Ko yẹ kawọn oloṣelu to ti darugbo bii temi tun maa ba awọn ọdọ dije mọ, ẹ fawọn ọdọ laaye-Ọbasanjọ  

Faith Adebọla

Oloye Oluṣẹgun Arẹmu Ọbasanjọ, olori orileede wa tẹlẹ, ti gba awọn oloṣelu lamọran pe ohun to daa, to si bojumu ni pe kawọn to ti darugbo, ti wọn si ti pẹ lẹnu oṣelu, faaye silẹ fawọn ọdọ atawọn to ṣi san-an-gun lagbo oṣelu, o ni dipo tawọn arugbo yoo maa ba awọn ọdọ dupo, niṣe lo yẹ ki wọn maa gba wọn lamọran ki wọn si maa tọ wọn sọna, tori eyi lo le mu Naijiria goke agba.

Ọbasanjọ sọrọ yii lọjọ Aje, Mọnde, ọjọ kọkanlelogun, ọsu Keji yii, nibi asọye ọdọọdun kan ti wọn maa n ṣe fun iranti Oloogbe Ọgagun Muritala Mohammed, to ṣakoso orileede wa lasiko iṣejọba ologun.

Ajọ aladaani Muritala Mohammed Foundation (MMF) lo ṣeto ayẹyẹ iranti ti wọn pe akọle tọdun yii ni: “Yatọ si ọrọ Boko Haram, ba a ṣe le koju ijinigbe, ifẹmiṣofo ati awọn agbebọn ni Naijiria.”

Gomina ipinlẹ Ekiti, Ọmọwe Kayọde Fayẹmi, to kọkọ sọrọ ṣaaju Ọbasanjọ, lo mẹnu ba a pe ileewe alakọọbẹrẹ loun wa nigba ti Muritala ati Ọbasanjọ fi n tukọ orileede Naijiria gẹgẹ bii ologun.

Ọrọ yii ni Oloye Ọbasanjọ tọka si nigba to kan an lati sọrọ, o ni:

“O yẹ ka ni ajọṣepọ to dan mọran laarin iran kan si omi-in. Fayẹmi sọ lẹẹkan pe ileewe alakọọbẹrẹ loun wa nigba ti Muritala ati Ọbasanjọ n ṣejọba. Ti iru Muritala ati Ọbasanjọ ba ṣi waa n dije pẹlu iru Fayẹmi, fun ipo gomina, ẹ o ri ipe ọrọ naa ko sunwọn.

“Awọn to wa lọjọ-ori Muritala ati Ọbasanjọ gbọdọ lọọ wabi jokoo si. Iriri ati imọ yoowu ti wọn ba ni, ka fi ṣeranwọ fawọn ọdọ to n bọ lẹyin wa ni, niṣe lo yẹ ka ta atare awọn imọ ati iriri yẹn sawọn to maa rọpo wa, ki i ṣe ka tun maa ba wọn figa gbaga, niṣe ni ka fun wọn ni nnkan to maa jẹ ki wọn le gbe Naijiria goke agba.”

Ọmọ Ologbe Muritala, Dokita Aisha Muhammed Oyewọle naa kin ọrọ Ọbasanjọ lẹyin, o ni ajọ MMF ti n ṣe bẹbẹ lati mu idagbasoke ba orileede Naijiria ati ilẹ Afrika lapapọ, nipa awọn eto ati iranwọ to maa ro awọn ọdọ lagbara lati de ipo aṣaaju rere, tori ala ti baba oun ni ki iku too da ẹmi ẹ legbodo niyẹn.

Tẹ o ba gbagbe, ọjọ kẹtala, oṣu Keji, ọdun 1976, ni awọn afibọn-gbajọba kan ninu awọn ṣọja ilẹ wa lọọ yinbọn pa Ọgagun Muritala Mohammed lẹni ọdun mẹtadinlogoji, ati amugbalẹgbẹ rẹ, Akintunde Akinṣẹhinwa, bo tilẹ jẹ pe awọn ọlọtẹ naa ko ri ijọba ọhun gba bi wọn ṣe lero.

Leave a Reply