‘‘Ko sẹni to le yọ Ọjọgbọn Akitoye nipo aṣaaju Yoruba’’

Ọlawale Ajao, Ibadan

Àjàtúká lo gbẹyin ipade awọn ẹlẹgbẹjẹgbẹ ilẹ Yoruba n’Ibadan nigba ti awọn kan gbiyanju lati yọ Ọjọgbọn Banji Akintoye nipo aṣaaju Yoruba l’Ọjọbọ, Tọsidee, to kọja.

Awijare awọn to fẹẹ yọ baba naa nipo ni pe baba funra rẹ lo mọ-ọn-mọ fi ipo naa silẹ pẹlu bo ṣe sọ pe oun ko ṣe apapọ ẹgbẹ Yoruba World Congress (YWC), iyẹn apapọ awọn ẹgbẹ ọmọ Yoruba kaakiri agbaye mọ, bẹẹ, ẹgbẹ yii ni wọn fi i ṣe olori Yoruba le lori.

Ninu ipade YWC ọhun to waye ninu gbọngan igbimọ awọn lọbalọba to wa ninu sẹkiteriati ijọba ipinlẹ Ọyọ, n’Ibadan, lawọn ẹlẹgbẹjẹgbẹ to kopa nibẹ ti bu ẹnu atẹ lu bi Ọjọgbọn Akintoye ṣe deede fi ẹgbẹ naa silẹ, wọn ni niṣe lo gbe igbesẹ yii lati yọ ara rẹ kuro nipo aṣaaju Yoruba ti awọn yan an si, ṣugbọn awọn ko ni i yan ẹlomi-in rọpo rẹ bayii nitori awọn gba pe oun ṣi laṣaaju awọn.

Nigba to n fidi ipinnu yii mulẹ, Baalẹ Ekotẹdo, Oloye Taiwo Ayọrinde, sọ pe “Sadeede la gbọ pe Ọjọgbọn Banji sọ pe oun ko ṣe ẹgbẹ YWC mọ, ̣ẹgbẹ Ilana Ọmọ Oodua ti oun ṣẹṣẹ da silẹ bayii loun n ṣe. Eyi ṣe wa ni kayeefi, ṣugbọn awa igbimọ ẹgbẹ gbogbo ọmọ Yoruba kaakiri agbaye fi asiko yii sọ pe awa ko yọ ọ nipo, oun naa ṣi laṣaaju wa, ṣugbọn o ni lati ṣe oun ti gbogbo awa ta a yan an sipo n fẹ.”

Ṣugbọn ohun ti olupepade ọhun, Ọgbẹni Victor Taiwo, tori ẹ pepade naa ni lati jẹ ki awọn olukopa nibi apero naa ṣagbeyẹwo awọn aiṣedeede Ọjọgbọn Akintoye, ki wọn si yọ ọ nipo aṣaaju Yoruba loju ẹsẹ nibẹ. Ṣugbọn nibi to ti n ka awọn ẹsun naa jade ninu iwe to kọ ọ si ni wahala ti bẹ silẹ nigba ti Ọgbẹni Ṣina Akinpẹlu, agbẹnusọ fun ẹgbẹ OPC ipinlẹ Ọyọ, jagbe mọ ọn nibi to ti n ba gbogbo eeyan sọrọ lọwọ pe ko gbẹnu dakẹ, o lo kere si gbogbo ọrọ to n sọ jade lẹnu naa, ati pe ko sẹni to le yọ ọjọgbọn naa nipo.

Diẹ lara awọn ẹsun ti Ọgbẹni Taiwo ka si baba naa lẹsẹ ni pe o n ṣe ijọba bii ijọba apàṣẹwàá pẹlu bo ṣe yọ oun atawọn oloye ẹgbẹ Yoruba World Congress mẹrin mi-in bii Oloye Tọla Adeniyi, Dokita Amos Akingba atawọn meji mi-in nipo, eyi to mu ki awọn mẹrin yooku naa kede pe awọn paapaa ti rọ ọ loye.

Ohun to wa ninu apilẹkọ Ọgbẹni Taiwo ni lati pada kede igbimọ ẹlẹni mọkanla kan ti yoo maa ṣakoso ẹgbẹ YWC titi digba ti wọn yoo fi yan aṣaaju mi-in pẹlu awọn ijoye ti yoo maa ba a ṣiṣẹ, ṣugbọn awọn eeyan ko jẹ ko ka iwe ọhun tan debi ti yoo kede orukọ awọn ọmọ igbimọ yii ti wọn fi da ipade naa ru mọ ọn lọwọ.

Gẹgẹ bo ṣe wa ninu iwe ọhun, Oloye Taiwo Ayọrinde ni wọn fi ṣe alaga igbimọ naa. lara awọn ọmọ igbimọ yooku ni Dokita Amos Akingba, Oloye Tọla Adeniyi, Dokita Tunde Amusat, Sheik Abdul-Raheem Aduranigba to jẹ imaamu agba fawọn ọmọ Yoruba niluu Ilọrin, Ọtunba Deji Ọṣibogun ati Ọjọgbọn Oluwakayọde Ogundoro.

Awọn yooku ni Abilekọ Dupẹ Ajayi-Gbadebọ, Ọgbẹni Laoye Sanda, Ọgbẹni Tajudeen Raimi ati Ọgbẹni Victor Taiwo funra rẹ. Ninu igbimọ yii naa l’Ọgbẹni Taiwo si sọ pe wọn yoo ti pada kede aṣaaju Yoruba titun atawọn igbimọ ijọba rẹ.

Ṣugbọn nigbẹyin, gbogbo awọn ẹlẹgbẹjẹgbẹ to wa nibẹ yari, wọn lawọn ko yọ Ọjọgbọn Akintoye nipo aṣaaju. Alukoro apapọ ẹgbẹ Oodua People’s Congress (OPC) nilẹ yii, Ọgbẹni Kazeem Lawal, lo kọ sọ bẹẹ, o ni loootọ, Ọgbẹni Taiwo l’Ọlọrun lo lati yan baba naa sipo aṣaaju Yoruba, ṣugbọn ko ṣee ṣe fun un lati yọ ọ. Lẹyin naa ni Ọgbẹni Hbib Ọlalekan Hammed ti i ṣe aarẹ ẹgbẹ Yoruba Youth Socio-cultural Association (YYSA) ti awọn ẹgbẹ yooku naa si fọwọ si i, wọn ni bo ku irawọ kan ṣoṣo ni sanmọ, Ọjọgbọn Akintoye lawọn n ba lọ.

Ninu ifọrọwerọ pẹlu akọroyin wa lẹyin ipade naa, Baṣọrun Adekunle Adeṣọkan, ẹni to ṣoju Ọjọgbọn Akintoye nibi ipade ọhun sọ pe baba naa ko sọ pe oun ko ṣe aṣaaju Yoruba mọ, gbogbo ọjọ aye ẹ lo fi n ja fun ominira ilẹ Yoruba laiboju wẹyin.

Leave a Reply