Kokeeni lawọn eleyii n gbe lọ si Mẹka tọwọ fi tẹ wọn

Monisọla Saka

Ọwọ ajọ to n gbogun ti tita, rira ati ilokulo oogun oloro lorilẹ-ede yii, National Drug Law Enforcement Agency (NDLEA), ti tẹ awọn eeyan mẹrin kan ti wọn n lọ si orilẹ-ede Saudi Arabia, fun iṣẹ Haji. Lasiko ti wọn n gbe egboogi oloro kokeeni ti wọn fẹẹ lọọ ta lọhun-un mi ni wọn mu wọn.

Gẹgẹ bi Ọgbẹni Fẹmi Babafẹmi, ti i ṣe agbẹnusọ ajọ naa ṣe fidi ẹ mulẹ l’Ọjọbọ, Tọsidee, ọjọ kẹfa, oṣu Kẹfa yii, o ni Emerald Hotel, to wa lagbegbe Ladipọ, Oshodi, nipinlẹ Eko, tawọn afurasi wa, ti wọn si ti n gbaradi lati lọ oogun oloro alagbara naa mi, ni wọn ti ko wọn l’Ọjọruu, Wẹsidee, ọjọ karun-un, oṣu Kẹfa yii.

Egboogi oloro kokeeni ti wọn ti di pẹlẹbẹ pẹlẹbẹ lọna igba, eyi to gbe iwọn to le ni kilo meji lori sikeeli, ni wọn ka mọ awọn afurasi mẹrẹẹrin ọhun, iyẹn, Usman Kamorudeen, ẹni ọdun mọkanlelọgbọn (31), Ọlasunkanmi Owolabi, ẹni ọdun mẹrindinlaaadọta (46), Fatai Yẹkini, ẹni ọdun mejidinlogoji (38), ati obinrin kan ṣoṣo to wa laarin wọn, Ayinla Kẹmi, ẹni ọdun mẹrinlelọgbọn (34), lọwọ.

Atẹjade naa ka bayii pe, “Ọwọ awọn oṣiṣẹ ajọ NDLEA, ti wọn ya bo Emerald Hotel, to wa lagbegbe Ladipọ, Oshodi, nipinlẹ Eko, tẹ awọn eeyan mẹrin kan ti wọn n lọ si Mẹka gẹgẹ bi iṣẹ Haji ṣe n lọ lọwọ l’Ọjọruu, Wẹsidee, ọjọ karun-un, oṣu yii, nileetura ti wọn wọ̀ si. Lasiko ti wọn n lọ kokeeni ti wọn ti pọn sinu lailọọnu keekeeke mi, ko too di pe ẹronpileeni wọn yoo gbera ni wọn mu wọn.

“Awọn eeyan tọwọ tẹ lasiko tawọn ikọ ọtẹlẹmuyẹ ajọ naa debẹ ni Usman Kamorudeen, Ọlasunkanmi Owolabi, Fatai Yẹkini, ati Arabinrin Ayinla Kẹmi.

“Yara meji ọtọọtọ ni awọn afurasi mẹrẹẹrin de si ninu otẹẹli naa. Wọn ti ṣeto, wọn si ti we kokeeni ọhun, ti iwọn rẹ le ni kilo meji (2.20kg), sinu lailọọnu, lasiko ti wọn fẹẹ maa lo o lawọn oṣiṣẹ ajọ NDLEA ja wọ yara wọn.

Idi kokeeni ọgọrun-un ni wọn ba ninu yara kọọkan ti wọn ka awọn afurasi ọhun mọ, eyi to mu ki gbogbo rẹ lapapọ jẹ igba. Eeyan meji meji to wa ninu yara kọọkan ni wọn yoo jọ pin ọgọrun-un kokeeni naa lọ mi”.

Babafẹmi fi kun ọrọ rẹ pe ọga NDLEA, Buba Marwa, ti ṣeleri pe ileeṣẹ awọn yoo ba ojugba wọn lorilẹ-ede Saudi Arabia ṣiṣẹ, lati le tọpinpin ẹni tawọn afurasi ọhun fẹẹ gbe ọja naa fun ti wọn ba gunlẹ si Mẹka, ki wọn si fi iya to tọ jẹ onitọhun pẹlu.

Wọn ni awọn ko ni i yee dọdẹ gbogbo awọn oniwa ibajẹ ti wọn gọ si abẹ ibooji pe awọn n lọ si Mẹka lọọ ṣiṣẹ Haji, pẹlu erongba ati huwa ti yoo ta epo si aṣọ aala orilẹ-ede yii.

Leave a Reply