Ko pẹ ti Lekan atọrẹ ẹ tẹwọn de ni wọn tun lọọ jale l’Abẹokuta, ladajọ ba ni ki wọn pada sibi ti wọn ti n bọ

Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta
‘Lẹyin ti aridaju ti fi han pe ẹ jẹbi ẹsun ti a fi kan yin, a oo yẹgi mọ yin lọrun titi ti ẹmi yoo fi bọ lara yin. K’Ọlọrun ṣaanu fun yin’
Bayii ni Adajọ Ayọkunle Rotimi-Balogun, ti ile-ẹjọ giga ilu Abẹokuta, sọ lọsẹ to kọja yii nipa awọn ọkunrin meji kan, Lekan Akinọla, ẹni ogoji ọdun ati Dare Ṣowumi, ẹni ọdun mẹtadinlọgbọn, ti wọn fẹsun idigunjale kan. Bẹẹ, awọn mejeeji ki i ṣe ẹlẹṣẹ igba akọkọ, wọn ti ṣẹwọn ri ki wọn too tun lọọ digunjale, ti ọwọ si ba wọn.
Agbẹnusọ ijọba, Agbẹjọrọ agba Oluwabunmi Akinọla, ṣalaye fun kootu pe ile Oloye Derin Adebiyi ni awọn meji yii ti digunjale lọjọ kẹtadinlọgbọn, oṣu kin-in-ni, ọdun 2019, ni deede aago meji ku iṣẹju marun-un, loru.
O ni ile naa wa lojule kejilelọgbọn, Legislative Quarters, Ibara, Abẹokuta. Agbẹnusọ ijọba tẹsiwaju pe Lekan ati Dare gba miliọnu meji aabọ naira lọwọ Oloye Adebiyi, wọn ko aago ọwọ mẹfa, ṣeeni ọrun to jẹ goolu delẹ; marun-un, foonu mẹta, ṣaaja to n lo oorun (Solar charger) ati kọkọrọ ọkọ ayọkẹlẹ Camry kan.
Akinọla fi to kootu leti pe ọdun 2018 ni wọn ṣẹṣẹ fi awọn olujẹjọ meji yii silẹ lọgba ẹwọn, lẹyin ti iwa arufin wọn gbe wọn debẹ. Bi wọn ṣe jade ni wọn tun lọọ ja Oloye Derin lole loṣu kin-in-ni, ọdun 2019.
O ṣalaye pe Sango-Ọta lọwọ ti ba Lekan lọjọ naa lẹyin to jale nile oloye yii tan, to n pada lọ sile. Ẹgbẹrun lọna ẹgbẹta naira (600,000) lo ni wọn ba lara ẹ, pẹlu diẹ ninu awọn dukia ti wọn ji nile oloye yii. Mimu ti wọn mu un naa lo ṣatọna bi ọwọ ṣe ba Dare pẹlu, ti wọn fi bẹrẹ ẹjọ latigba naa, ki ile-ẹjọ giga too fori ẹ ti sibi iku fun wọn lọjọ Iṣẹgun to kọja.
Bo tilẹ jẹ pe titi ti wọn fi pari ẹjọ naa lawọn eeyan yii n sọ pe awọn ko jẹbi, kootu fidi ẹ mulẹ pe awọn nnkan ija bii ibọn ati ada ti wọn ko wọle oloye, ti wọn si ko hilahilo ba awọn eeyan ibẹ, ti wọn tun ja wọn lole, lodi si ofin orilẹ-ede yii, paapaa, ofin to ni eeyan ko gbọdọ ni nnkan ọṣẹ lọwọ, ati eyi to lodi si fifọle onile jale.

Leave a Reply