Ko sọmọ ẹgbẹ PDP to le figagbaga pẹlu mi lọdun 2023 – Tinubu

Faith Adebọla
Ondije fun ipo aarẹ lẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress, APC, ati adari apapọ ẹgbẹ oṣelu naa, Aṣiwaju Bọla Ahmed Tinubu, ti rọ awọn alatilẹyin rẹ atawọn aṣoju ẹgbẹ naa pe ki wọn rọjo ibo witiwiti foun lasiko eto idibo abẹle to n bọ lọna yii, tori toun ba fi le jawe olubori, ti wọn si fa oun kalẹ gẹgẹ bii ọmooye funpo aarẹ, ko si ondije kankan ninu ẹgbẹ oṣelu Peoples Democratic Party, PDP, to le ba oun figagbaga to ba dọrọ idije funpo aarẹ ninu eto idibo gbogbogboo lọdun 2023.
Tinubu sọrọ yii lasiko to n fikun lukun pẹlu awọn aṣoju ẹgbẹ APC niluu Makurdi, ipinlẹ Benue, lọjọ kẹtadinlogun, oṣu Karun-un yii.
Gomina ipinlẹ Eko tẹlẹ naa, Tinubu, sọ pe “Mo rọ yin pe kẹ ẹ fun mi ni tikẹẹti ẹgbẹ APC tori ko le si ọrọ fifigagbaga laarin emi ati ẹnikẹni ti ẹgbẹ oṣelu alatako, PDP, ba fa kalẹ lọdọ wọn.
“Mo maa lo iriri mi nipo adari ti mo ti wa gẹgẹ bii gomina ipinlẹ Eko, ati ọna iṣakoso mi ni Naijiria tẹ ẹ ba dibo yan mi sipo aarẹ orileede yii.
“Mo fọwọ sọya pe ijọba ti ma a ṣe, ijọba to maa ṣe kedere si gbogbo eeyan ni, ko ni i si fifi igba kan bọ’kan ninu, gẹgẹ bii aarẹ. Naijiria lọrọ, ohun to kan ku fun wa ni ka dari awọn nnkan amuṣọrọ ati alumọọni wa sọna to tọ, ti yoo ṣe gbogbo wa lanfaani.”
Tinubu tun parọwa sawọn ọdọ pe ki wọn fọkan tan oun, o ni toun ba di aarẹ, gbogbo ireti ati afojusun wọn loun maa ṣiṣẹ le lori, oun o si ni i ja wọn kulẹ.

Leave a Reply