagamu, nigba tiyẹn ko si mọ pe wọn lero mi-in lọkan, o gbe wọn loootọ.
Nibi ti wọn ti n rin irinajo naa lọwọ ni wọn ti yọ ibọn si ọlọkada Bajaj ti nọmba ẹ jẹ SGM 965VQ naa, wọn ni ko duro bẹẹ ko sọkalẹ, ko gbe ọkada naa fawọn, ko si fa eti ẹ mejeeji, ko maa sa lọ.
Aminu ọlọkada ṣe bi wọn ṣe wi, ṣugbọn ko gba kamu sara bẹẹ, teṣan ọlọpaa Ṣagamu lo gba lọ gẹgẹ bi Oyeyẹmi Abimbọla, Alukoro ọlọpaa ipinlẹ Ogun ṣe fidi ẹ mulẹ.
Teṣan yii ni wọn ti mu awọn fijilante mọra, n ni wọn ba di gbogbo ọna to jade ni GRA Ṣagamu yii, ohun to si ran wọn lọwọ ti wọn fi ri awọn afurasi mejeeji naa mu niyẹn.
Abiọdun ati Mustapha ti ka nọmba ara ọkada naa penpe, ko see ri i lara rẹ mọ.
Ṣugbọn bi Abiọdun ṣe ri awọn ọlọpaa ti wọn n ṣọ ọna ti wọn n gba bọ, niṣe lo fi ọkada naa silẹ, to bẹrẹ si i fi ẹsẹ rẹ sare lọ. Awọn ọlọpaa naa gba tọ ọ, wọn si ri i mu.
Bi wọn ṣe mu un ni wọn mu Mustpaha, iwadii si fidi ẹ mulẹ pe ọdun 2016 ni Ṣakiru Mustpha wọ ọgba ẹwọn, nitori tirela ti wọn lo ko lọna, to si fẹẹ ja gba. Ọdun 2019 ni Abiọdun ṣẹwọn ni tiẹ, Alukoro sọ pe foonu lo ja gba to fi di ero ọgba ẹwọn.
Inu ẹwọn ọhun ni wọn ti pade, ni wọn ba di ọrẹ ojiji, wọn si pinnu lati da ikọ adigunjale tiwọn silẹ bi wọn ba ti jade. Bi wọn si ti gba ominira ni 2020 naa ni wọn bẹrẹ iṣẹ alọkolohun kigbe ọhun pada, to fi di pe wọn tun ko sọwọ lẹẹkeji. Ibọn ilewọ ibilẹ kan ati ọta ibọn ti wọn ko ti i yin lawọn ọlọpaa ba lọwọ wọn.
Ọga ọlọpaa pata nipinlẹ yii, CP Edward Ajogun, ti ni ki wọn ko wọn lọ sẹka iwadii, ibẹ ni wọn wa lasiko yii ti wọn n ṣe faaji wọn.