Ibrahim Alagunmu, Ilọrin
Alaga ẹgbẹ oṣelu All Progressive Congress (APC), ni Kwara, Sunday Fagbemi, ti sọ pe oludije sipo aarẹ lẹgbẹ APC, Asiwaju Bọla Ahmed Tinubu, lawọn yoo ko gbogbo ibo Kwara fun nibi eto idibo gbogbogboo ọdun 2023.
Fagbemi sọrọ yii lọjọ Ẹti, Furaide, nibi eto ifilọlẹ ipolongo ibo ti awọn obinrin ẹgbẹ APC ṣe fun Tinubu niluu Ilọrin, ti i ṣe olu ipinlẹ naa, eyi ti iyawo Aarẹ, Aishat Buhari, aya Shettima, iyawo Tinubu atawọn iyawo gomina miiran jake-jado ilẹ wa, peju sibi eto naa. Gomina ipinlẹ Kwara, Abdulraman Abdulrasaq paapaa ko gbẹyin.
Aishat Buhari ni o da oun loju pe awọn ọdọ ati obinrin lorile-ede yii yoo ṣe atilẹyin fun Tinubu, ti yoo si jawe olubori nibi eto idibo apapọ ọdun 2023. O tẹsiwaju pe lọdun 2015, wọn ṣe e, lọdun 2019, wọn ṣe e, wọn yoo si tun ṣe e lọdun 2023 latari aṣeyọri alailẹgbẹ ti ẹgbẹ oṣelu APC ti ṣe lẹnu igba ti wọn ti gbakoso iṣejọba Naijiria, ti wọn ko si fọrọ obinrin sere.
O fi kun un pe ẹgbẹ alaafia ni ẹgbẹ oṣelu APC, o rọ awọn obinrin ki wọn fara wọn ji si ipolongo ibo fun Tinubu, ki wọn si ma fi ọwọ kekere mu ọrọ ki ẹgbẹ naa bori.
Gomina Abdulrahman Abdurazaq, dupẹ lọwọ wọn pẹlu bi wọn ṣe mu ipinlẹ Kwara, gẹgẹ bii aaye ifilọlẹ ipolongo ibo awọn obinrin fun Tinubu. O tẹsiwaju pe ko si aaye fun ẹgbẹ oṣelu miiran ni Kwara, Tinubu ni yoo bori latari awọn aseyọri to ti ṣe, paapaa ju lọ nigba to jẹ gomina nipinlẹ Eko.
Aya gomina ipinlẹ Kwara, Olufọlakẹ Abdulrazaq, naa jẹẹjẹ pe awọn obinrin ati ọdọ ni Kwara yoo dibo lọpọ yanturu fun Tinubu lọdun 2023 latari aseyọri ti ẹgbẹ oṣelu APC ti ṣe.
Iyawo Tinubu, Sẹnetọ Olurẹmi Tinubu, sọ pe gbogbo araalu ni yoo jẹ anfaani ijọba awa-ara-wa ti ainisẹ lọwọ awọn ọdọ yoo si dinku.