Florence Babasola
Akọwe iroyin fun Ọọni Ogunwusi, Moses Ọlafare ti sọ pe ko si ootọ ninu ahesọ kan to n lọ kaakiri pe aafin Arole Oodua niluu Ileefẹ ti jona. Ọlafare sọ pe loootọ nijamba ina ṣẹlẹ ni nnkan bii aago kan ọsan oni, ṣugbọn yaara kekere kan lara ibi ti awọn oṣiṣẹ n lo niṣẹlẹ naa ti ṣẹlẹ.
O ni lọgan ni adari aabo laafin Ọọni, Kọlawọle Emmanuel, ati awọn oṣiṣẹ panapana ti Ọbafẹmi Awolọwọ University ti dide si ọrọ naa, ti gbogbo nnkan si pada bọ sipo.
Ọlafare fi kun ọrọ rẹ pe digbi ni gbogbo nnkan wa laafin Ọọni, ko si aburu kankan, bẹẹ ni ko si ẹni to farapa.