Ko si idanwo WAEC lọdun yii – Ijọba apapọ

Oluyinka Ṣoyẹmi

Ijọba apapọ ti kede pe ko si idanwo aṣekagba ileewe girama tawọn eeyan mọ si WAEC lọdun yii pẹlu bo ṣe yẹ ko bẹrẹ lọjọ kẹrin, oṣu to n bọ.

Bakan naa ni ikede waye pe awọn ileewe ijọba apapọ tijọba n gbero boya ki wọn wọle laipẹ ko ni i wọle mọ.

Minisita fun eto ẹkọ, Adamu Adamu, lo kede ọrọ naa lẹyin ipade igbimọ alaṣẹ ti Aarẹ Muhammadu Buhari dari lonii, Ọjọru, Wẹsidee.

Adamu ni ajọ to n ṣagbatẹru idanwo aṣekagba ko le paṣẹ ọjọ tawọn ileewe orilẹ-ede yii yoo wọle, bẹẹ lo ṣapejuwe iwọle lasiko yii bii igba teyan fẹẹ ṣe awọn ọmọleewe nijamba.

O waa rọ awọn ijọba ipinlẹ ti wọn ti kede ọjọ iwọle awọn ọmọleewe lati  yi ipinnu wọn pada ki gbogbo eeyan nilẹ yii le pawọpọ ba arun Koronafairọọsi to da gbogbo iṣoro yii silẹ ja.

Tẹ o ba gbagbe, awọn ọmọleewe Naijiria, Ghana, Sierra Leone, Gambia ati Liberia lo n ṣe idanwo WAEC.

Leave a Reply