Ko pẹ ti Ọladapọ tẹwọn de lo tun lọọ ja ọkọ gba n’Ilọrin

Ibrahim Alagunmu, Ilọrin
Ko jọ pe ọmọkunrin kan ti wọn porukọ rẹ ni Ọlaoye Ọladapọ kọ ẹkọ kankan lọgba ẹwọn to ti lo ọdun mẹta ki wọn too da a silẹ rara. Nitori ko pẹ to ti ọgba ẹwọn naa de to tun fi bẹrẹ idigunjale. Ọkọ ayọkẹlẹ Volkswagen Golf 3, kan loun atawọn ẹgbẹ ẹ tun lọọ fibọn gba lagbegbe Fate, niluu Ilọrin, nipinlẹ Kwara.
Nigba to n ṣafihan ọmọkunrin ti ko lọrọ ọ gbọ yii, Kọmiṣanna ọlọpaa ni Kwara, Paul Odama, sọ fawọn oniroyin lọjọ Ẹti, Furaidee, ọjọ kejila, oṣu Karun-un yii, pe arakunrin, kan Tijani Wasiu, to n gbe ni agbegbe Alálùbọ́sà, niluu Kìshí, nipinlẹ Ọyọ, lo mu ẹsun lọ si agọ ọlọpaa E Division, Kúléndé, niluu Ilọrin, pe awọn adigunjale mẹrin kan ti wọn faṣọ boju ja ọkọ ayọkẹlẹ Volkswagen Golf 3, gba lọwọ oun lẹnu ibọn ni Àmàlà Palace, lagbegbe Fate, niluu Ilọrin.
Eyi lo mu ileesẹ ọlọpaa bẹrẹ iwadii, lẹyin gbogbo akitiyan wọn ni aṣiri tu pe Ọlaoye Ọladapọ, lo tun ṣiṣẹ buruku naa, lẹyin to si ti digun ja ọkunrin onimọto yii lole lo ti ko aaṣa rẹ, to si gba ipinlẹ Niger lọ.
Ilu Bida, nipinlẹ naa lọwọ ti pada tẹ ẹ, to si jẹwọ pe oun jẹ ọkan lara awọn to ja ọkọ naa gba, ati pe oun ṣẹṣẹ de lati ọgba ẹwọn ni, ọdun mẹta loun si lo nibẹ ki wọn too tu oun silẹ.
Odama ni lẹyin ẹkunrẹrẹ iwadii ati iṣẹ takuntakun, ileeṣẹ ọlọpaa tun mu Isaac Idowu, ti wọn jọ n digunjale. A gbọ pe ijọba ṣẹṣẹ dariji oun naa lati ọgba ẹwọn to wa ni. Awọn adigunjale yii ni wọn maa n ja ọkọ gba, ti wọn yoo si tun yinbọn pa ẹni ti wọn ja lole. Kọmiṣanna ni lẹyin iwadii, awọn afurasi naa yoo foju ba ile-ẹjọ.

Leave a Reply