Ko sohun to buru ninu ki Musulumi jẹ aarẹ ati igbakeji, Onigbagbọ niyawo Tinubu-Kalu

Ọrẹoluwa Adedeji
Gomina ipinlẹ Abia tẹlẹ, Orji Uzor Kalu, toun naa jẹ ọmọ ileegbimọ aṣofin agba, ti sọ pe ko si ohun to buru bi ẹgbẹ APC ba fa igbakeji to jẹ Musulumi kalẹ lati ṣe igbakeji Tinubu, o ni niwọn igba ti iyawo rẹ, Olurẹmi ti jẹ Onigbagbọ, o ni ki aọn ọmọlẹyin Krisit ma tori eyi binu tabi ko aya soke.
Kanu sọrọ yii fawọn oniroyin nileegbimọ aṣofin agba niluu Abuja, l’Ọjọruu, Wẹsidee, ọsẹ yii. Gẹgẹ bi akọroyin iweeroyin Daily Trust ṣe sọ, Kalu ni, ‘‘Ẹ jẹ ki n sọ fun yin, ninu ile temi ti mo ti wa, iyawo mi ni olori ile. Koda, ẹyin ọkunrin ti ẹ wa nibi lasiko yii ti iyawo yin ko si nibi, sibẹ, iyawo yin naa ṣi ni olori ile yin. Fun apẹẹrẹ, ti mo ba wọ aṣọ kan, iyawo mi aa ni, ‘Ololufẹ mi, aṣọ ti o wọ yii ko dara, lọọ paarọ rẹ’. Iyawo yin lo maa sọ fun yin pe ogi ati akara ni kẹ ẹ mu laaarọ. Iyawo yin lo maa fẹ ki ẹ sanwo ileewe awọn ọmọ, boya o ba a jiyan tabi bẹẹ kọ, o ni lati san an.
‘‘Awọn Onigbagbọ gbọdọ fi ara balẹ daadaa, nitori Onigbagbọ ni iyawo Tinubu. Niwọn igba to si ti ri bẹẹ, a ko ni ohunkohun lati bẹru, nitori ki i ṣe iyawo ile lasan, oloṣelu to ni imọ nipa oṣelu ni.

Leave a Reply