Ko sigba tijọba ko ni i fi ofin lelẹ lori bi awọn eeyan ṣe n lo ẹrọ ayelujara nilokulo – Lai Muhammed

Jide Alabi

Pẹlu igbesẹ ti ijọba apapọ fẹẹ gbe lati fopin si ohun ti awọn eeyan yoo maa pin kiri lori ẹrọ ayelujara, o ṣee ṣe ki ariwo mi-in tun ṣelẹ, ti awọn ọmọ Naijiria ba ri i gẹgẹ bii ọna lati pa wọn lẹnu mọ ni.

Minisita fun eto iroyin, Alhaji Lai Muhammed, sọ pe ko sigba ti ijọba ko ni i fi gbedeke si bi awọn eeyan ṣe n lo ẹrọ ayelujara nilokulo, paapaa lori bo ṣe le da wahala silẹ laarin ilu.

O ni igbesẹ ọhun ti ṣe pataki bayii, nitori ọpọlọpọ wahala to ṣẹlẹ lasiko iwọde ta ko SARS, iroyin ẹlẹjẹ ti wọn n pin kiri lo fa a.

Ọdun 2018 ni minisita yii sọ pe oun ti kọkọ keboosi pe o ṣe pataki ki ofin ati ijanu wa lori bi awọn eeyan yoo ṣe maa lo ẹrọ ayelujara.

Minisita naa ni bayii, ko si ṣiṣe, ko si aiṣe, o ti di dandan fun ijọba lati wa ojuutu si bi ijanu ṣe maa wa, ki awọn alayederu iroyin ma lọọ fi igbekugbee wọn da Naijiria ru.

O ni aimọye iroyin ti ko jẹ ootọ lawọn kan n pin kiri, paapaa lasiko igba ti ọrọ iwọde ta ko SARS gbọna mi-in yọ, tawọn kan ti n tufọ awọn oṣere kan pẹlu fọto wọn, ṣugbọn ti ọrọ ko pada ri bẹẹ rara.

Muhammed ni, ‘‘A o ṣiṣẹ lori ẹ, bẹẹ ni ko ni i jẹ lorilẹ-ede yii nikan. A o ri i daju pe ko ni i saaye lilo ẹrọ ayelujara bi eeyan ba ṣe fẹ lai bikita wahala to le ṣẹlẹ.

3 thoughts on “Ko sigba tijọba ko ni i fi ofin lelẹ lori bi awọn eeyan ṣe n lo ẹrọ ayelujara nilokulo – Lai Muhammed

Leave a Reply