Ko si iwe-ẹri Adeleke lọdọ wa o – INEC Ọṣun

Florence Babaṣọla, Oṣogbo

Kọmiṣanna fun ajọ eleto idibo nipinlẹ Ọṣun, Dokita Mutiu Agboke, ti sọ fun igbimọ to n gbọ ẹsun to ṣu yọ lẹyin idibo gomina l’Ọṣun pe ko si satifikeeti ti gomina tuntun, Sẹnetọ Ademọla Adeleke, lo lasiko to fẹẹ dije lọdun 2018 lakata ajọ naa mọ.

Satifikeeti yii lo ṣatupalẹ awọn iwe-ẹri ti Adeleke sọ pe oun ni ninu Form CF 001 to fi dije dupo gomina lọdun naa lọhun-un.

A oo ranti pe igbimọ naa ti fun agbẹjọro fun Gomina Gboyega Oyetọla ati ti ẹgbẹ oṣelu APC lanfaani lati fiwe pe kọmiṣanna fun ajọ eleto idibo ọhun lati ko awọn iwe-ẹri Ademọla Adeleke wa si kootu.

Nigba ti igbimọ naa jokoo lọjo Iṣẹgun, Tusidee, ọsẹ yii, ni agbẹjọro Oyetọla, Oloye Akin Olujinmi (SAN) ran ile-ẹjọ leti nipa iwe ti wọn fi ranṣẹ si REC lọjọ kẹẹẹdogun, oṣu Kọkanla, ọdun yii, ati pe ohun ti kọmiṣanna naa ba sọ ni yoo jẹ ọpakutẹlẹ ohun ti ẹlẹrii keji ti olupẹjọ fẹẹ pe yoo jẹrii le lori.

Agbẹjọro fun olujẹjọ akọkọ to jẹ ajọ INEC, Paul Ananaba, sọ fun ile-ẹjọ pe kọmiṣanna ajọ naa ti ran aṣoju kan wa.

Aṣoju naa, Sheu Mohammed, ẹni to jẹ igbakeji ọga agba lori ọrọ idibo ati iṣakoso ẹgbẹ oṣelu, ṣalaye pe Form CF 001 ti Adeleke fi kalẹ lọdun naa ko si lakata awọn mọ.

O ni ilu Abuja ni wọn mu fọọmu naa lọ, ẹda rẹ (photocopy) nikan ni wọn mu wa si ọfiisi ajọ naa l’Oṣogbo. O ni Form EC8A lawọn ni lọwọ.

Ṣugbọn agbẹjọro fun olujẹjọ sọ fun kootu pe ni kete ti ile-ẹjọ ti beere fun awọn satifikeeti naa lo yẹ ki REC ti ranṣẹ si olu ileeṣẹ naa l’Abuja lati ba a fi ranṣẹ.

Ninu ọrọ ẹlẹrii miiran ti olupẹjọ pe, Rasak Adeọsun, sọ fun kootu pe gbogbo iwadii lo fidi rẹ mulẹ pe Adeleke ko ni iwe-ẹri kankan nitori ko lọ si yunifasiti kankan.

Leave a Reply