KO SAAYE ỌDUN IBILẸ KANKAN NI GBOGBO EKITI BAYII O

Gbogbo ọdun ibilẹ pata ni wọn ti fi ofin de ni ipinlẹ Ekiti bayii o. Bo ṣe ọdun eegun tabi ti ooṣa yoowu, ko si ẹni to gbodọ ko ero lẹyin, tabi ko gbọngudu gbọngudu ilu kan jade, ki wọn ni awọn n ṣe ọdun oosa awọn. Ko si ohun meji to fa eleyii ju ọrọ arun koronafairọọsi to wa nita bayii lọ.

Ijọba ipinlẹ naa funra wọn ni wọn gbe atẹjade yii sita, nibi ti Ọjogbọn Bọlaji Aluko to jẹ alaboojuto agba fun eto imojuto arun Korona yii ti sọ fun gbogbo awọn ọba alaye ati alaṣẹ ilu pe ki wọn fopin si gbogbo ọdun iblẹ yoowu lagbegbe wọn lẹsẹkẹsẹ. Aluko ni titi ti ọdun yii yoo fi pari, ko gbọdọ si ọdun ibilẹ nibi kan nitori ajakalẹ arun naa to n gbilẹ kaakiri si i.

 

 

Leave a Reply