Ko sẹni to le da wa duro, iwọde Yoruba Nation maa waye l’Ekoo loṣu keje

Faith Adebọla

Bi ko ba si ayipada, ọjọ Abamẹta, Satide, ọjọ kẹta, oṣu keje, to n bọ yii, niluu Eko yoo gbalejo gbajugbaja ajafẹtọọ ilẹ Yoruba nni, Sunday Adeyẹmọ, tawọn eeyan mọ si Sunday Igboho, pẹlu awọn alatilẹyin ẹ lori iwọde ti wọn fẹẹ ṣe lati polongo idasilẹ orileede Yoruba, iyẹn ‘Oduduwa Nation’.

Sunday Igboho ti sọ pe Yẹkinni kan ko le yẹ ẹ kawọn ma ṣe iwọde ọhun, o ni iwọde to lagbara lo maa jẹ pẹlu.

Igboho Ooṣa, bawọn kan ṣe maa n pe e, sọrọ latẹnu agbẹnusọ rẹ, Ọlayọmi Koiki, ninu fidio kan ti wọn fi lede sori atẹ ayelujara lopin ọsẹ to kọja yii, o ni: “A ti fi mẹseeji alafia ṣọwọ si Gomina Babajide Sanwo-Olu, a ti jẹ ki wọn mọ pe iwọde wa maa waye, iwọde alaafia si ni. Ko seyii to kan wa nipa awọn mi-in ti wọn ba n sọ pe ka ma wa s’Ekoo. Sanwo-Olu ni ọga agba lori eto aabo ipinlẹ Eko, awa si n bọ l’Ekoo.

Ọjọ kẹta, oṣu keje, ni ọjọ pataki naa, ko sẹni to le sọ pe ka ma wa s’Ekoo, tori iwọde alaafia ni.

A ti lọ si Ogun, a ti ṣe ti Ondo, Ọṣun, Ekiti ati Ọyọ ta a ti bẹrẹ, wọọrọwọ la n ṣe awọn iwọde wa, tori naa, ko si ọrọ ninu pe ka ma wa s’Ekoo, awa n bọ l’Ekoo.”

Bayii ni Sunday Igboho ṣe fọwọ ẹ gbaya pe iwọde Yoruba Nation n kanlẹkun nipinlẹ Eko, laipẹ.

Iwọde yii wa lara eto ti Sunday Igboho lawọn n ṣe lati mura ẹya Yoruba silẹ fun yiyapa kuro lara orileede Naijiria, ki wọn si da orileede tiwọn silẹ, igbesẹ yii ọkunrin ajafẹtọọ naa sọ pe ko si biboju wẹyin lori ẹ, o ni dandan ni ki Yoruba kuro lara Naijiria laipẹ.

Titi dasiko ti a fi n ko iroyin yii jọ, ileeṣẹ ọlọpaa Eko ati gomina ipinlẹ Eko ko ti i sọrọ lori iwọde to fẹẹ waye ọhun.

Leave a Reply