Ko siṣẹ lọjọ Alamisi ati ọjọ Jimọ o, nitori ọdun Ileya ni

Ijọba apapọ orilẹ-ede yii ti kede pe ko ni i si iṣẹ ni Ọjọbọ, Tọsidee, ọtunla ati ọjọ Ẹti, Furaidee ọjọ mẹrin oni. Ọlude Ileya ti wọn fun awọn eeyan ni wọn ṣe kede bẹẹ, wọn ni ki kaluku le lo anfaani lati ṣe ọdun naa ni aṣegbadun ni.

Ninu atẹjade to ti ọọffiisi Minisita ileeṣẹ to n ri si ọrọ abẹle ilẹ yii, Ọgbẹni Raufu Arẹgbẹṣọla, jade, ijọba ki gbogbo Musulumi orilẹ-ede yii ku ọdun, wọn si gbadura pe ọdun yoo yabo. Ijọba ni ki gbogbo Musulumi lo akoko yii lati fi na ọwọ ifẹ ati aanu si ọmọlakeji wọn.

Alaroye paapaa ni ọdun ayọ la o ṣe.

Leave a Reply