Ko seeyan tori ẹ pe to maa ni bi Buhari ṣe n ṣejọba yii lo daa ju loju oun-Ayọ Adebanjọ

Faith Adebọla, Eko

 Olori ẹgbẹ ajijangbara ilẹ Yoruba nni, Afẹnifẹre, iyẹn Alagba Ayọ Adebanjọ, ti fesi si oko ọrọ ati awọn ẹsun ti Oloye Bisi Akande fi kan an ninu iwe rẹ to ṣẹṣẹ ko jade bii ọmọ ọjọ mẹjọ lọsẹ to kọja, ti wọn pe akọle rẹ ni ‘My Participation,’ lede eebo.

Lasiko to n dahun ibeere ifọrọwanilẹnuwo eto ori tẹlifiṣan ayelujara Arise, lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọsẹ yii, ni Adebanjọ ti ṣapejuwe Bisi Akande bii ope nidii oṣelu, o ni gbogbo ọna ni gomina ipinlẹ Ọṣun tẹlẹ ri naa fi kere sẹni toun maa maa fesi sohun to ba sọ.

Ṣe ninu iwe ti Akande kọ lo ti kọkọ tẹmbẹlu Alagba Adebanjọ, o fẹsun kan baba naa pe ọkanjua ẹda ni, niṣe lo da Tinubu laamu pe ko foun nilẹ, ko si ba oun kọle si i, ati pe ijẹkujẹ ti wọn fẹẹ jẹ nidii oṣelu lo mu ki wọn fagba ara lọọ kopa nibi ipade apero iwe ofin ilẹ wa to waye lọdun 2014, lasiko iṣejọba Ọmọwe Goodluck Jonathan, gẹgẹ bii aarẹ ilẹ wa, o si tun fẹsun abuku kan baba naa loriṣiiriṣii.

Ninu ọrọ rẹ, Baba Adebanjọ sọ pe:

“Bisi Akande kere pupọ si mi, ki i ṣe ẹni to le sọrọ oṣelu ti maa fesi si. Ope patapata ni lagbo oṣelu. Mo ti mọ ọn tẹlẹ bii baba nla opurọ, iyẹn ki i ṣe tuntun. Ọrẹ rẹ kan, Akinfẹnwa, ninu iwe kan to kọ pe e ni aturọta ẹda, iyẹn o si jọ iru awa loju. Abẹṣin-kawọ lo n ṣe lẹyin Tinubu.

“O ti kere ju sẹni to maa sọrọ temi aa maa fesi si. Emi ni mo ba a buwọ luwee to fi jẹ gomina. Lara adehun ta a si jọ ṣe ko too di gomina ni pe ko lo ipo rẹ lati ṣeto apero gidi lori iwe ofin ilẹ wa, ki atunto le waye lori ajọṣe Naijiria. Adehun ta a tori ẹ dibo fun un lọdun 1999 niyẹn, ṣugbọn niṣe lo yẹ adehun.

“Atoun, ati Bọla Tinubu, ati Ṣẹgun Ọṣọba, gbogbo wọn la pe, ta a ṣekilọ fun wọn nigba ti wọn yẹ adehun. Wọn ti ta iran Yoruba fun Muhammadu Buhari tori ki Bọla Tinubu le jẹ aarẹ ni gbogbo ọna. Wahala tiwọn niyẹn, ki i ṣe temi ṣa o.

“Ṣugbọn keeyan maa purọ ojukoroju bii eyi lo toju su mi, mi o si mọ bi iru Akande to loun wa lara ọmọlẹyin Ọbafẹmi Awolọwọ latilẹ ṣe le maa fi iru ijọba Buhari yii yangan, ko tun maa kopa ninu ẹ, iṣakoso buruku to jẹ ọpọ awọn ti wọn ti i lẹyin dori aleefa ni wọn ti n geka abamọ jẹ.

“Ko seeyan ti ori ẹ pe kan to maa ni bi Buhari ṣe n ṣejọba yii lo daa ju loju oun Ko si onilaakaye ẹda kan to jẹ fi iru Buhari yii yangan. Bi Bisi Akande ṣe ṣe yii fi iru ẹni to jẹ han ni.

“Agbọ-gbọnti-nu lemi fi ọrọ ẹ ṣe.”

Leave a Reply