Ko si aisan ti ewe at’egbo ti Ọlọrun fun Yoruba ko gbọ, ṣugbọn a ko kọbi ara si i mọ-Ẹlẹbuibọn

Adefunkẹ Adebiyi,Abẹokuta

Lọsẹ to kọja yii ni Gomina ipinlẹ Ogun, Ọmọọba Dapọ Abiọdun, pepade awọn alẹnulọrọ ninu lilo tewe-tegbo ilẹ wa fun iwosan si gbọngan Iṣẹmabaye ‘June 12’ to wa ni Kutọ, l’Abẹokuta. Nibẹ ni Araba Ifayẹmi Ẹlẹbuibọn ti jẹ ko di mimọ pe nnkan ti n sọnu nilẹ Yoruba, paapaa awọn nnkan iṣẹdalẹ, o si ṣe ni laaanu pe a o fura.

Oloye Ẹlẹbuibọn ṣalaye pe ko si aisan naa ti ewe ategbo ti Ọlọrun fun ilẹ Yoruba ko gbọ, ṣugbọn awọn eeyan ko kọbi ara si i mọ. O ni oogun oyinbo to jẹ to ba wo aisan kan, yoo ko wahala mi-in ba ara ni wọn n fowo gọbọi ra, ohun to si n fa iku aitọjọ fawọn mi-in niyẹn.

Nigba to n ṣalaye lori awọn nnkan ti Yoruba n sọnu, baba onifa naa sọ pe ede Yoruba ti a n sọ paapaa le lọ si okun igbagbe, nigba ti awọn eeyan ko ba sọ ọ mọ, nitori ede oyinbo lo ku ti ọpọ obi n sọ si awọn ọmọ wọn nile bayii. Bẹẹ, wọn ti n sọ Yoruba ni Brazil, Trinidad ati Tobago, ṣugbọn awa ti a ni ede naa ko fi yangan mọ, bii pe ohun to jẹ tiwa ko wu wa mọ la n ṣe.

O fi kun un pe kawọn to n fi tewe-tegbo ṣewosan lọọ kọ ewe nibi to ti n jẹ, ki wọn si ma ṣe ohun ti wọn ko mọ loogun fawọn eeyan, ko ma baa di pe ijọba n le wọn kiri.

Ninu ọrọ Gomina Dapọ Abiọdun, ẹni ti Igbakeji ẹ, Onimọ-ẹrọ Nọimọt Salakọ, ṣoju fun, o rọ awọn to n fi tewe-tegbo ṣewosan pe ki wọn mọ iṣẹ ti wọn n ṣe naa dunju, ki wọn ma si faaye gba awọn aṣawọ, nitori ẹmi ṣe koko.

About Alaroye

Journalist, Press man and News Researcher of the federal Republic of Nigeria

Check Also

Nitori to ni oun yoo fopin si eto aabo ni Borno ati Yobe, PDP Ekiti sọrọ si Fayẹmi

Taofeek Surdiq, Ado-Ekiti Ẹgbẹ PDPipinlẹ Ekiti ti yẹgẹ ẹnu si gomina ipinlẹ Ekiti, Dokita Kayọde …

Leave a Reply

//dooloust.net/4/4998019
%d bloggers like this: